Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní August àti September: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 ní èdè èyíkéyìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa. October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
◼ A ti rí ìròyìn gbà láti ọ̀dọ̀ púpọ̀ lára àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn wa nípa àwọn ìrírí tí wọ́n máa ń ní nígbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwòsàn. Àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì kan ṣàròyé pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mú káàdì Medical Directive wọn dání nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ gbàwòsàn. Wọ́n tún ròyìn pé nígbà tí a bá ń kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Ìforúkọsílẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn tàbí fọ́ọ̀mù Ìgbaniwọlé àti àwọn ìwé mìíràn, “Kristẹni” ni ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa máa ń kọ láti fi sọ irú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Èyí ti mú kí ó ṣòro láti dá àwọn kan lára wa mọ̀ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí kò fara mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀ fún ìtọ́jú. Kàkà bẹ́ẹ̀, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà” ni ó yẹ kí a kọ. Lọ́nà yìí, wọn yóò mọ irú ẹni tí a jẹ́ lójú ẹsẹ̀ kí wọ́n lè fún wa ní ìtọ́jú tí ó yẹ. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí a kùnà láti sọ fún dókítà láti ìbẹ̀rẹ̀ pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ń pe àfiyèsí yín sí ohun tí a sọ nínú lẹ́tà wa ti July 19, 1995, sí gbogbo ìjọ, pé a ń fa ìṣòro fún ara wa àti fún àwọn ilé ìwòsàn nígbà tí a kò bá tẹ̀ lé ìlànà tí ó wà lókè yìí.
◼ Àwọn fọ́ọ̀mù tí ó pọ̀ tó ni a ń fi ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan fún lílò ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1999. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi òye lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí. Kí a lò wọ́n fún kìkì ète tí a ṣe wọ́n fún.
◼ Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta. Kí akọ̀wé ìjọ rí ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ August, kí wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú ìjọ ní ìparí oṣù náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ka iye àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní ti gidi, kí wọ́n sì kọ àròpọ̀ rẹ̀ sórí fọ́ọ̀mù Literaure Inventory. Àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ ni a lè mọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà tí ó jẹ́ ojúlówó ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ́kọ́ kọ nǹkan sí. Kí akọ̀wé bójú tó ìṣírò náà, kí alábòójútó olùṣalága sì ṣàyẹ̀wò fọ́ọ̀mù tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága yóò fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti August 21, 1998, sí August 30, 1998, Society yóò máa ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Igieduma. Nítorí ìṣírò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́ tàbí tí wọ́n fẹ́ wá kó ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn.
◼ Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ fún gbogbo ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní àfiyèsí lọ́gán. Ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn kò gbọ́dọ̀ tọ́jú ìwé ìwọṣẹ́ sọ́wọ́ láti rí i bóyá ẹni tí ó fẹ́ wọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà náà yóò lè dójú wákàtí tí a ń béèrè fún. Déètì ìyannisípò ni Society fúnra rẹ̀ lè yí padà lórí ìwé ìwọṣẹ́ tí a bá rí gbà lẹ́yìn déètì tí ẹni náà sọ pé òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀. A kì yóò yanni sípò ní déètì tí ó wà lórí fọ́ọ̀mù tí a kò rí gbà ṣáájú déètì yẹn àyàfi bí àwọn àyíká ipò pàtàkì kan bá mú kí èyí pọndandan. Bí irú àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀ bá wà, kí lẹ́tà bá ìwé ìwọṣẹ́ náà wá.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986, ìpínrọ̀ 24 sí 26.
◼ A ń fi ẹ̀dà méjì fọ́ọ̀mù S-10 Congregation Analysis Report ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ fi ìfarabalẹ̀ gidigidi kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yìí kí ẹ sì fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6, 1998, pẹ̀lú ìròyìn oṣù August. Inú fáìlì yín ni kí ẹ fi ẹ̀dà kejì sí.