4 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Júdà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé òfin Jèhófà
Àti nítorí pé wọn kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́;+
Irọ́ tí àwọn baba ńlá wọn tọ̀ lẹ́yìn ti mú kí wọ́n ṣìnà.+
5 Torí náà, màá rán iná sí Júdà,
Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Jerúsálẹ́mù run.’+