Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́
1. Ibi tó lámì wo la ti bá iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba dé, síbẹ̀ kí ló tún kù ká ṣe?
1 Láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, Gbọ̀ngàn Ìjọba 1,205 ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Nàìjíríà ti kọ́. Ní tòdodo, a mọrírì iṣẹ́ tí Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti gbogbo àwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti bá iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba dé ibi tó lámì, a ṣì ní púpọ̀ sí i láti ṣe. Báwo ni gbogbo wa ṣe wá lè ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ pàtàkì tó jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà yìí?—Ìṣí. 7:15.
2. Ọ̀nà wo la lè gbà ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn ní tààràtà?
2 Yọ̀ǹda Ara Rẹ: Bó o bá jẹ́ akéde tó ní ìdúró rere nínú ìjọ tó o sì ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tàbí tó o ti jù bẹ́ẹ̀ lọ, à ń ké sí ọ láti yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà tí iṣẹ́ bá kan Gbọ̀ngàn Ìjọba yín tàbí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò yín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan láti kọ̀wé béèrè fún àǹfààní yìí, kìkì àwọn tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ bá fọwọ́ sí nìkan la lè pè láti wá lọ́wọ́ sí iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ládùúgbò wọn. (Sm. 110:3) A retí pé kí gbogbo ẹni tó bá máa yọ̀ǹda ara rẹ̀ jẹ́ ẹni táá fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́, kó sì tún jẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀. (Sm. 133:1) Kódà kó o má tiẹ̀ mọṣẹ́ ọwọ́ èyíkéyìí, ọ̀pọ̀ nǹkan lo ṣì lè ṣe táá pa kún àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà. O sì tún lè kọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mìíràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ wúlò lọ́jọ́ iwájú.
3. Àwọn ọ̀nà mìíràn wo la lè gbà ti ìṣètò yìí lẹ́yìn?
3 Bí kò bá ní ṣeé ṣe fún ọ láti yọ̀ǹda ara rẹ, o ṣì lè ṣètìlẹyìn nípa fífún àwọn tó lè yọ̀ǹda ara wọn níṣìírí. O lè ṣèrànwọ́ nípa bíbá àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú ìjọ. Bí àwọn alàgbà bá ṣètò ṣáájú, ìjọ ò ní lálàṣí látàrí pé àwọn kan látinú ìjọ wọn wà lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò síyè méjì pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí wa tá à ń pawọ́ pọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń mú ìlọsíwájú bá Ìjọba Rẹ̀.—Héb. 13:16.
4. Báwo la ṣe lè máa fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba níṣìírí?
4 Máa Fún Àwọn Ẹlòmíràn Níṣìírí: Iṣẹ́ àṣekára ni iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa, ó sì máa ń gba àkókò púpọ̀. Kò ní yani lẹ́nu nígbà náà pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ò ní lè máa dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ wọn. Nítorí náà, á dára ká máa tara ṣàṣà láti máa yin àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé, tí wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn nǹkan kan du ara wọn láti lè bójú tó iṣẹ́ “tí ó pọn dandan yìí,” ká sì máa fún wọn níṣìírí.—Ìṣe 6:3; Róòmù 14:19.
5. Báwo làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ṣe lè rí i pé àwọn ò pọ̀n síbì kan?
5 Má Ṣe Pọ̀n sí Apá Kan: Àkọ́kọ́ nínú ìgbòkègbodò ìjọsìn wa ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 13:10) Ìdí nìyẹn tí Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fi máa ń rí i pé àwọn ṣètò iṣẹ́ náà lọ́nà tó fi jẹ́ pé bí kì í bá ṣe pé ó pọn dandan, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà gbọ́dọ̀ lè máa dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ wọn. Bákan náà, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé gbọ́dọ̀ gbìyànjú kí wọ́n má ṣe pa ọ̀kan tì nínú ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó wà níkàáwọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ìkọ́lé dí wọn lọ́wọ́ láti lọ sáwọn àpéjọ àtàwọn àpéjọpọ̀. Bákan náà, ìjọ tí alábòójútó àyíká bá máa bẹ̀ wò lásìkò tí wọ́n bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn lọ́wọ́ máa ń sapá láti rí i pé àwọn jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́sẹ̀ náà láìjẹ́ pé iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà dúró.
6. Kí la máa lè ṣe láṣeyọrí bí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí ìjọsìn tòótọ́ bàa lè máa tẹ̀ síwájú?
6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ará tó wà nínú ìjọ ń jùmọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan ‘kí ara náà bàa lè dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.’ (Éfé. 4:16) Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti sí ìjọsìn tòótọ́ ló máa jẹ́ ká lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti wàásù ìhìn rere náà ká sì tún máa ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn.