ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Íjíbítì ò lè ṣèrànwọ́ kankan (1-7)

      • Àwọn èèyàn ò fetí sí àsọtẹ́lẹ̀ (8-14)

      • Ìgbẹ́kẹ̀lé máa fi hàn pé wọ́n lágbára (15-17)

      • Jèhófà ṣojúure sí àwọn èèyàn rẹ̀ (18-26)

        • Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá (20)

        • “Èyí ni ọ̀nà” (21)

      • Jèhófà máa dá Ásíríà lẹ́jọ́ (27-33)

Àìsáyà 30:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ta ohun tí wọ́n fi rúbọ sílẹ̀,” ó ṣe kedere pé ṣíṣe àdéhùn ló ń sọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:2; 63:10; 65:2
  • +Ais 29:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 302-303

Àìsáyà 30:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láìgbọ́ tẹnu mi.”

  • *

    Ní Héb., “sínú ibi ààbò Fáráò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 31:1; Isk 29:6
  • +Nọ 27:21; 1Ọb 22:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 302-303

Àìsáyà 30:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 17:5

Àìsáyà 30:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 19:11; Isk 30:14

Àìsáyà 30:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 31:3; Jer 2:36

Àìsáyà 30:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ejò olóró tó ń yára kánkán.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 303-305

Àìsáyà 30:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 31:1; Jer 37:7, 8
  • +Sm 87:4; 89:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 303-304

Àìsáyà 30:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:1; Jer 36:2
  • +Ro 15:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 304

Àìsáyà 30:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:27; Ais 1:4; Jer 44:3
  • +Ais 59:3; Jer 9:3
  • +2Kr 33:10; 36:15, 16; Ne 9:29; Jer 7:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 304

Àìsáyà 30:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó dùn-ún gbọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 16:10; 18:7; Jer 11:21; 26:11
  • +Jer 23:16, 17; Isk 13:7; Mik 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 304-306

Àìsáyà 30:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 7:13, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 304-306

Àìsáyà 30:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 2:4, 5
  • +Jer 13:25; Mik 3:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 306-307

Àìsáyà 30:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 306-307

Àìsáyà 30:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kòtò omi.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 307

Àìsáyà 30:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 5:20; 2Kr 16:8; Ais 26:3
  • +Mt 23:37; Iṣe 7:51

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2021, ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 307

Àìsáyà 30:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 31:1, 3
  • +Di 28:49, 50; Jer 4:13; Ida 4:19; Hab 1:6, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 308

Àìsáyà 30:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:36; Di 32:30
  • +Isk 12:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 308

Àìsáyà 30:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ń fojú sọ́nà.”

  • *

    Tàbí “ń fojú sọ́nà fún un.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6; Isk 36:9, 10
  • +Sm 102:13; Ro 9:15
  • +Sm 99:4; Jer 10:24
  • +Jer 17:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 26

    3/1/2002, ojú ìwé 30

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 308-309

Àìsáyà 30:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 11:1; Ais 44:28; 62:1; Jer 31:6; Sek 1:17
  • +Ne 12:27; Ais 61:3
  • +Jer 29:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2011, ojú ìwé 28

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 309

Àìsáyà 30:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26; Sm 80:5
  • +Job 36:22; Sm 32:8; 71:17; 119:102

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2011, ojú ìwé 28

    11/1/2005, ojú ìwé 23

    2/15/2003, ojú ìwé 31

    6/15/2001, ojú ìwé 21

    9/15/1994, ojú ìwé 27

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 310

Àìsáyà 30:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:8, 9
  • +Di 5:32; Joṣ 1:7, 8; Owe 4:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2005, ojú ìwé 23

    9/1/2004, ojú ìwé 17-18

    2/15/2003, ojú ìwé 31

    5/15/1999, ojú ìwé 17-18

    5/1/1996, ojú ìwé 23

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 310

Àìsáyà 30:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ẹ sì máa pè wọ́n ní ohun ìdọ̀tí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:4; Di 7:5, 25; Ond 17:3, 4
  • +Ho 14:8; Sek 13:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 310-311

Àìsáyà 30:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó sì máa lóròóró dáadáa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 65:9; Sek 10:1
  • +Ho 2:21, 22
  • +Ais 65:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 232

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 311-312

Àìsáyà 30:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 311-312

Àìsáyà 30:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:18; 44:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 311-313

Àìsáyà 30:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “egungun àwọn èèyàn rẹ̀ tó fọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 60:20; Ifi 21:23; 22:5
  • +Ida 2:13
  • +Jer 33:6; Emọ 9:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 312-313

Àìsáyà 30:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkùukùu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:17; Na 1:6; Sef 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 312-313

Àìsáyà 30:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Èémí.”

  • *

    Ní Héb., “ajọ̀ àìníláárí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:28; Sm 32:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 313, 315

Àìsáyà 30:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ ara yín di mímọ́.”

  • *

    Tàbí “tó ń tẹ̀ lé ìró fèrè bó ṣe ń rìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:14; Sm 42:4; Jer 33:10, 11
  • +Di 32:4; Ais 26:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 313-314

Àìsáyà 30:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 29:3, 4
  • +Ẹk 15:16; Sm 98:1
  • +Na 1:2
  • +Sm 18:13
  • +Ond 5:4
  • +Joṣ 10:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 314

Àìsáyà 30:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 37:36
  • +Ais 10:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 314

Àìsáyà 30:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20; Ond 11:34
  • +Ais 10:24, 26

Àìsáyà 30:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    “Tófétì” tí wọ́n lò níbí dúró fún ibi tí wọ́n ti ń dáná sun nǹkan, èyí tó ṣàpẹẹrẹ ìparun.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:10; Jer 7:32
  • +Ais 37:37, 38; Isk 32:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 314

Àwọn míì

Àìsá. 30:1Ais 1:2; 63:10; 65:2
Àìsá. 30:1Ais 29:15
Àìsá. 30:2Ais 31:1; Isk 29:6
Àìsá. 30:2Nọ 27:21; 1Ọb 22:7
Àìsá. 30:3Jer 17:5
Àìsá. 30:4Ais 19:11; Isk 30:14
Àìsá. 30:5Ais 31:3; Jer 2:36
Àìsá. 30:7Ais 31:1; Jer 37:7, 8
Àìsá. 30:7Sm 87:4; 89:10
Àìsá. 30:8Ais 8:1; Jer 36:2
Àìsá. 30:8Ro 15:4
Àìsá. 30:9Di 31:27; Ais 1:4; Jer 44:3
Àìsá. 30:9Ais 59:3; Jer 9:3
Àìsá. 30:92Kr 33:10; 36:15, 16; Ne 9:29; Jer 7:13
Àìsá. 30:102Kr 16:10; 18:7; Jer 11:21; 26:11
Àìsá. 30:10Jer 23:16, 17; Isk 13:7; Mik 2:11
Àìsá. 30:11Emọ 7:13, 16
Àìsá. 30:12Emọ 2:4, 5
Àìsá. 30:12Jer 13:25; Mik 3:11
Àìsá. 30:151Kr 5:20; 2Kr 16:8; Ais 26:3
Àìsá. 30:15Mt 23:37; Iṣe 7:51
Àìsá. 30:16Ais 31:1, 3
Àìsá. 30:16Di 28:49, 50; Jer 4:13; Ida 4:19; Hab 1:6, 8
Àìsá. 30:17Le 26:36; Di 32:30
Àìsá. 30:17Isk 12:16
Àìsá. 30:18Ẹk 34:6; Isk 36:9, 10
Àìsá. 30:18Sm 102:13; Ro 9:15
Àìsá. 30:18Sm 99:4; Jer 10:24
Àìsá. 30:18Jer 17:7
Àìsá. 30:19Ne 11:1; Ais 44:28; 62:1; Jer 31:6; Sek 1:17
Àìsá. 30:19Ne 12:27; Ais 61:3
Àìsá. 30:19Jer 29:11, 12
Àìsá. 30:20Le 26:26; Sm 80:5
Àìsá. 30:20Job 36:22; Sm 32:8; 71:17; 119:102
Àìsá. 30:21Sm 25:8, 9
Àìsá. 30:21Di 5:32; Joṣ 1:7, 8; Owe 4:27
Àìsá. 30:22Ẹk 32:4; Di 7:5, 25; Ond 17:3, 4
Àìsá. 30:22Ho 14:8; Sek 13:2
Àìsá. 30:23Sm 65:9; Sek 10:1
Àìsá. 30:23Ho 2:21, 22
Àìsá. 30:23Ais 65:10
Àìsá. 30:25Ais 41:18; 44:3
Àìsá. 30:26Ais 60:20; Ifi 21:23; 22:5
Àìsá. 30:26Ida 2:13
Àìsá. 30:26Jer 33:6; Emọ 9:11
Àìsá. 30:27Ais 10:17; Na 1:6; Sef 3:8
Àìsá. 30:282Ọb 19:28; Sm 32:9
Àìsá. 30:29Di 16:14; Sm 42:4; Jer 33:10, 11
Àìsá. 30:29Di 32:4; Ais 26:4
Àìsá. 30:30Sm 29:3, 4
Àìsá. 30:30Ẹk 15:16; Sm 98:1
Àìsá. 30:30Na 1:2
Àìsá. 30:30Sm 18:13
Àìsá. 30:30Ond 5:4
Àìsá. 30:30Joṣ 10:11
Àìsá. 30:31Ais 37:36
Àìsá. 30:31Ais 10:12
Àìsá. 30:32Ẹk 15:20; Ond 11:34
Àìsá. 30:32Ais 10:24, 26
Àìsá. 30:332Ọb 23:10; Jer 7:32
Àìsá. 30:33Ais 37:37, 38; Isk 32:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 30:1-33

Àìsáyà

30 “Àwọn alágídí ọmọ gbé,”+ ni Jèhófà wí,

“Àwọn tó ń ṣe ohun tí mi ò ní lọ́kàn,+

Tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀,* àmọ́ tí kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,

Kí wọ́n lè dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.

 2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+

Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*

Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!

 3 Àmọ́ ibi ààbò Fáráò máa dójú tì yín,

Òjìji Íjíbítì tí ẹ sì fi ṣe ibi ìsádi máa rẹ̀ yín wálẹ̀.+

 4 Torí àwọn ìjòyè rẹ̀ wà ní Sóánì,+

Àwọn aṣojú rẹ̀ sì ti dé Hánésì.

 5 Àwọn èèyàn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan

Máa dójú ti gbogbo wọn,

Àwọn tí kò ṣèrànwọ́ kankan, tí wọn ò sì ṣeni láǹfààní kankan,

Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ nìkan ni wọ́n ń mú wá.”+

6 Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù:

Wọ́n gba ilẹ̀ wàhálà àti ìnira kọjá,

Ilẹ̀ kìnnìún, kìnnìún tó ń ké ramúramù,

Paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tó ń fò,*

Wọ́n gbé ọrọ̀ wọn sí ẹ̀yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

Àtàwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lò sórí iké àwọn ràkúnmí.

Àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò ní ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní.

 7 Torí ìrànlọ́wọ́ Íjíbítì ò wúlò rárá.+

Torí náà, mo pe ẹni yìí ní: “Ráhábù,+ tó jókòó jẹ́ẹ́.”

 8 “Ó yá, lọ, kọ ọ́ sára wàláà níṣojú wọn,

Kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé,+

Kó lè wúlò lọ́jọ́ ọ̀la,

Láti jẹ́ ẹ̀rí tó máa wà títí láé.+

 9 Torí pé ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ni wọ́n,+ àwọn ẹlẹ́tàn ọmọ,+

Àwọn ọmọ tí kò fẹ́ gbọ́ òfin* Jèhófà.+

10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’

Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+

Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+

11 Ẹ yà kúrò lọ́nà; ẹ fọ̀nà sílẹ̀.

Ẹ má fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì síwájú wa mọ́.’”+

12 Torí náà, ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sọ nìyí:

“Torí pé ẹ ò gba ọ̀rọ̀ yìí,+

Tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì àti ẹ̀tàn,

Tí ẹ sì gbára lé àwọn nǹkan yìí,+

13 Ẹ̀ṣẹ̀ yìí máa dà bí ògiri tó ti sán fún yín,

Bí ògiri gíga tó wú, tó máa tó wó,

Ó máa wó lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.

14 Ó máa fọ́ bí ìṣà ńlá tó jẹ́ ti amọ̀kòkò,

Ó máa fọ́ túútúú débi pé kò ní sí àfọ́kù kankan,

Láti fi wa iná láti ibi ìdáná

Tàbí láti fi bu omi nínú adágún.”*

15 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí:

“Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;

Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+

Àmọ́ kò wù yín.+

16 Dípò ìyẹn, ẹ sọ pé: “Rárá, a máa gun ẹṣin sá lọ!”

Ẹ sì máa sá lọ lóòótọ́.

“A máa gun àwọn ẹṣin tó ń yára kánkán!”+

Àwọn tó ń lépa yín sì máa yára kánkán.+

17 Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) máa gbọ̀n rìrì nítorí ìhàlẹ̀ ẹnì kan;+

Ìhàlẹ̀ ẹni márùn-ún máa mú kí ẹ sá,

Títí ohun tó ṣẹ́ kù nínú yín fi máa dà bí òpó lórí òkè ńlá,

Bí òpó tí wọ́n fi ṣe àmì lórí òkè kékeré.+

18 Àmọ́ Jèhófà ń fi sùúrù dúró* láti ṣojúure sí yín,+

Ó sì máa dìde láti ṣàánú yín.+

Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.+

Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.*+

19 Tí àwọn èèyàn bá ń gbé ní Síónì, ní Jerúsálẹ́mù,+ o ò ní sunkún rárá.+ Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́; ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.+ 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa fi wàhálà ṣe oúnjẹ fún yín, tó sì máa fi ìyà ṣe omi fún yín,+ Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá ò ní fi ara rẹ̀ pa mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.+ 21 Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+

22 Ẹ ó sọ fàdákà tí ẹ fi bo àwọn ère gbígbẹ́ yín àti wúrà tí ẹ fi bo àwọn ère onírin*+ yín di aláìmọ́. Ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí wọ́n fi ṣe nǹkan oṣù, ẹ ó sì sọ fún wọn pé: “A ò fẹ́ mọ́!”*+ 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+ 24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ máa jẹ oúnjẹ ẹran tí wọ́n fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí wọ́n fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́. 25 Odò àti ipadò máa wà lórí gbogbo òkè ńlá tó rí gogoro àti gbogbo òkè kéékèèké tó ga,+ ní ọjọ́ tí a pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú. 26 Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú máa dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì máa lágbára sí i ní ìlọ́po méje,+ bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà bá di àfọ́kù àwọn èèyàn rẹ̀,*+ tó sì wo ọgbẹ́ ńlá tó dá sí wọn lára nígbà tó kọ lù wọ́n sàn.+

27 Wò ó! Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,

Inú ń bí i gan-an, ó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* tó ṣú bolẹ̀.

Ìbínú kún ètè rẹ̀,

Ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tó ń jẹni run.+

28 Ẹ̀mí* rẹ̀ dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tó muni dé ọrùn,

Láti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nínú ajọ̀ ìparun;*

Ìjánu sì máa wà ní páárì àwọn èèyàn+ náà láti kó wọn ṣìnà.

29 Àmọ́ orin yín máa dà bí èyí tí wọ́n kọ ní òru

Nígbà tí ẹ̀ ń múra sílẹ̀* fún àjọyọ̀,+

Inú yín sì máa dùn bíi ti ẹni

Tó ń rìn tòun ti fèrè*

Bó ṣe ń lọ sí òkè Jèhófà, sọ́dọ̀ Àpáta Ísírẹ́lì.+

30 Jèhófà máa mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀ tó gbayì,+

Ó sì máa fi apá rẹ̀ hàn+ bó ṣe ń fi ìbínú tó le sọ̀ kalẹ̀ bọ̀,+

Pẹ̀lú ọwọ́ iná tó ń jẹni run,+

Òjò líle tó bẹ̀rẹ̀ lójijì,+ ìjì tó ń sán ààrá àti àwọn òkúta yìnyín.+

31 Nítorí ohùn Jèhófà, jìnnìjìnnì máa bo Ásíríà;+

Ó máa fi ọ̀pá lù ú.+

32 Gbogbo bó ṣe ń fi ọ̀pá rẹ̀ tó fi ń jẹni níyà,

Èyí tí Jèhófà máa mú wá sórí Ásíríà,

Máa jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti háàpù,+

Bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ sí wọn lójú ogun.+

33 Torí pé ó ti múra Tófétì*+ rẹ̀ sílẹ̀;

Ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba pẹ̀lú.+

Ó ti to igi jọ pelemọ, ó sì fẹ̀,

Pẹ̀lú iná tó ń jó lala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi.

Èémí Jèhófà, tó dà bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́,

Máa dáná sí i.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́