ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/98 ojú ìwé 3-4
  • Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Fífi Ìdùnnú Kúnjú Àìní Ìkórè Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ojúṣe Rẹ Nínú Kíkọ́lé fún Ọjọ́ Ọ̀la
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 8/98 ojú ìwé 3-4

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà

1 Nígbà tí a bá wo pápá kárí ayé, o múni lọ́kàn yọ̀ láti rí ìbísí gígadabú tí ètò àjọ Jèhófà ti orí ilẹ̀ ayé ń nírìírí rẹ̀! Ní ọdún tí ó kọjá ní Nàìjíríà nìkan, 172 ìjọ tuntun ni a dá sílẹ̀, nígbà tí a sì fi àròpọ̀ 3,348 àwọn ìjọ kún un kárí ayé. Pẹ̀lú gbogbo ìbísí yìí, kò yani lẹ́nu pé a nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i.

2 Ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin ń fi ìtara àti ìtìlẹyìn tí ó ga lọ́lá hàn fún ètò àjọ Jèhófà nípa yíyọ̀ǹda àkókò àti ohun ìní wọn fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn 25 tí ń ṣiṣẹ́ ní Nàìjíríà ń bójú tó àìní nǹkan bí 160 ìjọ kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ẹkùn olúkúlùkù wọn. A ti fi àbójútó ilé kíkọ́ àti títún wọn ṣe síkàáwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn, a sì mọrírì làálàá wọn. Gbogbo ìṣètò fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí Kristẹni ti fífúnni àti fífi ara ẹni rúbọ—òdì-kejì ẹ̀mí tí ó wọ́pọ̀ gan-an tí àwọn ènìyàn ń fi hàn nínú ayé.—2 Tím. 3:2, 4.

3 Láti ṣèrànwọ́ ní mímú kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba dọ́gba, Society ti pèsè àwọn àpẹẹrẹ àwòrán Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn. Èyí yóò ṣèrànwọ́ láti dín àkókò àti ohun àmúṣọrọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí ó yọ̀ǹda ara wọn kù. Èyí yóò tún ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí a fi ọgbọ́n lo Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn alàgbà lè yan èyí tí wọ́n bá fẹ́ nínú àwọn àwòrán náà báyìí. Níní àwòrán yìí yóó ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí a ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó bára mu, tí ó sì rí bákan náà délẹ̀. Bí àwọn ìjọ ti ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní ṣíṣètìlẹyìn fún mímú kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba bára mu, a fojú sọ́nà pé ẹrù púpọ̀ lára àwọn olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé, ayàwòrán ilé, àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, àti àwọn òṣìṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe mìíràn tí wọ́n fi tinútinú yọ̀ǹda láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ náà, ni a óò mú fúyẹ́ gan-an.

4 Oríṣiríṣi Ọ̀nà Ni A Lè Gbà Ṣe É: Ìpinnu nípa bóyá kí a háyà Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kí a kọ́ ọ ni ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe ní àdúgbò. Àwọn ni yóò tún bójú tó ìnáwó lórí ìkọ́lé èyíkéyìí àti àbójútó. Kí a lè dín owó kù, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìjọ ti sakun láti ṣe èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà bí ó ti lè ṣeé ṣe tó pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ó ní ìmọ̀ iṣẹ́.

5 Àwọn gbọ̀ngàn náà gan-an ni a lè fi bíríkì, búlọ́ọ̀kù onísìmẹ́ǹtì, yẹ̀pẹ̀, igi, tàbí àwọn ohun èlò mìíràn kọ́, ó sinmi lórí owó tí yóò náni àti ohun tí ó wà lọ́wọ́ àti ohun tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní àgbègbè náà. Ó bani nínú jẹ́ láti sọ pé, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ládùúgbò ni a kò tíì parí àní lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pàápàá. Àwọn olùfìfẹ́hàn kan ti lo ipò tí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wà tàbí ibi tí ó wà gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti má ṣe wá sí àwọn ìpàdé. Láìsí àní-àní, nígbà tí a bá kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó dára tí ó sì bójú mu, yóò ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí iṣẹ́ wa ṣe pàtàkì lójú àwọn ará àdúgbò.

6 Ọ̀kan nínú ìdí tí a kì í fi parí Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lè jẹ́ nítorí pé ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó tóbi jù tàbí tí wọ́n dáwọ́ lé èyí tí ó jẹ́ olówó gọbọi, kìkì láti rí i pé wọn kò lè parí rẹ̀ nítorí àìsí owó. Àwọn púpọ̀ kò ‘kọ́kọ́ jókòó, kí wọ́n sì gbéṣirò lé ìnáwó náà’ láti rí i bóyá àwọn akéde yóò lè san owó tí yóò parí iṣẹ́ náà. (Lúùkù 14:28) Àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ tí ó wà lọ́wọ́, ó sì wá di dandan fún wọn láti dáwọ́ dúró fún ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó lè máa bá a lọ. Bí ìyẹn bá ti ṣẹlẹ̀ sí yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn àgbègbè yín. A ti sọ fún wọn pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí píparí ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí a kò tíì parí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kí a lè yà wọ́n sí mímọ́.

7 Lílo ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà bẹ̀rẹ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan kí a sì parí rẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú gan-an. Kí àwọn ìjọ tí ó bá ń ronú nípa kíkọ́ gbọ̀ngàn ìjọba tuntun gbé ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ṣì ń ṣiyèméjì pé a lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, kí a parí rẹ̀, kí a sì yà á sí mímọ́ láàárín oṣù kan péré. Ṣùgbọ́n, a ti ṣe èyí ní ibi méjì ní Nàìjíríà (Ewossa ní Ìpínlẹ̀ Ẹ̀dó àti Dọ̀pẹ̀mú ní Ìpínlẹ̀ Èkó), inú àwọn ará sì dùn láti rí i. Inú wa yóò dùn láti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i tí a kọ́ lọ́nà yìí.

8 Ní Èkó, kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 25 sẹ́yìn. Láìpẹ́ yìí, àwọn ìjọ tí ń lò gbọ̀ngàn náà pinnu láti parí rẹ̀ kí wọ́n sì yà á sí mímọ́. Nígbà tí wọ́n ń ṣe èyí, wọ́n ronú pé yóò dára láti kọ́ gbọ̀ngàn mìíràn láti dín àpọ̀jù àwọn ènìyàn kù nínú gbọ̀ngàn tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Níwọ̀n bí àwọn tí yóò lo gbọ̀ngàn ìjọba tuntun náà ti jẹ́ ara àwọn ìjọ tí ó ti ń náwó lórí gbọ̀ngàn tí ó wà tẹ́lẹ̀, wọ́n ronú pé ó yẹ kí wọ́n parí gbọ̀ngàn méjèèjì, kí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́ lẹ́ẹ̀kan náà. Nípa lílo ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá, kíkọ́ gbọ̀ngàn tuntun náà parí láàárín ọjọ́ 15 péré, wọ́n sì ya gbọ̀ngàn méjèèjì sí mímọ́ ní ọjọ́ kan náà.

9 Níwọ̀n bí àkókò tí ó ń gbà láti parí iṣẹ́ ìkọ́lé kíákíá ti máa ń kúrú gan-an, a dámọ̀ràn pé kí ìjọ èyíkéyìí tí ó bá fẹ́ lo ọ̀nà ìgbàkọ́lé yìí kọ́kọ́ gba àwọn ìwé àṣẹ tí ó tọ́, àwòrán ilẹ̀, àti àwòrán ilé tí ìjọba ti fọwọ́ sí. Bí ó ti sábà máa ń rí, ó dára jù pé kí ẹ ti gba ìwé àṣẹ ìkọ́lé kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà. Àmọ́ ṣá o, níbi tí ìyẹn kò bá ti ṣeé ṣe, kí ẹ ti béèrè fún irú ìwé àṣẹ bẹ́ẹ̀ nígbà tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé náà, kí ẹ sì máa bá a lọ láti ṣiṣẹ́ lórí gbígba ìwé àṣẹ náà taápọntaápọn. Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ kó àwọn ẹ̀dà ìwé ilẹ̀ yín ránṣẹ́ sí Society fún àyẹ̀wò. A óò pèsè owó nípasẹ̀ ètò Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba bí ìjọ bá fẹ́ gba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìjọ èyíkéyìí tí ó fẹ́ láti kọ́lé nípa lílo ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá yìí kọ́kọ́ jíròrò iṣẹ́ náà pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn àdúgbò wọn. Kí wọ́n fi ìwé ìbéèrè wọn ránṣẹ́ sí Society.

10 Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Ṣètìlẹ́yìn fún Iṣẹ́ Àtàtà: Society kún fún ìmoore fún ọ̀pọ̀ àwọn tí ó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó múni láyọ̀ ní tòótọ́ láti rí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn nínú gbogbo apá iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àṣeyọrí ìṣètò yìí ṣeé ṣe nítorí irú ẹ̀mí ìmúratán, ọ̀làwọ́, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ níhà ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí ó yọ̀ǹda ara wọn, àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda àkókò tí wọn ì bá ti lò pẹ̀lú ìjọ àti ìdílé wọn. (Sm. 110:3; Kól. 3:23) Ìdáhùnpadà onífẹ̀ẹ́ yìí mú kí wọ́n yẹ fún ìgbóríyìn, ìmọrírì, àti ìtìlẹyìn wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.—Róòmù 12:10; Héb. 13:1.

11 Gbogbo àwọn tí ó bá tóótun láti ṣèrànwọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ni a ti sọ fún pé kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Volunteer Worker Questionnaire (S-82). Àwọn fọ́ọ̀mù yìí ni ìjọ ń fi ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn láti fi ìtóótun òṣìṣẹ́ hàn àti bí ó ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó sí. Nígbà tí ìyípadà bá dé bá ipò tí olùyọ̀ǹda ara ẹni kan wà, bí ìgbà tí ẹnì kan bá ṣí lọ, tàbí tí a bá yàn án gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, kí a kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù tuntun lọ́gán, kí akọ̀wé ìjọ sì fi í ránṣẹ́. Bí olùyọ̀ǹda ara ẹni kan kò bá tóótun mọ́, kí àwọn alàgbà fi tó ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípasẹ̀ lẹ́tà. Bí ẹ bá nílò fọ́ọ̀mù púpọ̀ sí i, ẹ lè béèrè fún wọn lórí fọ́ọ̀mù Literature Order Form olóṣooṣù. Alábòójútó àyíká pẹ̀lú lọ́kàn-ìfẹ́ nínú àwọn tí ó ti yọ̀ǹda ara wọn nínú pápá iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ yìí. Nítorí náà, kí ó ṣàtúnyẹ̀wò fáìlì tí àwọn ẹ̀dà kejì ti fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Volunteer Worker Questionnaires wà ní gbogbo ìgbà tí ó bá ṣèbẹ̀wò sí ìjọ.

12 Mímú Kí Owó Ìkọ́lé Mọ Níwọ̀n: Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ni a ti sọ fún pé kí wọ́n ṣètò ẹ̀ka iṣẹ́ tí yóò máa rajà lábẹ́ ìdarí alàgbà kan tí ó dáńgájíá. Àwọn arákùnrin tí ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka yìí yóò fi taápọntaápọn máa gba ìsọfúnni nípa ibi tí a ti lè rí ọjà rà kí a lè wá àwọn ọjà tí owó rẹ̀ rọjú kàn nípa fífi owó ọjà wéra, kí a sì dúnàá dúrà rẹ̀ dáadáa. Lọ́nà yìí, a wá lè ṣe ìpinnu nípa àwọn tí a óò máa gbọjà lọ́wọ́ wọn, àti irú àwọn ohun èlò tí a óò rà. Nígbà mìíràn, nígbà tí iṣẹ́ bá ń lọ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, àwọn arákùnrin tí ó tóótun ní ìjọ àdúgbò ni a máa ń ké sí láti ṣèrànwọ́ ní ẹ̀ka yìí. Nígbàkigbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, yálà a ń kọ́ tuntun tàbí a fẹ́ tún un ṣe, tí yóò béèrè lílo olùyọ̀nda ara ẹni láti àwọn ìjọ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tàbí àwọn tí ń ṣe ìpàdé nínú gbọ̀ngàn náà, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn ni yóò bójú tó iṣẹ́ náà.

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú aráyé ti di tútù ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń bá a nìṣó láti fi ẹ̀rí ìfẹ́ wọn hàn fún ẹnì kìíní-kejì, ìfẹ́ tí ó ré kọjá ààlà ẹ̀ya ìran àti ti ìpínlẹ̀. (Mát. 24:12) Ní àfarawé Baba wa ọ̀run, ǹjẹ́ kí a máa bá a lọ láti fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìmúratán wa láti ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wa yóò mú ìbùkún jìngbìnnì àti ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà wá.—Mál. 3:10; Héb. 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́