ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/07 ojú ìwé 4-5
  • Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 9/07 ojú ìwé 4-5

Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn Nípa Ṣíṣe Ohun Tó Buyì Kún Jèhófà

1. Báwo ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àgbègbè ọdún yìí ṣe tan mọ́ bá a ṣe lè máa ṣe ohun tó buyì kún Jèhófà?

1 Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Láyé Àtọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fi iyì bora bí aṣọ. (Sm. 104:1) Ọ̀rọ̀ tó máa ń buyì kún Jèhófà tó sì máa ń fọ̀wọ̀ hàn fáwọn ètò tí Jèhófà ti gbé kalẹ̀ ni Jésù máa ń sọ ní gbogbo ìgbà. (Jòh. 17:4) Ní Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” tó ń bọ̀ lọ́nà yìí, olúkúlùkù wa máa ní àǹfààní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè máa fògo fún Jèhófà.

2. Ọ̀nà wo ni ètò tá a bá ṣe ká bàa lè wà ní gbogbo ìpàdé yẹn á gbà buyì kún Jèhófà?

2 Ìjọsìn Tó Ń Buyì Kún Ọlọ́run: Ọ̀nà kan tá a lè gbà buyì kún Jèhófà ni pé ká ṣètò tó yẹ ká bàa lè wà níbi àpèjẹ tí Jèhófà pè wá sí, ìyẹn àpéjọ àgbègbè tọdún yìí. Ṣó o ti tọrọ àyè níbi iṣẹ́? Ṣó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò tó yẹ kó o bàa lè wà níbẹ̀ jálẹ̀ gbogbo àpéjọ àgbègbè náà títí kan ọjọ́ Friday? Ṣó o ti ṣètò tó máa jẹ́ kó o lè débẹ̀ lásìkò tí wàá fi lè tètè wá ibi tó o máa jókòó sí kó tó di pé a fi orin àti àdúrà bẹ̀rẹ̀? Ṣó o ti ṣètò oúnjẹ ọ̀sán, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹ láti jẹun níbi táwọn ará wà láyìíká Gbọ̀ngàn Àpéjọ? Nígbà tí ohùn orin bá bẹ̀rẹ̀ sí í dún gẹ́gẹ́ bí àmì pé ìpàdé ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, ì báà jẹ́ láàárọ̀ tàbí lọ́sàn-án, tí alága sì rọ̀ wá pé ká lọ jókòó sí àyè wa, ńṣe ni ká tètè parí ìjíròrò wa, ká sì lọ jókòó sí àyè wa kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀.

3. Bá a bá ń fọkàn bá àpéjọ náà lọ, báwo nìyẹn ṣe máa buyì kún ìjọsìn wa?

3 Bá a bá ṣe ń fọkàn bá ìpàdé náà lọ tún máa ń buyì kún Baba wa ọ̀run. Oníròyìn kan tó lọ sí àpéjọ àgbègbè kan kọ̀wé pé kò sẹ́ni tó máa wá síbẹ̀ tí orí rẹ̀ ò ní wú. Ó ní: “Àwọn tó wà ní àpéjọ náà ya ọmọlúwàbí, ńṣe ni gbogbo ibẹ̀ dákẹ́ minimini, bí wọ́n ṣe ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ látorí pèpéle, èyí tó fi hàn pé ọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún.” Ó tún ṣàlàyé nípa “báwọn ọmọdé tó pésẹ̀ ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ . . . , pé irú àwọn ọmọ onígbọràn bẹ́ẹ̀ ò wọ́pọ̀. Ó sì kíyè sí bí gbogbo wọn ṣe pọkàn pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣí Ìwé Mímọ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ ṣe ń pè é.” Àmọ́ ṣá o, ó bani nínú jẹ́ pé láwọn àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún tó kọjá, a ráwọn ọ̀dọ́ mélòó kan tí wọ́n ń rìn gbéregbère káàkiri ojúgbó tí wọ́n sì ń hùwà pálapàla tí kò yẹ Kristẹni. A rí àwọn míì tí wọn kì í ṣe tọkọtaya, tí wọ́n ń fára wọn lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ń fọwọ́ kọ́ ìbàdí tàbí ọrùn ara wọn. Ìwà tó bògìrì gbáà lèyí jẹ́ fún Kristẹni. Kò yẹ kó jẹ́ pé ìgbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ la ó máa sọ̀rọ̀ tàbí la ó máa fi fóònù tẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wa, kì í sì í ṣe àsìkò láti jẹun tàbí láti máa rìn káàkiri. Káwọn ọ̀dọ́ jókòó ti àwọn òbí wọn, káwọn òbí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ẹ̀kọ́ kọ́ ní ìpàdé náà. (Diu. 31:12; Òwe 29:15) Bá a bá ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí, a ó máa fọ̀wọ̀ hàn fáwọn ẹlòmíì, a ó sì tún máa fi hàn pé a mọrírì ìtọ́ni tá a wá gbọ́ ní àpéjọ yẹn.

4. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó máa buyì kún Ọlọ́run nígbà tá a bá wà ní àpéjọ àgbègbè?

4 Ìmúra Tó Buyì Kún Ọlọ́run: Ọ̀pọ̀ ló sọ pé àwọn mọrírì ìránnilétí tá a gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè ọdún tó kọjá tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Máa Hùwà Táa Buyì Kúnni Nígbà Gbogbo,” èyí tó tẹnu mọ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé aṣọ àti ìmúra wọn ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ó sì tún yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀ lọ́dún yìí náà. Aṣọ tá a bá wọ̀ àti bá a bá ṣe múra ń fi ojú tá a fi ń wo Jèhófà hàn, ó sì ń fi bá a ṣe mọrírì jíjẹ́ tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ hàn. Ìmúra wa gbọ́dọ̀ máa fi wá hàn ní gbogbo ìgbà pé a jẹ́ ẹni tó “ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.”—1 Tím. 2:9, 10.

5. Báwo la ṣe lè múra lọ́nà tó máa buyì kún Ọlọ́run nígbà tá a bá fẹ́ najú lọ láàárín ìlú tá a ti ń ṣe àpéjọ?

5 Ṣé ìgbà tá a bá wà nípàdé nìkan la gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó ń buyì kún Ọlọ́run? Rántí pé ọ̀pọ̀ ló máa fi báàjì wa dá wa mọ̀ nígbà tá a bá wà ní ìlú tá a ti ń ṣe àpéjọ. Ó yẹ kí ìmúra wa mú ká yàtọ̀ sáwọn aráàlú. Nítorí náà, nígbà tá a bá fẹ́ najú lọ pàápàá, bóyá ńṣe la sì fẹ́ lọ ra oúnjẹ lẹ́yìn tí ìpàdé parí, a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó yẹ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wá ṣe ìpàdé àgbègbè nílùú náà, a kò sì gbọ́dọ̀ wọ àwọn aṣọ bíi Jíǹsì, ṣòkòtò péńpé tàbí àwọ̀tẹ́lẹ̀ alápá péńpé tàbí èyí tí kò lápá. Ẹ ò rí i pé ìwàásù lèyí máa jẹ́ fáwọn aráàlú náà! Inú Jèhófà á dùn bá a bá ń múra lọ́nà tó máa fi wá hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀.

6. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú fífi ara wa hàn bíi Kristẹni tó wuyì?

6 Èrè Pọ̀ Níbẹ̀: Bá a bá ń ṣe ohun tó máa fi wá hàn bíi Kristẹni tó wuyì láwọn àpéjọ wa, ó máa jẹ́ ká lè ní àǹfààní láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà, àwọn tó rí wa á sì lè máa rí nǹkan rere sọ nípa wa. Lẹ́yìn tí àpéjọ àgbègbè kan parí, òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ pé: “A ò tíì rí irú àwọn èèyàn tó mọ̀wàá hù báyìí rí. Ẹ̀yin lẹ̀ ń ṣe bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe.” Ṣíṣe ohun tó wuyì fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún ara wa, a sì ń fògo fún Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Ó ń fi hàn pé a bẹ̀rù Ọlọ́run àti pé a mọrírì àǹfààní tá a ní láti gbẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Baba wa. (Héb. 12:28) Ǹjẹ́ ká sapá láti máa fi ara wa hàn bíi Kristẹni tó wuyì bá a ṣe ń retí Àpéjọ Àgbègbè ti ọdún yìí, èyí tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

◼ Àkókò Ìpàdé: Àpéjọ á máa bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án [9:00] géérégé láràárọ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Tó bá ku ìṣẹ́jú díẹ̀ kí àpéjọ bẹ̀rẹ̀, alága á jókòó sórí pèpéle, ohùn orin Ìjọba Ọlọ́run á sì máa dún láti fi hàn pé àpéjọ máa tó bẹ̀rẹ̀. Oníkálukú ti gbọ́dọ̀ wà lórí ìjókòó lákòókò yẹn kí àpéjọ náà bàa lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ á parí ní agogo márùn-ún kú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [4:35] nírọ̀lẹ́ Friday àti Sátidé, á sì parí ní agogo mẹ́rin ku ogún ìṣẹ́jú [3:40] nírọ̀lẹ́ Sunday.

◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà nìkan lo lè bá gbàyè sílẹ̀.

◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Jọ̀wọ́ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tí wàá fi fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ sílẹ̀ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà oúnjẹ gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A ò sì ní gba ọtí líle láyè.

◼ Ọrẹ: Owó kékeré kọ́ là ń ná láti ṣètò àpéjọ àgbègbè. A lè fi ìmọrírì wa hàn nípa fífínnúfíndọ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé, a sì lè fi irú owó tá a bá fẹ́ fi ṣètìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí ẹni tó bá fẹ́ ṣètìlẹ́yìn nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó ní àpéjọ àgbègbè kọ “Watch Tower” sórí ìwé sọ̀wédowó náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó náà fún, kí ẹni náà kọ ọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní o, kó má ṣe kọ ọ́ pa pọ̀.

◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ fún olùtọ́jú èrò tó bá wà nítòsí, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti mọ bí aláìlera náà ṣe máa dé Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì káwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ wa tí wọ́n ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó, kí wọ́n bàa lè ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.

◼ Ààbò Lójú Pópó: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wakọ̀ jẹ́jẹ́ o, kẹ́ ẹ sì rí i pé ẹ tẹ̀ lé òfin ìrìnnà nígbà tẹ́ ẹ bá ń lọ sí àpéjọ àti nígbà tẹ́ ẹ bá ń padà sílé. Ohun mímọ́ làwa Kristẹni ka ẹ̀mí sí, torí náà, ẹ rí i pe ẹ tẹ̀ lé gbogbo òfin tí kò ní mú ká fẹ̀mí ara wa wewu. (Sm. 36:9) Ẹ rí i pé àwọn tó ṣètò awakọ̀ tó máa gbé e yín lọ sí àpéjọ rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe sáré àsápajúdé, kí wọ́n wakọ̀ jẹ́jẹ́, kí wọ́n má sì fẹ̀mí àwọn èèyàn wewu.

◼ Gbígba Ohùn Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ti ẹ̀rọ tá à ń lò ní àpéjọ, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ lo ẹ̀rọ tó ń gbohùn sílẹ̀ rí i pé òun ò fi dí ẹlòmíì lọ́wọ́.

◼ Fọ́tò Yíyà: Kí ẹni tó bá máa ya fọ́tò nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́ rí i pé òun kò lo iná tó ń bù yẹ̀rì. Kò ní bọ́gbọ́n mú fẹ́ni kẹ́ni láti máa jáde lọ ya fọ́tò nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Àti pé, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ará làwọn tó ń ya fọ́tò tà, a ò gbà wọ́n láyè láti gbégbá fọ́tò yíyà wá sínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a wàásù fẹ́nì kan nígbà àpéjọ àgbègbè tẹ́ni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ jẹ́ ká kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43), ìyẹn fọ́ọ̀mù tá a máa fi ń kọ ohun tá ò fẹ́ gbà gbé nípa ẹni tó fìfẹ́ hàn sí. Kí àwọn akéde mú fọ́ọ̀mù yẹn kan tàbí méjì dání. A lè rí fọ́ọ̀mù yìí gba ní Ilé Ìgbàwé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín nígbà tẹ́ ẹ bá padà délé.

◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Ó máa fi hàn pé àwọn arábìnrin nífẹ̀ẹ́ àwọn ará bí wọn ò bá jẹ́ kí gèlè wọn ṣe gẹngẹ débi tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú lọ́sàn-án Sunday nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ oníkẹ́jẹ́bú tá à ń lò báyìí títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

◼ Ilé Gbígbé: Fi èso tẹ̀mí sílò bó o bá ti dé síbi tá a ó ti ṣe àpéjọ, tí wọ́n sì ń fi ibi tó o máa dé sí hàn ẹ́. Má ṣe dé sínú ilé tí wọ́n kọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí kì í bá ṣe ibẹ̀ ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní kó o dé sí. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nípa dídé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. Lọ́dún tó kọjá a rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin mélòó kan tí wọ́n jọ wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ títí tí ilẹ̀ fi ṣú wọn síbẹ̀, tí wọ́n sì sùn síbẹ̀. Èyí kò bójú mu rárá. Kò sì tún bójú mu pé káwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin máa jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú àwọn sí ibùwọ̀ tó wà fún àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin nìkan. Ibi tí wọ́n bá sọ pé o ti lè dáná nìkan ni kó o ti máa dáná o. A gbọ́ pé àwọn kan máa ń dáná nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí ò fi hàn pé wọ́n mọrírì ìjọsìn Ọlọ́run.—Lúùkù 10:38-42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́