Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 19
Orin 78 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 9, ìpínrọ̀ 19 sí 24, àti àpótí tó wà lójú ìwé 73 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 135-141 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 137:1–138:8 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ló Mú Kí Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù Tó Wà Nínú Róòmù 14:7-9 Tù Wá Nínú? (5 min.)
No. 3: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì Tó Dẹ́ṣẹ̀—td 10D (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, tẹnu mọ́ ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ní àwọn ìrírí tó wuni lórí. Sọ kókó kan tàbí méjì tí ìjọ ní láti ṣiṣẹ́ lé lórí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀, kó o sì jíròrò àwọn àbá mélòó kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe dáradára sí i.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé? Ìjíròrò tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 198, ìbéèrè 12 àti 13.
10 min: “Jèhófà Ń Dá Wa Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Yìí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 117 àti Àdúrà