Àwòkọ́ṣe fún Tèwe Tàgbà
Àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run dán mọ́rán. Ìfẹ́ Jèhófà ló ń fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ṣe. Ó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” ó sì rí èrè rẹ̀ gbà. Nóà là ń sọ, àpẹẹrẹ tó yẹ kí tèwe tàgbà máa tẹ̀lé. (Jẹ́n. 6:9) Fídíò Nóà bá Ọlọ́run rìn tá a ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Noah—He Walked With God máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fọkàn yàwòrán bí Nóà ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀, àtohun tó mú kó tọ́ sí ìbùkún Jèhófà, wàá sì rí bó o ṣe lè fara wé àwọn ànímọ́ rere tó ní.
Wo fídíò náà, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: (1) Ohun tó burú wo làwọn áńgẹ́lì kan ṣe, àwọn wo sì làwọn Néfílímù? (Jẹ́n. 6:1, 2, 4) (2) Kí ló mú káwọn èèyàn di ẹni búburú bẹ́ẹ̀, báwo ni ìwà búburú tí wọ́n hù sì ṣe rí lójú Ọlọ́run? (Jẹ́n. 6:4-6) (3) Kí ló jẹ́ kí Nóà yàtọ̀ ní tiẹ̀? (Jẹ́n. 6:22) (4) Báwo làwọn ẹni burúkú náà ṣe pa run? (Jẹ́n. 6:17) (5) Báwo ni áàkì náà ṣe tóbi tó? (Jẹ́n. 6:15) (6) Nǹkan míì wo ni Nóà ṣe, ojú wo làwọn èèyàn sì fi wò ó? (Mát. 24:38, 39; 2 Pét. 2:5) (7) Mélòó ni oríṣi ẹranko kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọkọ̀? (Jẹ́n. 7:2, 3, 8, 9) (8) Ọjọ́ mélòó ni òjò fi rọ̀, ọjọ́ mélòó ni omi náà sì lò lórí ilẹ̀ kó tó gbẹ? (Jẹ́n. 7:11, 12; 8:3, 4) (9) Kí ló mú kí Nóà àti ìdílé rẹ̀ la ìkún omi náà já? (Jẹ́n. 6:18, 22; 7:5) (10) Ibo ni áàkì náà gúnlẹ̀ sí? (Jẹ́n. 8:4) (11) Báwo ni Nóà ṣe mọ ìgbà tó yẹ láti jáde kúrò nínú áàkì? (Jẹ́n. 8:6-12) (12) Kí ni Nóà ṣe nígbà tó jáde kúrò nínú áàkì? (Jẹ́n. 8:20-22) (13) Kí ni òṣùmàrè dúró fún? (Jẹ́n. 9:8-16) (14) Báwo lèèyàn ṣe lè ‘bá Ọlọ́run rìn’? (Jẹ́n. 6:9, 22; 7:5) (15) Bá a bá fẹ́ rí Nóà nínú Párádísè, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (Mát. 28:19, 20; 1 Pét. 2:21)
Látinú ohun tí àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ nípa Nóà, tó fi òótọ́ inú ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ tó lè jẹ́ kí ìwọ alára mọ bó o ṣe lè ‘bá Ọlọ́run rìn’ kó o sì ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà lágbára láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní là?—Jẹ́n. 7:1; Òwe 10:16; Héb. 11:7; 2 Pét. 2:9.