Ojúṣe Rẹ Nínú Kíkọ́lé fún Ọjọ́ Ọ̀la
1 Lónìí, àwọn Kristẹni ń bá a nìṣó láti bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé tẹ̀mí tí Jésù bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan bí 1,970 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ. (Mat. 4:17; 7:24, 25, 28; 2 Joh. 7:46) Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ yìí ní jìngbìnnì. (Òwe 10:22) Bí a tí ń lọ láti kéde Ìjọba Ọlọ́run, a tún ń kọ́lé láti bójú tó ìbísí ọjọ́ iwájú.
2 Bí a ti ní láti ṣàtúnṣe ọ̀pọ̀ ògbólógbòó Gbọ̀ngàn Ìjọba, a nílò àfikún gbọ̀ngàn láti pèsè àyè fún àwọn ìjọ tuntun tí à ń dá sílẹ̀. Ní ọdún tí ó kọjá nìkan, àwọn ìjọ ní Nàìjíríà fi 153 ròkè sí i. A nílò owó àti àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni láti parí àwọn ìkọ́lé tí a ti dáwọ́ lè wọ̀nyí pẹ̀lú àṣeyọrí. Ìṣarasíhùwà gbígbéniró, tí ó yẹ fún oríyìn, ti àwọn ará síhà kíkúnjú àìní yìí ni a ti san èrè fún.
3 Ìtìlẹ́yìn Onífẹ̀ẹ́ tí Ọ̀pọ́ Ti Ṣe: A ń fi ìfẹ́ wa hàn fún “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” nípa ṣíṣètọrẹ sínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. (1 Pet. 2:17) Àwọn ọrẹ tí ẹ̀ka yìí ti rí gbà, ti pèsè owó láti ṣètìlẹ́yìn nínú kíkọ́ 110 Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Ṣùgbọ́n, àìní náà ń bá a lọ láti pọ̀ sí i, bí iṣẹ́ ìkójọ náà ti ń yára kánkán. Nítorí náà, Jèhófà ń bá a lọ láti bù kún ìṣètò yìí, àwọn alàgbá sì ní láti rí i dájú pé a kọ orúkọ sórí àpótí ọrẹ fún Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba ní gàdàgbà, kí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́to gbogbo àwùjọ ní gbogbo ibi tí a ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Àwọn ọrẹ tí a rí gbà, àti àwọn owó ti a ń san padà, ni a ń fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti fún ìṣàtúnṣe ńlá.
4 Society, àti gbogbo ìjọ tí ń jàǹfààní láti inú ìpèsè náà, fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún ògìdìgbó ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ìdílé, tí wọ́n ń ṣètọrẹ déédéé sínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Gbogbo ìjọ ni ó yẹ kí ó ṣe ìtọrẹ sínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba, yálà àwọn fúnra wọn ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan lọ́wọ́ tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kò gbọdọ̀ kùnà láti sọ iye tí àwùjọ rẹ̀ fi tọrẹ ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá fún wọn. Èyí jẹ́ àǹfààní dídára fún gbogbo àwùjọ láti ṣàjọpín, àtàgbà àtọmọdé, láìka ohun tí ipò àtilẹ̀wá wọ́n ní ti ìṣúná owó lè jẹ́ sí. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wá lè múra sílẹ̀ ṣáájú lílọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti baà lè ní ohun kan láti fi ṣe ìtọrẹ sínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba.
5 Àìní fún ìtọrẹ déédéé ń bẹ níbẹ̀. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ní Ilẹ̀ Àpéjọ 44 ní Nàìjíríà, kò sì sí èyí tí a lè sọ pé a ti kọ́ parí nínú wọn. Ọ̀pọ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a ti ń kọ́ fún àìmọye ọdún, tí a kò sì tí ì kọ́ parí títí di ìsinsìnyí. Àwọn ìdáwọ́lé wọ̀nyí ń falẹ̀ nítorí àìsówó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé agbára gbogbo wa ò dọ́gba, a lè rí i pé nípa ṣíṣe àtúnṣe nínú ọ̀nà tí a gbà ń náwó, a lè ní ìpín kíkún sí i nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà. Ǹjẹ́ kí a fi “ohun-ìní” wa bọlá fún Jèhófà. Ní ọ̀nà yìí, a ń fi ìfẹ́ wa hàn fún Un, Òún sì máa ń bù kún àwọn tí ń fi tọkàntọkàn ṣètọrẹ.—Òwe 3:9; 1 Kro. 29:14-17.
6 O ha jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, bí àye rẹ̀ bá sì yọ láti ṣèrànlọ́wọ́ pẹ̀lú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, o lè fi èyí tó àwọn alàgbà àdúgbò, àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, àti alábòójútó àyíká létí. A nílò àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni, tí ó lóye iṣẹ́, jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ń sọ pé àwọ́n nílò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni púpọ̀ sí i. Ní àfikún sí i, lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tí Society yàn, a ń kọ́ àwọn arákùnrin mìíràn tí ó tóótun láti ṣe iṣẹ́ tí a ń béèrè fún, kí a baà lè ran ọ̀pọ̀ ìjọ sí i lọ́wọ́ nínú ìkọ́lé tí wọ́n dáwọ́ lé.
7 Ojúṣe Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn: Ní March 1994, Society yan Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn márùn-ún fún Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n, nítorí àìní tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, a ní àròpọ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn 25 nísinsìnyí. Èé ṣe tí a fi yan ìgbìmọ̀ wọ̀nyí? A yàn wọ́n kí wọ́n baà lè pèsè ìrànlọ́wọ́ ní gbogbo ìgbésẹ̀ ìwéwèé àti ìkọ́lé. Wọ́n ní àwọn àwòrán ìgbékalẹ̀ ilé, tí Society pèsè, tí ó fi àwọn ọ̀nà tí a lè gbà yára kánkán kọ́lé hàn. Àwọn arákùnrin tí ó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí jẹ́ alàgbà onírìírí, wọ́n sì lè pèsè àwọn àbá tí ó wúlò fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó sì fani mọ́ra, àti fún dídín àkókò àti ìnáwó kù. Nítorí ìrírí wọn, wọ́n lè ran àwọn alàgbà àdúgbò lọ́wọ́ láti pinnu bóyá yóò dára láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà tẹ́lẹ̀ ṣe tàbí láti kọ́ tuntun mìíràn, wọ́n sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pinnu ṣáájú kí wọ́n tó kówó sílẹ̀, bóyá ibi tí wọ́n wéwèé láti kọ́ tuntun sí tàbí ilé tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ dára tó. Wọ́n tún lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fojú díwọ̀n ní kedere iye tí ilé kíkọ́ náà yóò ná wọn àti iye tí ó dára láti ta Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà tẹ́lẹ̀, tí wọ́n lè fẹ́ tà.
8 A ti pèsè ìtọ́sọ́nà ìkọ́lé lórí bí a ti ń ṣe iṣẹ́ kọnkéré tí ó jingíri, bí a ti í kan àwọn ọ̀pá àjà tí ó jíire, iye sìmẹ́ńtì, òkúta, iyanrìn, àti omi tí ó yẹ kí a pò pọ̀, àti àwọn apá iṣẹ́ ìkọ́lé mìíràn, fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn. Nípa títẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí Society pèsè, àti àwọn àbá mìíràn láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, yóò ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ àwọn ilé tí ó wúlò, tí ó dára, tí yóò wà pẹ́ títí. Bí iye tí yóò kọ́kọ́ náni láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó dára tilẹ̀ pọ̀, ó jẹ́ ọ̀nà dídára láti gbà lo ohun àmúṣọrọ̀ tí a yà sọ́tọ̀, ju láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí kò jọjú, tí kò ní wà pẹ́ títí. Ìròyìn ti fi hàn pé àwọn òrùlé ti wó lulẹ̀ tàbí kí atẹ́gùn ti ṣí wọn lọ, nítorí tí a kò kọ́ wọn dáradára. Èyí ń jẹ́ kí àwọn ìjọ sanwo lẹ́ẹ̀mejì, tí ó fi hàn pé ó dínwó kù láti náwó púpọ̀, kí a sì kọ́ ọ dáradára lákọ̀ọ́kọ́.
9 Ṣááju ríra ilẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu láti kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn. A yan àwọn ìgbìmọ̀ yìí láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn agbègbè tí a yàn wọ́n sí, tí ó kó àyíká mélòó kan mọ́ra, wọ́n sì lè ṣèrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ríra ilẹ̀ àti ṣíṣàyẹ̀wò ìwé ẹ̀tọ́ jíjẹ́ oníǹkan, tí ó bófin mu, tí wọ́n ní fún ilẹ̀ tí a fẹ́ rà fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n ní ìtọ́sọ́nà láti ran àwọn ará lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣòro tí wọ́n lè bá pàdé nínú ríra ilẹ̀. A ní ìgbọ́kànlé pé àwọn alàgbà yóò tètè ṣiṣẹ́ lórí àbá tí àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn bá fún wọn, láti dín ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ tàbí àwọn ohun tí ń gbówó lọ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kù.
10 Nígbà tí ẹ bá ń yan ilẹ̀ fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ìlú tí ó ní jú ìjọ kan lọ, ó yẹ kí àwọn alàgbà àdúgbò jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, (àwọn) alábòójútó àyíká, alábòójútó ìlú ńlá, àti bí ó bá ṣeé ṣe, pẹ̀lú àwọn alàgbà tí ó wà ní àwọn ìjọ ìtòsí. Èyí lè ran àwọn alàgbà àdúgbò lọ́wọ́ nínu yíyan ibì kan tí yóò ṣàǹfààní fún (àwọn) ìjọ tí ń lọ́wọ́ nínú ìdáwọ́lé lọ́ọ́lọ́ọ́ náà, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó dín àkúnya ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò kù, tí yóò sì tún fàyè sílẹ̀ fún ìbísí ọjọ́ iwájú ní agbègbè náà. Ní àwọn agbègbè ìgboro ìlú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó jẹ́ pé ìjọ mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àní ní àwọn ibi tí àwọn ènìyàn kò ya sí pàápàá, a lè yan agbègbè kan tí ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lò.
11 Ní lílo ìtọ́sọ́nà tí Society pèsè, àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ń pèsè ìrànlọ́wọ́ wíwúlò, bí wọ́n ti ń ran àwọn ìjọ àdúgbò lọ́wọ́ nínú ìdáwọ́le ti ṣíṣàtúnṣe àti àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tuntun. Nígbà tí ìkọ́lé bá bẹ̀rẹ̀, a máa ń ṣètò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni fún àkókò tí a óò nílò wọn ní ti gidi, níbi ìkọ́lé náà, kí wọ́n má baà pàdánù nínípìn-ín nínú ìpàdé àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá, ti ìjọ wọn. Ètò àti òye iṣẹ́ tí wọ́n kọ́ nínú àwọn ìdáwọ́lé wọ̀nyí yóò tún ṣèrànwọ́ nínú ìdáwọ́lé kíkọ́ Ilẹ̀ Àpéjọ.
12 Gbogbo wá lè mú èso inú rere dàgbà nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń bojú tó ìgbòkègbodò ilé kíkọ́ náà. Ní ọ̀nà yìí, à ń ṣe iṣẹ́ tí a ní í ṣe náà “ní kíkún” a sì ń ṣe é “pẹ̀lú ìdùnnú kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn.” (Ìṣe 14:26; Heb. 13:17) Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti Èkó ṣe àlàyé yìí nínú ìròyìn ọdọọdún wọn: “Ìrírí wa ní ọdún 1995 ti ru ìmọ̀lára wa sókè gidigidi, ó sì ti méso wá. Society àti àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tẹnu mọ́ mímọ ète àti ẹrù iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní onírúurú ìpàdé pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn alàgbà àti/tàbí ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ní gbogbo ẹkùn agbègbè náà. Síwájú sí i, yóò dára láti sọ pé a ti parí àwọn ìdáwọ́lé kan lórí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, nígbà tí àwọn mìíràn ṣì ń lọ lọ́wọ́ tàbí ń bọ̀ lọ́nà. A kọ́ díẹ̀ lára àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni/òṣìṣẹ́ wa ní ọdún náà, wọ́n sì ti já sí ìbùkún ńlá nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aláǹfààní ṣíṣeyebíye yìí.”
13 Gbígbé Ẹrù Ìnáwó Ìdáwọ́le Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ó yẹ kí a ṣètò fún ìnáwó èyíkéyìí tí a nílò ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. (Luk. 14:28-30) Àwọn alàgbà ní láti pinnu agbára ìjọ náà láti san gbogbo owó tí yóò ná wọn, nípa ṣíṣe ìwádìí láti pinnu (1) èló ni ẹ óò lè gbé sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan láti ṣètìlẹ́yìn fún ríra ilẹ̀ àti kíkọ́ ilé, (2) èló ni ẹ lè rí yá ládùúgbò, àti nígbà wo ni owó náà yóò lè tẹ̀ yín lọ́wọ́, àti (3) èló ni àwọn akéde ní lọ́kàn láti fi ṣètọrẹ lóṣooṣù láti san owó èyíkéyìí tí ẹ bá yá, ní àfikún sí bíbójú tó àwọn ìnáwó àtìgbàdégbà.
14 Lẹ́yìn náà, àwọn alàgbà àwọn ìjọ tí ń fẹ́ láti yáwó nínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọbá ní láti jíròrò ìdáwọ́lé tí wọ́n ń wéwèé náà àti iye tí yóò ná wọn pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn wọn, tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa fífi àìní wọn àti kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdáwọ́lé náà tó Society létí ní lílo fọ́ọ̀mu Kingdom Hall Loan Survey. Lẹ́yìn tí àwọn alàgbà bá ti kọ ọ̀rọ̀ kún apá tí ó kàn wọ́n lóri fọ́ọ̀mù náà, alábòójútó àyíká yóò kọ àlàyé rẹ̀ kún un, yóò sì dá fọ́ọ̀mù náà padà sọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, fún àlàyé tiwọn. Àwọn pẹ̀lú yóò pari kíkọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù náà, wọn yóò sì fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ṣọwọ́ sí Society. Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn bá ti fi ìsọfúnni ṣọwọ́ sí Society, a óò kọ̀wé ní tààràtà sí ìjọ tí ọ̀rán kàn. A óò máa pèsè owó ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, bí owó bá ti ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ àti bí àìní náà bá ṣe pọ̀ sí.
15 Pa Ẹ̀mí Onítara Mọ́: Gbogbo ìjọ ni ó yẹ láti gba oríyìn fún ìwà ọ̀làwọ́ wọn nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. A ti gba ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìmọrírì láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọ tí a ti ràn lọ́wọ́. “Ìmúdọ́gba” ń wáyé láàárín àwọn ìjọ. (2 Kọr. 8:14, 15) Ìjọ kan ní Ohafia kọ̀wé pé: “Àwa, mẹ́ḿbà ìjọ lódindí fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ki yín fún gbígbé Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba kalẹ̀, àti ní pàtàkì fún dídá Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn sílẹ̀, tí a ń jàǹfààní láti inú rẹ̀ nísinsìnyí. Gbogbo ìgbà ni a máa ń rántí yín nínú àdúrà wa, a sì máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣètìlẹ́yìn fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ yín yòókù.” Ìjọ mìíràn ní Ikom, ní Ìpínlẹ̀ Cross River, pẹ̀lú kọ̀wé pé: “A ń tipa báyìí fi ìdùnnú àti ìmọrírì wa hàn fún dídá tí ẹ dá Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti ẹkùn Ìlà Oòrùn sílẹ̀. Ní October 5, 1995, nígbà tí a ṣèpàdé pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, a fún wa nítọ̀ọ́ni nípa bí ó ṣe yẹ kí a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ibi tí ó yẹ kí a kọ́ ọ sí. Ní títẹ̀ lé ìtọ́ni náà, a rí ìdí láti wá ilẹ̀ míràn yàtọ̀ sí èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀. A ti jàǹfààní láti inú ètò àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe yìí, pé kí a dá ìgbìmọ̀ kan bí irú èyí sílẹ̀.”
16 Nígbà tí a bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ìmóríyá, ìtara, àti ẹ̀mí tí ń gbéni ró máa ń fi kún àṣeyọrí ìdáwọ́lé náà. Ó yẹ kí a máa bá ẹ̀mí kan náà nìṣó, bí a ti ń làkàkà láti mú ọ̀pọ̀ sí i wá sínú ìmọ̀ òtítọ́, tí a sì ń fún wọn níṣìírí láti pé jọ pọ̀ pẹ̀lú wa nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Irú ìtara bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìfìmọrírì hàn, tí ń yọrí sí ìbísí ńlá nínú iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé àti nínú ìbísí ìjọ lódindi.
17 Bí a ti ń bá a lọ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, ní fífi tokuntokun tiraka nínú iṣẹ́ tí ń bẹ lọ́wọ́, láìsí àníàní, ìbùkún Jèhófà yóò máa bá a lọ lórí wa. (Luk. 13:24) A kò mọ ìmúgbòòrò àti ìbísí tí ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí a gbara dì láti tẹ́wọ́ gba ìrọ́wọlé àwọn olùjọ́sìn, tí ó lè wà ní ọjọ́ iwájú. Ìyẹ́n ń béèrè ìmúrasílẹ̀ ní ìhà ọ̀dọ wa. Nítorí náà, a ń gbàdúrà fún ìbùkún àti ìdarí Jèhófà tí ń bá a lọ. Ní kíkọ́lé fún ọjọ́ ọ̀la, ǹjẹ́ kí gbogbo wá jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà—nípa ti ara, pẹ̀lú ohun àmúṣọrọ̀ wa, àti nípa tẹ̀mí. Dájúdájú, òun yóò bù kún wa, bí a ti ń bójú tó àwọn tí ń rọ́ wá sínú ètò àjọ Ìjọba rẹ̀ ní apá ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí dáradára.—Aisa. 60:8, 10, 11, 22.