Ẹ Má Fara Wé Àwọn Èèyàn Ayé
1 Ọ̀kan lára ohun táwọn èèyàn ayé ń ṣe ni “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòh. 2:15-17) Àṣà yìí sì ti gbòde kan báyìí nínú báwọn èèyàn ṣe ń ki àṣejù bọ àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu ìgbéyàwó. Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n gbà ń fi ìgbéyàwó ṣòwò báyìí. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni ò tíì fi hàn pé àwọn kì í ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú ayé nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò ayẹyẹ ìgbéyàwó.—Jòh. 17:16; Róòmù 12:2.
2 Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan nínú ìjọ máa ń ṣe oríṣi ìgbéyàwó méjì, ìyẹn ti àṣà ìbílẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìgbéyàwó tí wọ́n á sì ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún méjèèjì. Èyí ti dá kún gbígbé tí ìgbéyàwó ń gbówó gegere lórí. Àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbéyàwó Tí Ó Lọ́lá—Apá 1: Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1994 sọ pé: ‘Ó ti di ohun tí ó pọn dandan tí ó sì bá a mu láti pèsè ìsọfúnni díẹ̀ nípa oríṣi ìgbéyàwó méjì tí a ní ní orílẹ̀-èdè yìí, àwọn ni Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó àti Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀. Oríṣi ìgbéyàwó méjèèjì wọ̀nyí ni ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ni ó bófin mu tí ó sì lọ́lá. Èyíkéyìí nínú méjèèjì ṣètẹ́wọ́gbà fún ìjọ Kristẹni.’
3 Àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbéyàwó Tí Ó Lọ́lá—Apá 2: Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1994, fi kún un pé: ‘Lójú ìwòye ohun tí a ti sọ yìí àti fún ìdí náà pé irú ìgbéyàwó méjèèjì ni ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ni ó bófin mu tí ó sì lọ́lá, ó pọn dandan láti pinnu èwo nínú méjèèjì ni o fẹ́ láti ṣe. Kò pọn dandan, kì í ṣe ohun àbéèrèfún, láti ṣe irú ìgbéyàwó méjèèjì papọ̀. Yálà kí o ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó tàbí Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀, pẹ̀lú ìforúkọsílẹ̀. Níwọ̀n bí sísan owó orí ìyàwó náà nínú ara rẹ̀ kò ti sọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ di èyí tí ó pé pérépéré tàbí lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láìsí fífa ìyàwó náà lé ọkọ ìyàwó lọ́wọ́, nígbà náà ẹnì kan tí ó fẹ́ ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó lè san owó orí ìyàwó láìṣe ìyókù nínú àwọn ohun tí àṣà ìbílẹ̀ béèrè fún.’
4 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1994 tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìpínrọ̀ 2 sọ nípa Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó pé: ‘A fún gbogbo gbòò níṣìírí láti ṣe irú ìgbéyàwó yìí nítorí pé ó pèsè ààbò tí ó gbópọn fún aya àti àwọn ọmọ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ náà kú, àti àwọn àǹfààní mìíràn pẹ̀lú.’ Àwọn àǹfààní mìíràn tó wà nínú Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó ni pé ó lè mú Kristẹni kan yàgò fún àwọn àṣà ayé tó lè ṣàkóbá fún orúkọ rere tí olúwa rẹ̀ ní nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ti Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó, kò sí ìdí fún ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gbàdúrà fún tọkọtaya, èyí tó jẹ́ àmúlùmálà ìgbàgbọ́, kìkì nítorí pé òun ni bàbá tàbí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyàwó náà ń gbé. Bákan náà ni òfin yìí lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn àṣà míì tó tako ohun táwa Kristẹni gbà gbọ́.
5 Pẹ̀lú àlàyé tá a ti ń bá bọ̀ yìí, ta ló yẹ kó pinnu irú ìgbéyàwó tó yẹ kẹ́nì kan ṣe? Àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbéyàwó Tí Ó Lọ́lá—Apá 3: Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1994 sọ lójú ìwé 3, ìpínrọ̀ 1 pé: ‘Kì í ṣe àwọn òbí bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí ni yóò ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ẹrù iṣẹ́ ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti kó wọnú àdéhùn ìgbéyàwó ni láti pinnu irú ìgbéyàwó tí wọ́n fẹ́, yálà Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó tàbí Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀. Kò sí ẹnì kankan tí ó ní ẹ̀tọ́ láti fipá mú ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti kó wọnú àdéhùn ìgbéyàwó náà láti ṣe irú ìgbéyàwó kan tàbí òmíràn. Àwọn ni ó ni ẹrù iṣẹ́ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Wọ́n tún lómìnira láti yan ibi tí wọ́n yóò ti ṣe ìgbéyàwó náà àti . . . ẹni tí yòó sọ ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó náà.’
6 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú, níwọ̀n bí kì í ti ṣe ojúṣe àwọn òbí láti pinnu irú ìgbéyàwó tí wọ́n máa ṣe, kò ní bójú mu fún ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn láti fi dandan lé e pé àfi tí wọ́n bá ṣe gbogbo ohun tí àṣà ìbílẹ̀ là sílẹ̀ kí wọ́n tó lè láǹfààní àtilo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ojúṣe ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ò ju pé kí wọ́n rí ẹ̀rí pé àwọn méjèèjì lórúkọ rere nínú ìjọ. Ọ̀nà tí wọ́n sì lè gbà mọ̀ ni nípa bíbéèrè lẹ́tà ìdámọ̀ràn látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ìjọ táwọn méjèèjì wà.
7 Bó bá jẹ́ pé Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó ni, ọkọ àtàwọn àna ẹ̀, ìyẹn bó bá pọn dandan, ni wọ́n máa mọ bí wọ́n á ṣe yanjú ọ̀rọ̀ sísan owó orí ìyàwó láàárín ara wọn. Bó bá pọn dandan, wọ́n lè ṣàdéhùn ọjọ́ tí ọkọ́ á san owó orí ìyàwó láìṣe ayẹyẹ. Ohun tó mú ká sọ èyí ni pé Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó pé pérépéré ó sì ṣètẹ́wọ́gbà láìsan owó orí ìyàwó kankan. Nípa báyìí, ó máa ṣeé ṣe láti dín ìnáwó kù lọ́pọ̀lọpọ̀ bó bá jẹ́ àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu kan ṣoṣo ló wáyé dípò méjì—ọ̀kan fún Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ àti òmíràn fún Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó.
8 Kókó mìíràn tá a tún fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín fífi orúkọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ sílẹ̀ àti ṣíṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó. Bí àwọn tó fẹ́ di tọkọtaya náà kò bá tíì ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀, bí wọ́n bá lọ forúkọ ìgbéyàwó náà sílẹ̀ ní Káńsù, kódà kí ìwé àṣẹ tí wọ́n fún wọn dà bí èyí tí wọ́n máa ń fún àwọn tó bá ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó gẹ́lẹ́, ìyẹn Form E, ìgbéyàwó náà ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi sọ́kàn pé Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó yàtọ̀ sí fífi orúkọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ sílẹ̀ o. Kò dìgbà tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ kó tó lè ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó. Ohun tí òfin sọ ni pé kí ọ̀kan tàbí àwọn méjèèjì tó ń gbèrò láti ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó lọ fi orúkọ sílẹ̀ ní ibi ìforúkọsílẹ̀ ìgbéyàwó, ìyẹn Marriage Registry gẹ́gẹ́ bí àfẹ́sọ́nà tó fẹ́ di tọkọtaya ní ọjọ́ mọ́kànlélógún ṣáájú. Lópin ọjọ́ kọkànlélógún tí wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ yìí ni wọ́n á padà lọ gba fọ́ọ̀mù kan tí wọ́n ń pè ní Form C, èyí táá wá jẹ́ kí wọ́n lè fi Form E so wọ́n pọ̀ bíi tọkọtaya ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní ibi ìforúkọsílẹ̀ ìgbéyàwó, ìyẹn Marriage Registry. Bí gbogbo àwọn tó yẹ kó buwọ́ lu fọ́ọ̀mù tí wọ́n ń pè ní Form E yìí bá ti buwọ́ lù ú, tí wọ́n sì fi lé tọkọtaya lọ́wọ́, Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó ti ṣe nìyẹn. Kò pọn dandan kí wọ́n tún ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ mọ́. Bó bá ṣe wù kí fọ́ọ̀mù táwọn èèyàn fi ń forúkọ ara wọn sílẹ̀ bíi tọkọtaya lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ jọ fọ́ọ̀mù Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó tó, a ò gbọ́dọ̀ fi fíforúkọ ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láwọn àdúgbò kan, perí Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó.
9 Ẹni tó bá pinnu àtiṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá máa ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, ó gbọ́dọ̀ forúkọ ìgbéyàwó náà sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ sọ fún òjíṣẹ́ náà pé òun fẹ́ forúkọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ tóun ti ṣe sílẹ̀, òjíṣẹ́ yẹn ló máa wá fún un ní fọ́ọ̀mù tí wọ́n fi máa ń ṣe ìforúkọsílẹ̀ irú ìgbéyàwó tó ti wáyé bẹ́ẹ̀. Ọkọ nìkan lè lọ fi orúkọ ìgbéyàwó náà sílẹ̀, wọ́n sì lè ní káwọn méjèèjì wá. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè pọn dandan pé kí bàbá tàbí alágbàtọ́ ọmọbìnrin náà wà níbi ìforúkọsílẹ̀ náà.
10 Ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó ní ìjọba ìbílẹ̀ kan lè yàtọ̀ sí ti ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn. Síbẹ̀, kí ọkọ ìyàwó tó lọ forúkọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Òfin Àṣà Ìbílẹ̀ sílẹ̀, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun san owó orí ìyàwó àti pé wọ́n ti fa ìyàwó lé òun lọ́wọ́. Béèyàn bá lọ forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ láì tíì ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀, ìgbéyàwó náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ o. Ó ṣe tán ìgbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀ kì í wáyé láì dána.
11 Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan kì í forúkọ ìgbéyàwó tá a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀. Bó bá jẹ́ irú ìjọba ìbílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló wà nítòsí yín, ẹ lè lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ tó bá máa ń ṣe é tàbí kẹ́ ẹ kúkú lọ ṣe Ìgbéyàwó ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó, láìṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu mìíràn mọ́.
12 Ó dá wa lójú pé títẹ̀lé ìtọ́ni wọ̀nyí tìṣọ́ratìṣọ́ra á túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe fara wé àwọn èèyàn ayé.—Jòh. 17:14, 16.