Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 11
Orin 6
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n ka Jẹ́nẹ́sísì 6:1 sí 9:19 tàbí kí wọ́n ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀, kí wọ́n sì wo fídíò Noah—He Walked With God láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ February 18.
20 min: “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún.”a (Ìpínrọ̀ 1 sí 13) Kí alábòójútó olùṣalága bójú tó o. Fi ìtara jíròrò ohun tí a fẹ́ láti ṣàṣeparí lóṣù March àti ní àwọn oṣù tó máa tẹ̀ lé e. Kí olúkúlùkù lo kàlẹ́ńdà tó wà nínú àkìbọnú yìí láti ṣe ètò tó gbéṣẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bó bá ti ṣeé ṣe tó lóṣù March. Fún gbogbo àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú oṣù náà. Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 7 àti 8, sọ pé kí àwọn tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà nígbà Ìṣe Ìrántí tó kọjá sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n gbádùn nígbà náà. Ṣèfilọ̀ pé wọ́n á rí fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ gbà lẹ́yìn ìpàdé yìí.
13 min: Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun.” Ṣèfilọ̀ déètì tí ẹ óò ṣe àpéjọ àkànṣe tó ń bọ̀, kí o sì rọ gbogbo ìjọ láti wà níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Fún àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n ké sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn pé kí wọ́n wá.
Orin 49 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 18
Orin 95
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Gbogbo Wa La Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Fídíò Náà, Noah—He Walked With God.” Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò fídíò Noah ní tààràtà pẹ̀lú àwùjọ, kí o lo kìkì àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpótí tó wà lójú ewé yìí. Ní oṣù April, a ó ṣàyẹ̀wò fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Ní àfidípò, jíròrò “Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń wo Àwọn Oníwà Ipá Lo Fi Ń wò Wọ́n?” Àsọyé tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2000, ojú ìwé 26 sí 29.
20 min: “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún.”b (Ìpínrọ̀ 14 sí 23) Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìwéwèé àkànṣe tí ìjọ ṣe fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i lóṣù March. Sọ gbogbo ètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí ẹ ṣe fún oṣù náà. Darí àfiyèsí sí ríran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò àti ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọdé àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lè tóótun gẹ́gẹ́ bí àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ṣèfilọ̀ orúkọ àwọn tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, kí o sì fún ọ̀pọ̀ sí i níṣìírí láti ronú tàdúràtàdúrà láti dara pọ̀ mọ́ wọn.
Orin 215 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 25
Orin 174
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàṣefihàn méjì tó ṣe ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ March 1, kí èkejì sì lo Jí! March 8. Jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan fi ọ̀kan nínú wọn lọni. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù February sílẹ̀.
30 min: “Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Ohun Tó O Kọ́ ní Àpéjọ Àgbègbè ‘Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ Sílò?” Kí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé àgbègbè pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú kan, lo ìṣẹ́jú mẹ́jọ sí mẹ́wàá láti fi jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ní ṣókí, ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, kí o sì ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí nípa (1) bí wọ́n ṣe sapá láti fi ìtọ́ni náà sílò, (2) bí wọ́n ti ṣe jàǹfààní látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àti (3) ohun tí wọ́n tún rò pé àwọn lè ṣe láti túbọ̀ jàǹfààní sí i. Béèrè àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ láti lè mú kí ìjíròrò náà tani jí. Ran gbogbo ìjọ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti fi àwọn nǹkan tá a ti kọ́ sílò.
Orin 151 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 4
Orin 207
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
12 min: “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn.” Sọ pé kí àwọn akéde sọ bí apá yìí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní ìmúrasílẹ̀ fún síso àwọn àpilẹ̀kọ ìwé ìròyìn mọ́ ìjíròrò wa nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ń wáyé láwọn àkókò tó le koko wọ̀nyí. Àwọn ìrírí wo ni àwọn kan ti ní bí wọ́n ti ń lọ láti tu àwọn èèyàn nínú, tí wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa fífi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tí ń dà wọ́n láàmú? Nínú àṣefihàn kúkúrú méjì, fi hàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 15 àti Jí! March 8 lọni.
12 min: Lo Ìwé Ìmọ̀ Láti Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́. Lóṣù March, a fẹ́ láti sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ní ṣókí, sọ ìrírí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2000, ojú ewé 3, ìpínrọ̀ 8. Bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnì kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, jẹ́ kí ó ṣàṣefihàn bó ṣe bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Rán olúkúlùkù létí nípa àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Àbá fún Fífi Ìwé Ìmọ̀ Lọni,” tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002. Nípa lílo ìwé náà, ṣàṣefihàn ọ̀kan nínú àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 6 nínú àkìbọnú ọ̀hún lábẹ́ àkọlé náà, “Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni Ní Tààràtà.”
16 min: “Èé Ṣe Tí A Óò Fi Máa Wàásù Nìṣó?”c Kí a parí rẹ̀ pẹ̀lú fífi ọ̀rọ̀ wá akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ti ń wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu wò. Sọ pé kí wọ́n sọ èrò wọn nípa ìdí tí wọ́n fi tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ yìí àti bí ó ti ṣe wọ́n láǹfààní.
Orin 223 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.