Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ May 6 sí August 19, 1996. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ìrúbọ kan ṣoṣo ti Jésù rọ́pò gbogbo ìrúbọ tí a ṣe lábẹ́ Òfin Mósè. [4, uw-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 8(4)]
2. ‘Gọ́ọ̀gù ti Mágọ́gù’ jẹ́ àpẹẹrẹ ìtọ́ka sí àwọn ìjọba ayé yìí. (Isk. 38:2) [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 8/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2.]
3. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Òhólà ti jẹ́ ẹ̀gbọ́nbìnrin fún Òhólíbà, bí Ìsíkẹ́ẹ̀lì orí 23 ti ṣàpèjúwe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ìsìn Roman Kátólíìkì jẹ́ ẹ̀gbọ́nbìnrin fún ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ètò àjọ méjèèjì sì ti sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin nípa ṣíṣe àgbèrè tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn agbára ìṣòwò àti ti ìṣèlú ayé. [6, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 4/1 ojú ìwé 30.]
4. Láìka ohun yòówù kí a ṣe sí, bí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run, ohun gbogbo yóò padà bọ̀ sípò. [5, uw-YR ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 12]
5. Pé kò dára láti ní àwọn ènìyàn tí kì í ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní a lè rí láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Dínà, ọmọbìnrin Jákọ́bù. [3, my-YR Ìtàn 20]
6. Jákọ́bù 4:17 àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:7-9 fohùn ṣọ̀kan, ní fífi hàn pé mímọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa ni yóò mú wa jíhìn fún un. [10, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 4/1 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 1.]
7. Dáníẹ́lì fẹ̀rí hàn pé òún jẹ́ wòlíì tòótọ́ nípa ṣíṣàlàyé ìtumọ̀ àlá ère náà lẹ́yìn tí Ọba Nebukadinésárì ti ṣàpèjúwe rẹ̀ fún un. [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo Dáníẹ́lì 2:7-9, 26.]
8. Omi tí ń ṣàn jáde láti inú tẹ́ḿpìlì inú ìran náà tí a ṣàpèjúwe nínú Ìsíkẹ́ẹ̀lì 47:1 dúró fún agbára ìsọnidimímọ́ tí batisí ní. [14, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 20.]
9. Má ṣe fòyà láti sọ pé rárá fún ẹnì kan tí ń rọ̀ ọ́ láti ‘jayé orí rẹ,’ àní bí ìkésíni náà bá wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí ó sọ pé Kristẹni ni òun pàápàá. (2 Pet. 2:18, 19) [8, uw-YR ojú ìwé 43 ìpínrọ̀ 11]
10. Ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé yóò ní ìmúṣẹ. (Aisa. 55:10, 11) [2, kl-YR ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 10]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:
11. Kí ni ó yẹ kí ìgbìyànjú Ábúráhámù láti fi Aísíìkì rúbọ ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì rẹ̀? (Jẹn. 22:1-18) [3, uw-YR ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 8(1)]
12. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé iṣẹ́ àyànfúnni tí Jèhófà Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà jẹ́ òfin kan? (Jẹn. 1:28; 2:15) [6, uw-YR ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 2]
13. Lọ́nà wo ni ó yẹ kí àwọn Ẹlẹ́rìí ẹni àmì òróró ti Jèhófà àti àwọn alájọṣepọ̀ wọn gbà dà bí Ìsíkẹ́ẹ̀lì? (Isk. 11:25) [1, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3.]
14. Àwọn wo ni irú ọmọ Ejò náà ní nínú? [2, uw-YR ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]
15. Ní àfikún sí fífi ẹ̀sùn irọ́ pípa kan Jèhófà, kí ni Sátánì sọ pé Ọlọ́run fi ń du àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀? (Jẹn. 3:1-5) [10, uw-YR ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 1]
16. Kí ni “ìlú ńlá” tí a tọ́ka sí nínú Hébérù 11:10? [11, uw-YR ojú ìwé 48 ìpínrọ̀ 6]
17. Ní ọ̀nà méjì wo ni a lè gbà sọ pé Ádámù àti Éfà kú “ní ọjọ́ tí” wọ́n jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú? (Jẹn. 2:17) [13, uw-YR ojú ìwé 56 ìpínrọ̀ 5]
18. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà? [13, kl-YR ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 7]
19. Wòlíì wo ni ó tọ́ka sí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí “òbírí” kan, ibo sì ni a ti ṣàkọsílẹ̀ èyí nínú Ìwé Mímọ́? [8, kl-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 14]
20. Báwo ni Bíbélì ṣe pèsè ojú ìwòye tí ó ṣe kedere nípa àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún wa, báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀? [6, kl-YR ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 9]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
21. Ní ìmúṣẹ Ìsíkẹ́ẹ̀lì 21:26, ìjọba _________________________ “gíga” ni a ‘mú rẹlẹ̀’ nípa pípa á run ní ọdún _________________________ ìjọba “rírẹlẹ̀” ti _________________________ ni a sì “gbé ga,” ní fífi wọ́n sílẹ̀ nínú ìṣàkóso ilẹ̀ ayé láìsí ìdásí láti ọwọ́ àpẹẹrẹ irú _________________________ kan tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run. [5, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 16.]
22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ _________________________ tí a ti kọ tẹ́lẹ̀ ṣáájú, ìwé Dáníẹ́lì jóòótọ́. A mẹ́nu ba Dáníẹ́lì ní ìgbà _________________________ nínú ìwé Ìsíkẹ́ẹ̀lì. [14, w88-YR 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5]
23. Ìbálò Jèhófà pẹ̀lú Fáráò ṣí _________________________ rẹ̀ tí ó ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ payá, ó sì ṣí _________________________ rẹ̀ payá nípa fífi ìyà jẹ àwọn olórí kunkun alátakò àti àwọn aninilára. [15, kl-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 14]
24. Ẹ́kísódù 34:7 ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí _________________________ kan bí wọ́n bá ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, tí a sì kó wọn lọ sí oko ẹrú, nígbà tí Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4 ń sọ̀rọ̀ nípa ìjíhìn ti _________________________ fún Ọlọ́run. [4, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 2/1 ojú ìwé 6.]
25. Nígbà tí o bá ń ka Bíbélì, ó dára láti bi ara rẹ léèrè nípa bí o ṣe lè ṣe àmúlò ohun tí ìwọ́ ń kà fún _________________________ àti bí o ṣe lè lo ohun tí ìwọ́ ń kà láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn _________________________. [1, uw-YR ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 12(4) àti ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 12(5)]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
26. Ìdàníyàn pàtàkì Kristẹni kan nínú ìgbésí ayé ni (láti ní àǹfààní nínú ìjọ; láti la Amágẹ́dọ́nì já; láti ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà). [7, uw-YR ojú ìwé 42 ìpínrọ̀ 9]
27. Ọ̀pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti mọ̀ pé àwọn ìṣòro tí a máa ń bá pàdé nínú ìgbésí ayé sábà máa ń dìde nítorí (àwọn ènìyàn tí wọ́n pinnu láti pa wá lára; ìgbà àti èṣì; ìfẹ́ ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ wa àti ẹgbẹ́ búburú). (1 Kọr. 15:33; Jak. 1:14, 15) [9, uw-YR ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 13]
28. (Ìmọ̀; agbára ìkọ́ni; ìwà) wa ń fi ibi tí a dúró sí hàn ní ìbátan pẹ̀lú àríyànjiyàn gíga jù lọ náà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run. [12, uw-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 12]
29. Àwọn tí ó kọ́kọ́ di “àwọn ohun èèlò àánú” ni (àwọn Kèfèrí; àwọn Júù; àwọn òǹkọlà ará Samáríà), tẹ̀ lé e ni (àwọn Kèfèrí; àwọn Júù; àwọn òǹkọlà ará Samáríà), níkẹyìn sì ni (àwọn Kèfèrí; àwọn Júù; àwọn òǹkọlà ará Samáríà) dé. (Rom. 9:23, 24) [16, uw-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 8 àti 10]
30. Ìṣubú Bábílónì ni a sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ (Dáníẹ́lì àti Hóséà; Jóẹ́lì àti Ámósì; Aísáyà àti Jeremáyà). [9, kl-YR ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 17]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Sm. 78:40, 41; Isk. 18:25; Dan. 1:8, 11-13; Ìṣe 8:32-38; 1 Joh. 1:8, 9
31. Ìmọrírì fún òtítọ́ àti fún ohun tí Jésù Kristi ti ṣe ní mímú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ ń sún àwọn aláìlábòsí ọkàn láti ṣe batisí. [3, uw-YR ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 7]
32. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kò gbọdọ̀ lọ́ tìkọ̀ láti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún àwọn aláṣẹ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn pé àwọn kì yóò ṣẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn oníwà-bí-Ọlọ́run wọn tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́. [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 11/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 17.]
33. Nípa lílo ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù Kristi, a lè ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gaara ní ti gidi nítorí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. [5, uw-YR ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 10]
34. Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣe tán nígbà gbogbo láti ṣàtúnṣe ìrònú wọn sí ọ̀nà Jèhófà, a kò sì gbọdọ̀ nímọ̀lára láé pé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ lílẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kò kàn wá, kí a sì ṣàìnáání rẹ̀. [4, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 11/1 ojú ìwé 31.]
35. Ọlọ́run ní ìmọ̀lára, àwọn yíyàn tí a bá ṣe sì kàn án. [6, kl-YR ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 8]