ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/03 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 1/03 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé wọ̀nyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni. A óò sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. February àti March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Kí àwọn akéde sọ fún àwọn onílé pé wọ́n lè fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa kárí ayé bí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, jẹ́ kí onítọ̀hún wà lára àwọn tí wàá máa mú ìwé ìròyìn lọ fún déédéé. Fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, kí o sì ní i lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tán láti March 2, àsọyé tuntun tí àwọn alábòójútó yóò máa sọ fún gbogbo èèyàn yóò jẹ́ “Ìdáǹdè Kúrò Nínú Ayé Òkùnkùn.”

◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Wednesday, April 16, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Níbi tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kí olúkúlùkù lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà. Ó yẹ kí a tún ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tó máa wá kò ṣe ní ṣèdíwọ́ àti ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ ní àdúgbò wọn.

◼ Nígbà tí alábòójútó olùṣalága bá gba ìwé ìṣirò owó láti ọ́fíìsì ẹ̀ka ní oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ó rí i dájú pé a ka gbogbo ohun tó wà nínú ìwé náà sí etígbọ̀ọ́ ìjọ, ìyẹn àkọsílẹ̀ ọrẹ tí ìjọ ṣe fún Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ọrẹ fún iṣẹ́ Society kárí ayé, nígbà tí a bá ń ka ìròyìn ìnáwó tó máa tẹ̀ lé e.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà: Organized to Accomplish Our Ministry—Ègùn

◼ Fídíò Tuntun Tó Wà: Sing Praises to Jehovah—On Videocassette, Ìdìpọ̀ 1 àti 2—Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà

◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí a óò ṣe lọ́dún 2003, a óò ṣètò àyè ìjókòó lọ́tọ̀ fún àwọn adití ní àwọn àyíká tí a to orúkọ wọn sísàlẹ̀ yìí, níbi tí a ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà:

Akabo (EE-08) March 1 àti June 7-8

Àkúrẹ́ (WE-12) March 1 àti May 17-18

Badagry (WE-04) August 3 àti April 19-20

Badagry (WE-23) March 2 àti August 30-31

Dálùwọ́n (WE-03) March 2 àti June 14-15

Enugu (EE-17) June 28 àti March 8-9

Igwuruta Ali (EE-22) March 15 àti August 16-17

Iléṣà (WE-15) March 30 àti June 21-22

Kàdúná (NE-01b) March 15 àti June 14-15

Ọ̀tà (WE-06) March 23 àti June 28-29

Ọ̀tà (WE-07) March 2, àti May 31-June 1

Ùbogò (ME-07) August 16 àti April 26-27

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́