Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí lọni fún ọrẹ ₦25: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Níbi tí ó bá ti yẹ, a lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ bíi, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them? àti Will There Ever Be a World Without War? lọni. September: Efik àti Hausa—Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, The Bible—God’s Word or Man’s? Igbo—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Isoko—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ A ń fi àwọn fọ́ọ̀mù S-1, S-14, àti S-20 tí a óò lò nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. A kò gbọ́dọ̀ lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí ní ìlòkulò. Kìkì ète tí a ṣe wọ́n fún ni kí a lò wọ́n fún.
◼ Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta. Kí akọ̀wé ìjọ rí ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ August, kí wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọn yóò ṣèṣirò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú ìjọ ní ìparí oṣù náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní ti gidi, kí wọ́n sì kọ àròpọ̀ rẹ̀ sínú fọ́ọ̀mù Literature Inventory. Ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn lè sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ fún wọn. Ẹ jọ̀wọ́ fi ẹ̀dà tí ó wà lókè ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ jù ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta fún àkọdánrawò yín. Kí akọ̀wé bójú tó ìṣirò náà, kí alábòójútó olùṣalága sì ṣàyẹ̀wò fọ́ọ̀mù tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága yóò fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ A ń fi ẹ̀dà méjì fọ́ọ̀mù Congregation Analysis Report S-10 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yìí pẹ̀lú ìṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì fi ẹ̀dà tí ó wà lókè ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ jù ní September 6, 1996, pẹ̀lú ìròyìn August. Ẹ̀dà kejì jẹ́ ti fáìlì yín.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti August 19, 1996, títí di August 30, 1996, Society yóò máa ṣèṣirò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì ní Igieduma. Nítorí ìṣirò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè fún láti fi ránṣẹ́ tàbí láti wá kó ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn. Àmọ́ ṣáá o, yàrá ìgbàwé wa yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, o lè ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí àwọn ìwé mìíràn.
◼ Society ti ní nọ́ḿbà tẹlifóònù tuntun nísinsìnyí, tí yóò ṣèrànlọ́wọ́ gidigidi fún wa nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ orí tẹlifóònù. Nọ́ḿbà tuntun náà ni 052-257767. Èyí jẹ́ àfikún sí àwọn nọ́ḿbà tí a ń lò lọ́wọ́, àwọn wọ̀nyí 055-98023, 055-98033, 055-98051, 055-98052, àti 01-821423 (Ibùdó Ìkówèésí ní Èkó).