Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 26
Orin 101 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 9, àti àpótí tó wà lójú ewé 79 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 142-150 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 144:1–145:4 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Dá Ayé Láti Jẹ́ Párádísè—td 25A (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Yẹra fún “Ìṣègbè”?—Ják. 2:1-4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Jíròrò “Ọ̀kan Lára Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?” Lo àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday, October 1. Fún àwọn ará ní ìṣírí láti kópa nínú rẹ̀.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò. Fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2005, ojú ìwé 4.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù October. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó máa fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó. Àpilẹ̀kọ kan ni kẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìbéèrè tó lè múni nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ èyí tí wọ́n lè lò, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Níwọ̀n bí Jí! October–December ti jẹ́ àkànṣe, ní kí àwọn ará sọ irú àwọn tó lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìròyìn náà àti bá a ṣe lè fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
Orin 41 àti Àdúrà