3 Àmọ́ èèyàn lásán ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
Ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn ní, wọn kì í ṣe ẹ̀mí.+
Tí Jèhófà bá na ọwọ́ rẹ̀,
Ẹnikẹ́ni tó bá ranni lọ́wọ́ máa kọsẹ̀,
Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá sì ràn lọ́wọ́ máa ṣubú;
Gbogbo wọn máa ṣègbé lẹ́ẹ̀kan náà.