Gbogbo Wa La Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Fídíò Náà, Noah—He Walked With God
Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:1 sí 9:19 tàbí kí o ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wo fídíò Noah, kí o sì ronú nípa bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: (1) Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ Nóà, báwo ló sì ṣe dà bẹ́ẹ̀? (2) Kí ló mú kí Nóà jẹ́ èèyàn pàtàkì bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, èé sì ti ṣe? (3) Ibo ló ṣeé ṣe kí wọ́n ti kan áàkì náà, báwo ni àkókò tí wọ́n fi kàn án ṣe gùn tó, báwo sì ni áàkì náà ṣe tóbi tó? (4) Yàtọ̀ sí kíkan áàkì, nǹkan mìíràn wo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ tún ní láti ṣe? (5) Báwo lo ṣe rò pé ipò nǹkan á ṣe rí nínú áàkì náà gbàrà tí ilẹ̀kùn tì? (6) Báwo ni kò bá ti rí lára rẹ ná ká ló o bá wọn la Ìkún Omi náà já? (7) Kí lohun tá a máa ń rí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó máa ń rán wa létí Ìkún Omi náà, kí ló sì túmọ̀ sí? (8) Kí ni ìtàn tí Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ nípa Nóà kọ́ ọ nípa ìwọ fúnra rẹ, nípa ìdílé rẹ, àti nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti fún wa láti ṣe? (9) Àwọn ìbéèrè wo ló máa wù ọ́ láti bi Nóà àti ìdílé rẹ̀ nígbà tó o bá pàdé wọn ní Párádísè? (10) Báwo lo ṣe wéwèé láti lo fídíò Noah ní báyìí?