ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/06 ojú ìwé 5-6
  • Ẹ Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Ayé Níbi Ìsìnkú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Ayé Níbi Ìsìnkú
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 5/06 ojú ìwé 5-6

Ẹ Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Ayé Níbi Ìsìnkú

1 Olùṣàkóso ayé yìí, ìyẹn Sátánì ń wá bó ṣe máa ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Nítorí ìyẹn ló ṣe ń jà fitafita láti mú wa tàpá sí ìlànà Bíbélì. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa yàgò fún un nígbà gbogbo tá ò bá fẹ́ di ara ayé tó wà lábẹ́ agbára rẹ̀, èyí tó máa tó pa run yán-án yán-án láìpẹ́.—Ják. 4:7; 1 Jòh. 2:15-17.

2 Apá pàtàkì kan tó yẹ ká ti wà lójúfò gidigidi ni nígbà tá a bá ń ṣe ètò ìsìnkú. A gbọ́dọ̀ pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ sí gbogbo àṣà ìsìnkú tó wá látinú ẹ̀kọ́ èké, ìjọsìn ẹ̀mí èṣù, àti ẹ̀mí ayé, bó bá ṣe wù kó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tàbí kó gbajúmọ̀ tó ládùúgbò tá à ń gbé. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa ń ṣe nínú àwọn ọ̀ràn míì, nígbà tá a bá wà níbi ìsìnkú, ohun tó gbọ́dọ̀ wà lórí ẹ̀mí wa ni bá ò ṣe ní lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó máa kó èérí bá ìjọsìn mímọ́, tó máa da ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ láàmú, tó máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn láàmú tàbí tó máa mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ó sàn kí wọ́n fi ìwọ̀sí lọ̀ wá, kí wọ́n fi wá ṣẹ̀sín, kí wọ́n takò wá, kódà kí wọ́n ṣenúnibíni sí wa bó bá jẹ́ pé ohun tó gbà nìyẹn, nítorí pé a ò juwọ́ sílẹ̀ lórí ìpinnu wa, ju pé ká lọ́wọ́ sí àṣà ìsìnkú tó tako Ìwé Mímọ́ nítorí àtirí ojúure tẹbí tọ̀rẹ́ tí wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa.

3 Pípín Ohun Ìrántí Níbi Ìsìnkú: Wọ́n máa ń pín àwọn ẹ̀bùn kan gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí. Ṣó yẹ ká máa há irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ níbi ìsìnkú? Ṣebí torí àtitu àwọn téèyàn wọn kú nínú la ṣe ń lọ sílé olókùú. Ìfẹ́ tó dénú àti àníyàn tó tọ́ lohun tó yẹ kó sún wa lọ kí mọ̀lẹ́bí téèyàn wọn kú náà, kò yẹ kó jẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan pé ká lè rí ẹ̀bùn gbà tàbí torí àtihá ẹ̀bùn fáwọn àlejò tó wá síbi ìsìnkú. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ retí pé kí àwọn tí òkú kú fún máa há ẹ̀bùn fáwọn tó wá kí wọn. Kódà bí agbára àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ bá tiẹ̀ ká a láti há ẹ̀bùn fáwọn tó wá, tó sì tọkàn wọn wá, wọ́n gbọ́dọ̀ rántí pé àsìkò ọ̀fọ̀ àti àkókò tó gba ìrònú ni àsìkò ìsìnkú kì í ṣe ibi pọ̀pọ̀ṣìnṣìn, kì í sì í ṣe ibi téèyàn á ti máa ṣe ṣekárími bíi híhá ẹ̀bùn, èyí tí wọ́n sábà máa ń kọ orúkọ ẹni tó há ẹ̀bùn náà sí lára. (Oníw. 7:2; 1 Jòh. 2:16) Ẹ̀bùn kọ́ làwọn abánikẹ́dùn lọ gbà níbẹ̀. Bá a bá fojú ìfẹ́ ará wò ó, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ló ṣeé ṣe kí wọ́n nílò ìrànwọ́ láti bójú tó ìnáwó ìsìnkú.—Ják.1:27.

4 Ìdí nìyẹn tí àpilẹ̀kọ náà, “Ìsìnkú Kristẹni—Apá Kẹrin,” tó jáde nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1994 ní ojú ìwé 3, fi sọ pé: ‘Àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ láti ṣètìlẹ́yìn ní ti ọ̀ràn ìnáwó fún àwọn ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Ète irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe láti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu fún àwọn ìbátan àti àlejò tí wọn kò gba tẹni rò, ṣùgbọ́n láti kájú ìnáwó pósí àti àwọn ìnáwó pípọndandan mìíràn.’ Fún ìdí yìí, a ò fẹ́ kẹ́ ẹ máa há ẹ̀bùn níbi ìsìnkú, torí kò sí àpẹẹrẹ irú àṣà bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì, kò sì sí oore kan tí àṣà náà ṣe àwọn tí èèyàn wọn ṣaláìsí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àṣà náà ń gbé ògo fún àwọn èèyàn tó sì ń mú àṣà ayé wọnú ètò ìsìnkú Kristẹni.—Róòmù 12:2.

5 Kíki Òkú: Níbi ìsìnkú, ṣe ló yẹ ká sapá láti tu àwọn téèyàn wọn kú nínú. (2 Kọ́r. 1:3-5) Kò sí ààyè fún ẹnikẹ́ni láti kà tàbí sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí nípa ẹni tó ṣaláìsí náà ṣáájú tàbí lẹ́yìn àsọyé ìsìnkú. Ẹni tó bá sọ àsọyé náà ò gbọ́dọ̀ sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tàbí ṣe ohunkóhun tó máa gbógo fún olóògbé náà. Dípò tá a fi máa sọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà di agbo àwọn tó ń ki aláìsí ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá, ohun tí ètò ìsìnkú wà fún ni láti fi gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lárugẹ, títí kan inúure rẹ̀ tó mú ká ní ìrètí àjíǹde. Alásọyé náà gbọ́dọ̀ rí i pé òun ò sọ ju ohun tó wà nínú ìwé àsọyé lọ, gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tó sì wà nínú rẹ̀, ṣe ni kó fọgbọ́n mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ rere tí ẹni tó kú náà ní. Bí ẹni náà bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi kú, ó máa dáa tí alásọyé bá ṣàṣàrò lórí bí olóògbé náà ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dọjọ́ tó ṣaláìsí. (Héb. 6:12) Jíjíròrò àwọn kókó dáadáa yìí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn níbi ìsìnkú á tu àwọn tó ṣì wà láàyè nínú á sì jẹ́ kí wọ́n lè máa rántí òkú náà sí rere.

6 Jíjẹ àti Mímu Níbi Ìsìnkú: Bíbélì sọ kedere pé ìyàtọ̀ wà láàárín “ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín; ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.” (Oníw. 3:4) Ní Oníwàásù 7:2, Bíbélì sọ pé “ilé ọ̀fọ̀” yàtọ̀ sí “ilé àkànṣe àsè.” Ohun tá a bá máa ṣe níbi ìsìnkú gbọ́dọ̀ yàtọ̀ gédégédé sí èyí tó máa ń wáyé níbi ìgbéyàwó. Ó hàn gbangba pé ibi ìsìnkú àwa Kristẹni kì í ṣe ibi àsè, kì í ṣe ibi tá a ti fẹ́ lọ jẹun, tá a ti fẹ́ lọ mu tàbí ibi tí orin á ti máa ròkè lálá.

7 Nítorí náà, ká tiẹ̀ lá a fẹ́ dáná rárá, ó yẹ ká ríyẹn bí ẹ̀mí ìmoore táwọn ẹbí aláìsí náà fi hàn fún kìkì àwọn abánikẹ́dùn tó wá láti ọ̀nà jíjìn tó jẹ́ pé kò lè rọrùn fún wọn láti máa wá oúnjẹ fúnra wọn torí pé àlejò ni wọ́n. (Fi wé Mátíù 15:32.) Kò yẹ kí àwọn tó ń gbé ní abúlé tàbí ìlú tó wà nítòsí gbà láti jẹ nínú oúnjẹ yẹn bí wọn ò bá fẹ́ dá kún ìnáwó àwọn mọ̀lẹ́bí òkú náà. Dípò ìyẹn, ṣe ló yẹ kí ìfẹ́ tiẹ̀ sún wọn láti gba àwọn abánikẹ́dùn tó wá látọ̀nà jíjìn bẹ́ẹ̀ sílé kí wọ́n sì tọ́jú wọn, èyí tó máa jẹ́ ìwàásù tó dáa fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọn ò sì mọ̀ ju kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n máa mu kí wọ́n sì máa jó níbi ìsìnkú. (Oníw. 3:4, 8) Nítorí náà, bó o bá ń lọ síbi ìsìnkú, fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1978, ojú ìwé 7, sọ́kàn pé, ‘gbogbo àwọn olùbẹ̀wò yóò fẹ́ láti fi ìgbatẹnirò hàn nípa ṣíṣàì hùwà ìmọtara ẹni ní ọ̀nà kan tí yóò dá kún ìnáwó tí ìdílé náà ti ń ṣe ní mímúra sílẹ̀ fún ìsìnkú náà. Dípò bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ohun rere fún wọn láti yọ̀ǹda ara wọn láti ran ìdílé náà lọ́wọ́ ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé àti jíjẹ́ iṣẹ́ fún wọn.’

8 Àìsùn Òkú àti Ìsìnkú Ẹlẹ́ẹ̀kejì: Ìgbàgbọ́ èké ló bí àṣà àìsùn òkú, ìyẹn ṣíṣọ́ tàbí dídáàbò bo òkú mọ́jú pẹ̀lú jíjẹ, mímu, kíkọrin àti lílu àwo orin. Ó jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti lé àwọn ẹ̀mí burúkú jìnnà kí ọkàn tàbí ẹ̀mí ẹni tó kú náà bàa lè dé ibi tó ń lọ láìséwu. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyè sí i pé ṣíṣètò irú àìsùn òkú bẹ́ẹ̀ tàbí lílọ síbẹ̀ ò bá ẹ̀kọ́ Kristẹni mu. Nítorí náà, Kristẹni kankan ò gbọ́dọ̀ ṣètò àìsùn òkú tàbí kó lọ síbẹ̀, ì báà jẹ́ lọ́wọ́ alẹ́ nìkan tàbí títí mọ́jú. Ìlànà yìí kan náà ló kan ìsìnkú ẹlẹ́ẹ̀kejì táwọn tó ń ṣe é sọ pé wọ́n “fi máa ń bá aláìsí náà palẹ̀ mọ́ fún ìgbésí ayé ‘láyé míì,’ wọ́n sì tún máa ń lò ó láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí òkú náà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ kó sì dáàbò bo àwọn.” Sátánì, baba èké ló wà nídìí gbígbé àṣà méjèèjì tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ èké yìí lárugẹ, pé nǹkan kan tí wọ́n ń pè ní ọkàn tàbí ẹ̀mí máa ń kúrò nínú ara nígbà téèyàn bá kú. (Jẹ́n. 2:7; Ìsík. 18:4, 20a; Sm. 22:29; Jòh. 8:44) Fún ìdí yìí, ẹnikẹ́ni tó bá lọ ṣàìsùn òkú, tó ṣe ẹ̀jọ òkú tàbí tó lọ́wọ́ sí i lọ́nà kan ṣá, ti lọ́wọ́ sí ìjọsìn òkú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò burú bí ẹnì kan bá sọ pé òun fẹ́ láti wo òkú ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí òun, síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí “títẹ́ òkú nítẹ̀ẹ́ ẹ̀yẹ” nínú èyí táwọn àlejò á ti máa tò kọjá níwájú òkú tí wọ́n á sì máa sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé wọ́n ń jọ́sìn rẹ̀.

9 Àwọn Nǹkan Míì: Àwọn àṣà mìíràn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n fi ń bọlá fún òkú tàbí tó fi hàn pé wọ́n ń bẹ̀rù òkú èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ni: ìjáde òkú lọ́jọ́ kẹjọ, lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, tàbí lẹ́yìn ogójì ọjọ́; fífá orí; gígé èékánná lọ́nà àrà ọ̀tọ̀; lílo oríṣi ìlẹ̀kẹ̀ kan sí àwọn ibì kan lára àti sísín gbẹ́rẹ́ sára nítorí òkú; àti sísọ òkú di òrìṣà nípa gbígbé e wọ onírúurú ilé àtàwọn ‘ibi pàtàkì’ kí wọ́n tó sin ín. (Léf. 19:28; Róòmù 1:21-25) Bákan náà, láwọn apá ibì kan ní Nàìjíríà, àṣà ìbílẹ̀ wọn ni pé kí wọ́n máa wọ irú aṣọ pàtó kan nígbà ìsìnkú nítorí ìbẹ̀rù òkú àti gẹ́gẹ́ bí àmì ọ̀wọ̀ fún òkú. Láwọn apá ibì kan ní Nàìjíríà, àwọn ìbátan, àwọn olóyè tàbí àwọn aráàlú máa ń gba òòyẹ̀ màlúù tàbí ewúrẹ́, adìyẹ, wáìnì àti iṣu. Wọ́n á pín in, kálukú á sì lọ se tiẹ̀ jẹ nílé. Àmọ́ kí wọ́n tó jẹ́ ẹ, wọ́n lè kọ́kọ́ ta ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sílẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń ta ọtí sílẹ̀ láti fi ṣètùtù. Ẹ̀mí àwọn baba ńlá wọn tó ti kú ni wọ́n ń fi èyí tù lójú. Ṣó yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n ń sin Jèhófà, tí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti mú wọn kúrò lábẹ́ àjàgà ìgbàgbọ́ èké, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àwọn àṣà ayé tún máa lọ́wọ́ sí àṣà wọ̀nyí? Málákì 3:18 tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn tó jẹ́ ti ayé. Bákan náà, 1 Jòhánù 5:21, kìlọ̀ fún wa kíkankíkan pé ká “ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”

10 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó jẹ́ olóòótọ́, à ń ṣọ̀fọ̀, a sì máa ń rántí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Síbẹ̀, òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì pé àwọn òkú kì í joró àti pé wọ́n máa tó jíǹde kì í jẹ́ kí ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ wa pàpọ̀jù. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣà wa, ṣe ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká dìrọ̀ mọ́ òtítọ́ inú Bíbélì ṣinṣin ká sì kọ àwọn àṣà ayé tó tako Bíbélì àtàwọn nǹkan míì tó jẹ́ ti ayé tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi ìsìnkú.—1 Kọ́r. 10:31; 2 Kọ́r. 6:14-18; Jòh. 17:16.

11 Bá a bá ń bá a lọ láti máa kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn àti ìránnilétí Bíbélì yìí tìṣọ́ratìṣọ́ra, a ó lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run a ó sì lè máa wù ú ní kíkún.—Kól. 1:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́