ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/03 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Jó Rẹ̀yìn Tó O Bá Ń Sìn Nílẹ̀ Àjèjì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 1/03 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ìgbà wo ló yẹ kí a dá àwùjọ tó ń sọ èdè òkèèrè sílẹ̀?

Bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sọ èdè òkèèrè bá wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ kan, àwọn alàgbà ní láti ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ṣètò fún iṣẹ́ ìwàásù ní èdè yẹn. (km–YR 7/02 ojú ìwé 1; km-YR 2/98 ojú ìwé 3 àti 4) Ó lè ṣẹlẹ̀ pé ńṣe làwọn èèyàn tó ń sọ èdè òkèèrè náà wà káàkiri ìpínlẹ̀ ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n múlé gbera wọn. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn alábòójútó àyíká yóò pèsè ìtọ́sọ́nà tó yẹ, èyí tí yóò ran àwọn ìjọ tí ọ̀rọ̀ kàn náà lọ́wọ́ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù. Látìgbàdégbà, wọ́n lè máa ṣètò àsọyé fún gbogbo èèyàn tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ láti pinnu bí àwọn tí yóò máa wá sí àwọn ìpàdé náà ṣe máa pọ̀ tó.

A lè dá àwùjọ kan tó ń sọ èdè òkèèrè sílẹ̀ nígbà tá a bá ti kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí: (1) Àwọn akéde tàbí àwọn olùfìfẹ́hàn wà tí wọ́n lóye ìhìn rere náà ní èdè òkèèrè dáadáa. (2) Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tóótun wà láti máa bójú tó àwùjọ náà àti láti máa darí, ó kéré tán, ìpàdé kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (3) Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà múra tán láti ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ náà. Nígbà tí a bá ti kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí a béèrè fún yìí, kí àwọn alàgbà jẹ́ kí ọ́fíìsì ẹ̀ka mọ̀ nípa rẹ̀, kí Society bàa lè fọwọ́ sí àwùjọ náà kí wọ́n sì pèsè àwọn ìtọ́ni síwájú sí i.

Ọ̀pọ̀ àwùjọ tó ń sọ èdè òkèèrè máa ń bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn alàgbà lè fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi àwọn ìpàdé mìíràn kún un, irú bí Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Wọ́n lè ṣe Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì, Ìkẹta, àti Ìkẹrin nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tóótun tó lè sọ èdè náà bá wà tó lè ṣe agbani-nímọ̀ràn. Àmọ́, àwùjọ náà yóò máa dára pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn náà, fún ọ̀rọ̀ tí a gbé karí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ọ̀rọ̀ ìtọ́ni, àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Àwọn alàgbà tún lè ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún àwùjọ náà.

Gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ náà yóò máa ṣiṣẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ lábẹ́ àbójútó ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Kí àwọn alàgbà náà máa pèsè ìtọ́sọ́nà tó wà déédéé, kí wọ́n sì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti bójú tó àwọn ohun tí àwùjọ náà nílò. Nígbà tí alábòójútó àyíká bá ń bẹ ìjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ náà wò, yóò tún ṣètò láti bá àwùjọ náà ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá kó bàa lè gbé àwùjọ náà ró nípa tẹ̀mí. Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, àwùjọ tó ń sọ èdè òkèèrè náà lè di ìjọ tó bá yá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́