ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/06 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 5/06 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù May: Ká lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìjọ, kí a fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fi ìwé yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”

◼ Níwọ̀n bí oṣù July ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa jẹ́ oṣù tó túbọ̀ rọrùn láti ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Kí alága àwọn alábòójútó tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bẹ́ ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń tọ́jú owó sí fún bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, kó ṣàyẹ̀wò èyí pẹ̀lú. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.

◼ Kẹ́ ẹ tó dáwọ́ lé iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ì báà jẹ́ tuntun tàbí èyí tẹ́ ẹ fẹ́ tún ṣe, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kàn sí àwọn arákùnrin tó wà ládùúgbò tí wọ́n ń ṣèrànwọ́ fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kẹ́ ẹ sì tún kàn sí wọn bẹ́ ẹ bá fẹ́ ralẹ̀ tàbí tẹ́ ẹ bá fẹ́ ta ilẹ̀. Àwọn arákùnrin tó ń ṣèrànwọ́ fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bá jẹ mọ́ ọ̀ràn ilẹ̀, ó sì tún ṣeé ṣe kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi lè tóótun láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déètì tí akéde náà fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà ò bá lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déètì kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déètì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (bi12 eléèpo ẹ̀yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́)—Gẹ̀ẹ́sì

Watch Tower Publications Index 2003—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà

◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà—Lórí Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, kásẹ́ẹ̀tì kan)—Ìgbò

◼ Àwo DVD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Kọrin Ìyìn sí Jehofah—Lórí Àwo DVD, Apá 3—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Tún Ti Wà Lọ́wọ́ Báyìí:

Hellfire—Is It Part of Divine Justice? (fún àwọn Mùsùlùmí) (Ìwé Àṣàrò Kúkúrú No. 74)—Gẹ̀ẹ́sì

Kọrin Ìyìn sí Jehofah (Ìwé orin ńlá)—Yorùbá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́