Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ May 4 sí August 24, 1998. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Bíbélì, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì lẹ́ẹ̀kejì lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀ wọ́n wò ní ọdún 56 Sànmánì Tiwa. [5, w90-YR 9/15 ojú ìwé 26]
2. Fífọ́n eérú òkú tí a dáná sun ká kò bá Ìwé Mímọ́ mu. [2, w96-YR 9/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]
3. Ìtara àníjù láti mú kí ire Ìjọba náà máa tẹ̀ síwájú kò dá ṣíṣàìní ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ìfọ̀rànrora-ẹni-wò, àti jẹ̀lẹ́ńkẹ́ nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láre. (1 Kọ́r. 13:2, 3) [3, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 10/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5.]
4. Àjíǹde sí ìyè ti ọ̀run ni a pè ní “àjíǹde èkíní,” èyí jẹ́ èkíní ní ti àkókò àti ní ti ipò. (Ìṣí. 20:6) [6, w96-YR 10/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 5]
5. Ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Gálátíà 5:26 sọ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí gbogbo eré ìdárayá àti eré ìgbafẹ́ tí a ti ń díje. [9, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g95-YR 12/8 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 9.]
6. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì ṣàǹfààní ní ríràn wá lọ́wọ́ láti fi ọ̀wọ̀ hàn, kí a wà létòletò, kí a sì ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. [4, w90-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5, 6]
7. Lẹ́tà sí àwọn ará Fílípì ni Pọ́ọ̀lù kọ ní nǹkan bí oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí ó dá ìjọ tí ó wà ní Fílípì sílẹ̀, ìṣòro wíwúwo kan tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn ni ó sì fà á. [12, w90-YR 11/15 ojú ìwé 25]
8. Jésù ni a “polongo . . . ní olódodo nínú ẹ̀mí,” gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ nínú 1 Tímótì 3:16, nípa fífi ìyè tẹ̀mí san èrè fún un nígbà tí ó jíǹde; èyí wá yọrí sí pípolongo tí Ọlọ́run polongo pé Jésù jẹ́ olódodo pátápátá àti ẹni yíyẹ fún àwọn iṣẹ́ àyànfúnni gígalọ́lá púpọ̀ sí i. [16, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 1/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 12.]
9. Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Tẹsalóníkà, bí Pọ́ọ̀lù ṣe mẹ́nu kan wíwàníhìn-ín Jésù Kristi ní ìgbà mẹ́rin ní kedere jẹ́ nítorí ọkàn-ìfẹ́ tí ìjọ náà ní sí ẹ̀kọ́ yìí. [14, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
10. A lè ṣiṣẹ́ jèrè ìwàláàyè nípa sísin Jèhófà Ọlọ́run. [7, kl-YR ojú ìwé 182 ìpínrọ̀ 4]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:
11. Lọ́nà wo ni àwọn kan ní Kọ́ríńtì fi ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà “láìyẹ” nígbà tí wọ́n bá pàdé láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi? (1 Kọ́r. 11:27) [2, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 2/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 17.]
12. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe bù kún wa jìgbìnnì fún ohunkóhun tí a bá fi rúbọ nítorí ìjọsìn rẹ̀? [1, kl-YR ojú ìwé 169 ìpínrọ̀ 20]
13. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí Kristẹni kan múra tán láti tọrọ àforíjì àní bí ó bá tilẹ̀ rò pé òun kò ṣe ohun kan tí ó burú? [1, w96-YR 9/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4, 7]
14. Apá pàtàkì wo nínú “àṣírí ọlọ́wọ̀” ni a mú ṣe kedere nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Éfésù? (Éfé. 3:4-6) [11, w90-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4]
15. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ àti àpọ́sítélì, báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ lónìí? [7, w90-YR 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3]
16. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé Òfin ni a fi “kún un láti mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere”? (Gál. 3:19) [8, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo uw-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 3 àti 4.]
17. Nínú Fílípì 1:3-7, kí ni ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbóríyìn fún àwọn ará, báwo ni a sì ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ wọn? [12, w90-YR 11/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
18. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí gbogbo Kristẹni òjíṣẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Kólósè 4:6? [13, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
19. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé òun ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin ‘máa wọṣọ pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà’? (1 Tím. 2:9) [16, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g90-YR 12/22 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2.]
20. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn Kristẹni kọbi ara sí ìṣílétí Pọ́ọ̀lù nínú 1 Tímótì 6:6 ní ti “fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi”? [17, w91-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 8]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
21. A kọ ìwé Kọ́ríńtì Kejì ní _________________________ ẹ̀rí sì fi hàn pé _________________________ ni ó fi jíṣẹ́. [5, w90-YR 9/15 ojú ìwé 26]
22. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríǹtì 10:4 pé “àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara,” ó ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ yíjú sí _________________________ irú bí _________________________ tàbí _________________________ láti dáàbò bo ìjọ lòdì sí àwọn olùkọ́ èké. [7, w90-YR 9/15 ojú ìwé 27 (àpótí)]
23. Nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Gálátíà, ó fi hàn pé ìdáláre ń wá nípasẹ̀ _________________________ nínú Jésù Kristi, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ _________________________ nítorí náà ó sọ pé _________________________ kò pọndandan fún àwọn Kristẹni. [8, w90-YR 11/15 ojú ìwé 23]
24. Ó hàn gbangba pé “ìtúsílẹ̀” tí a tọ́ka sí nínú Fílípì 1:23 jẹ́ ìrètí Pọ́ọ̀lù láti wà pẹ̀lú Kristi lẹ́yìn _________________________. [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 3/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4.]
25. Lẹ́tà kejì sí àwọn ará Tẹsalóníkà ni _________________________ kọ nígbà tí ó wà ní Kọ́ríńtì ní ọdún_________________________. [15, w91-YR 1/15 ojú ìwé 23]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
26. Bí o bá ń ṣiyè mejì gidigidi nípa ẹnì kan nígbà ìfẹ́sọ́nà, ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni (kí o jẹ́ kí agbára òòfà ìfẹ́ borí iyèméjì rẹ̀; kí o fòpin sí ipò ìbátan náà; kí o pajú rẹ dé sí àwọn àléébù burúkú náà pẹ̀lú ìrètí pé nǹkan yóò dára sí i lẹ́yìn ìgbéyàwó). [16, fy-YR ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 19]
27. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Gálátíà túmọ̀ Aísáyà 54:1-6, ó fi obìnrin Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí (Jerúsálẹ́mù ti ilẹ̀ ayé; Jerúsálẹ́mù ti òkè; Jerúsálẹ́mù Tuntun). (Gál. 4:21-26) [9, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
28. Nínú Éfésù 1:10, “iṣẹ́ àbójútó” ń tọ́ka sí (Ìjọba Mèsáyà; Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso; ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe àbójútó àwọn àlámọ̀rí agboolé rẹ̀). [10, w90-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3]
29. (Àwọn ẹlẹ́sìn Júù; ẹgbẹ́ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù; Bábílónì Ńlá) ni a fi hàn pé ó jẹ́ “ọkùnrin oníwà àìlófin” tí a mẹ́nu kàn nínú 2 Tẹsalóníkà 2:3. [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 1/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 11.]
30. Nínú 1 Kọ́ríńtì 12:31, “ọ̀nà títayọ ré kọjá” ń tọ́ka sí ọ̀nà (òtítọ́; ìfẹ́; ìgbésí ayé tí ó kún fún àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí). [2, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 7/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3.]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
1 Kọ́r. 10:11, 12; 2 Kọ́r. 4:7; 2 Kọ́r. 8:14; Fílí. 4:6, 7; 2 Tẹs. 1:8, 9, 12
31. Nígbà tí ẹnì kan bá fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, òun yóò nírìírí agbára tí Ọlọ́run ń fúnni. [5, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 3/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5.]
32. Ó yẹ kí a kọbi ara sí àpẹẹrẹ oníkìlọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lábẹ́ ìdarí Mósè, kí a sì yẹra fún gbígbáralé ara ẹni. [4, w90-YR 9/15 ojú ìwé 25]
33. Àwọn ẹ̀bùn ọlọ́làwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ lé pèsè fún àìní àwọn tí ó wà ní ibi tí nǹkan kò ti fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure, nígbà tí ìtara àti ìforítì àwọn tí a ń ṣẹ́níṣẹ̀ẹ́ lè jẹ́ orísun ìdùnnú àti ìṣírí fún àwọn tí ó fúnni lọ́rẹ. [6, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 12/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 20.]
34. A kò gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró ní wíwàásù ìhìn rere náà, nítorí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, gbogbo àwọn tí ń bẹ láàyè lónìí tí ó wà láàyè títí di òpin ètò burúkú yìí, tí a sì dá lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ yóò fara gba ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun. [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 5/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 4.]
35. Jèhófà ń fúnni ní ìtòròparọ́rọ́ àti ipò ìparọ́rọ́ láàárín àwọn àyíká ipò tí ó kún fún àdánwò jù lọ. [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 11/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 19 àti 20.]