Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú
1 Lọ́dún 1983, ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìṣọ̀kan Ìjọba” ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìfilọ̀ kan wáyé pé a óò ṣàgbékalẹ̀ ètò kan fún ṣíṣe àkànṣe ọrẹ láti ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti ṣíṣe àtúnkọ́ àwọn mìíràn jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà. A ò mọ̀ rárá nígbà yẹn pé ohun tá a bẹ̀rẹ̀ lọ́nà kékeré yẹn yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún wá. A bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmúṣẹ ohun tí Sáàmù 92:4 sọ lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé: “Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ; mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”
2 Inú wa ń dùn gan-an báyìí fún àṣeyọrí tí à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà. Lónìí, ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́nà yíyára kánkán ń lọ ní pẹrẹu. Lọ́nà kan tàbí òmíràn, gbogbo wa pátá la ní àǹfààní láti kópa nínú ìgbòkègbodò yìí. À ń ṣe èyí nípa fífi ọrẹ owó ńlá tàbí kékeré ṣètìlẹyìn, láti ṣèrànwọ́ fún kíkọ́ ibi ìjọsìn púpọ̀ sí i jákèjádò ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló tún ń fi tinútinú yọ̀ǹda àwọn ohun èlò wọn, bákan náà ni wọ́n tún ń yọ̀ǹda àkókò wọn, agbára wọn, àti òye iṣẹ́ tí wọ́n ní fún irú àwọn ìdáwọ́lé bẹ́ẹ̀. Ohun tó mú kí gbogbo ètò náà yọrí sí rere ni ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ìtìlẹ́yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbùkún rẹ̀ lórí ìsapá gbogbo wa lápapọ̀.—Sm. 127:1.
3 Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ti tẹ̀ lé irú ìlànà tá a gbé kalẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ fún àwọn ìjọ tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àpótí kan wà tí àwọn akéde máa ń fi ọrẹ wọn sí fún Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997 ṣèfilọ̀ pé ìyípadà kan máa wáyé nínú ètò yìí. Ó sọ pé: “Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ ètò Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́dún 1983, àwọn arákùnrin ti fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ gan-an ni, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe láti yá àwọn ìjọ lówó fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] ìjọ ní orílẹ̀-èdè yìí [Amẹ́ríkà] ló ti jàǹfààní látinú ìṣètò yìí. Bí kì í bá ṣe ti ìṣètò yìí ni, kì bá tí ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ ìjọ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe àwọn tó nílò àtúnṣe. Ipò kan tó ń fẹ́ àmójútó kíákíá ti wá dìde báyìí, ìyẹn ni láti lò lára àwọn ọrẹ tí a dá yìí láti pèsè owó yíyá fún àwọn ìjọ láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan kò ṣẹnuure fún. Society àtàwọn ìjọ tí wọ́n ń jàǹfààní látinú ìṣètò yìí mọrírì rẹ̀ gidigidi bí ẹ ti ń bá a nìṣó ní kíkọ́wọ́ ti ètò yìí lẹ́yìn.”
4 Ìfilọ̀ yẹn jẹ́ ìkésíni láti kópa nínú ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́nà yíyára kánkán. Ibi tí Society ń ná Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba sí yóò gbòòrò sí í. Lára èyí yóò jẹ́ ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wa láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, síbẹ̀ a óò ṣì máa bá a lọ láti máa pèsè owó yíyá fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní orílẹ̀-èdè yìí [Amẹ́ríkà]. Àpilẹ̀kọ kan tó jáde lẹ́yìn ìgbà náà nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1997 ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “A ṣì ní láti máa bá a lọ ní kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ayé. Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá nìkan, ẹgbẹ̀rìndínlógún ó lé méjìdínláàádọ́rùn-ún [3,288] ìjọ tuntun la dá sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọ yìí ló wà nílẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà, àti ní apá Ìlà Oòrùn Yúróòpù.”
5 Àwọn àbájáde wo la ti rí látìgbà náà? Ìwé Yearbook 2001 ròyìn pé: “Nípasẹ̀ ètò yìí, ní ọgbọ̀n orílẹ̀-èdè, irínwó lé mẹ́tàléláàádọ́ta [453] Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti kọ́ parí látìgbà náà wá, iṣẹ́ sì ń lọ lórí àwọn mìíràn tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [727]. [Ní Nàìjíríà, ọ̀kànléláàádọ́sàn-án [171] àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun la kọ́ tá a sì yà sí mímọ́ láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002.] A ti gbájú mọ́ yíya àwọn àwòrán Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu fún orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun èèlò ìkọ́lé àti ọ̀nà ìkọ́lé tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè wọn. Ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, òkúta ni wọ́n ń lò láti kọ́lé; ní Tógò, bíríkì ló wọ́pọ̀ jù; ní [Nàìjíríà àti] ní Cameroon, búlọ́ọ̀kù tí wọ́n á wá rẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n sábà máa ń lò. Lọ́nà yìí, ó máa ń ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí láti tètè ní àwọn òye iṣẹ́ tó pọn dandan láti lè bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan níbàámu pẹ̀lú ètò tá a ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn.”
6 Ẹ̀rí pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ yìí la lè rí ní àgbáálá ilẹ̀ Áfíríkà tó gbòòrò. Bó o ti ń wo àwòrán díẹ̀ lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́, fọkàn yàwòrán ipa tí irú àwọn ibi ìjọsìn wọ̀nyí ti ní lórí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèyí ti fara hàn kedere—ó ti nípa lórí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará wa karí ayé, lórí àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn àgbègbè tá a kọ́ wọn sí, àti lórí bí iye àwọn tó ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ ṣe ń ròkè sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́ nílẹ̀ Áfíríkà ni àkìbọnú yìí sọ̀rọ̀ lé lórí jù lọ, àwọn ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò sọ̀rọ̀ lórí bí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe ń tẹ̀ síwájú láwọn apá ibòmíràn láyé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
CENTRAL AFRICAN REPUBLIC
Bimbo, Bangui
Begoua, Bangui
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ukonga, Tanzania
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Accra, Gánà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Salala, Liberia
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Karoi, Zimbabwe
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Allada, Benin—Gbọ̀ngàn Ìjọba ti àtijọ́
Allada, Benin—Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kpeme, Tógò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Sokodé, Tógò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Fidjrosse, Benin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Lyenga, Zambia—Gbọ̀ngàn Ìjọba ti àtijọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Lyenga, Zambia—Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Kinshasa, Congo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Musambira, Rwanda