Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa àti Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lò Wọ́n
1 Ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tí ètò Jèhófà ti ń pèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń mú lọ fáwọn èèyàn àtèyí táwa fúnra wa ń kà láìdá iye kan pàtó lé e. Ìbùkún ńlá gbáà ni ìṣètò yìí ti mú wá, ó sì ti mú kí ọ̀nà tá a gbà ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ rọrùn gan-an. Ṣùgbọ́n o, a ò ní gbàgbé pé bí a ò tiẹ̀ “dá iye pàtó kan lé” àwọn ìtẹ̀jáde náà, wọn kì í ṣe “ọ̀fẹ́.” Owó kékeré kọ́ la fi ń ra àwọn èlò àti irin iṣẹ́ tá a fi ń tẹ̀wé, kì í sì í ṣe owó kékeré la fi ń kó wọn wọlé sórílẹ̀-èdè yìí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ibú owó tó máa ń ná wa láti kó àwọn oúnjẹ tẹ̀mí náà lọ sí gbogbo ìjọ. Nítorí náà, a rí i bí ohun tó tọ́ láti mẹ́nu ba àwọn nǹkan díẹ̀ tó yẹ ká fi sọ́kàn nípa àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí.
2 Kí nìdí tá a fi ní láti máa fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà kárí ayé? (Ka Òwe 3:9.) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti máa fi ohun ìní wa tó níye lórí bọlá fún Jèhófà. Òun ló ń fún wa ní gbogbo nǹkan tá a ní. Àwọn ọrẹ tá a bá sì fi sílẹ̀ máa fi hàn pé a mọrírì ohun tó ń ṣe fún wa. Ṣebí ọlá Jèhófà là ń jẹ, àbí? Kò wá yẹ kó jẹ́ pé àwọn tá a bá fún ní ìtẹ̀jáde wa nìkan la ó máa retí pé kí wọ́n fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn.
3 Ọwọ́ wo ló yẹ ká máa fi mú àwọn ìtẹ̀jáde wa? (Ka Mátíù 25:21.) Ìṣòtítọ́ ni ìlànà tí Bíbélì tẹnu mọ́ níhìn-ín. Tá a bá ń ṣòótọ́, Jèhófà á túbọ̀ máa bù kún wa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ọ̀rọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa kò le tóyẹn. Ṣùgbọ́n tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré, nǹkan ńlá lè tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ síkàáwọ́ wa. Àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó níye lórí gan-an ló wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, ó sì yẹ ká máa fi hàn bẹ́ẹ̀ nínú ọwọ́ tá a fi ń mú wọn. Kò yẹ ká máa fi àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí sílẹ̀ fáwọn ọmọ kéékèèké tí wọn ò mọ ohun tó wà fún tí wọ́n sì lè fà á ya. Báwọn ọmọdé bá ti mọ̀wé kà dáadáa débi táwọn náà fi lè máa dá tiwọn gbà, ó yẹ ká kọ́ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa tọ́jú ìtẹ̀jáde wọ̀nyí kí wọ́n má bàa dọ̀tí. Láwọn ìjọ kan, a máa ń rí àwọn ìtẹ̀jáde wa tí wọ́n ti lò dọ̀tí nílẹ̀ẹ́lẹ̀ níbi tí wọ́n sọ wọ́n sí. Èyí fi hàn pé a ò fi bẹ́ẹ̀ mọyì báwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe ṣeyebíye tó.
4 Kí ni ṣíṣe bí mi ò bá ní ọrẹ tó pọ̀ tó láti fi ṣètìlẹ́yìn tí mo sì fẹ́ gba ìtẹ̀jáde? (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:13-15.) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń fẹ́ kí gbogbo wa jàǹfààní látinú àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí tá à ń gbà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé. Ìdí nìyẹn tí ètò Jèhófà fi sọ pé káwọn ìtẹ̀jáde tá a sábà máa ń lò láwọn ìpàdé ìjọ máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó, irú bí Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìwé tá a máa ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Síbẹ̀, kò yẹ ká ṣi àǹfààní yìí lò tàbí ká fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú un. A sì tún lè máa pín ọ̀pọ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde yòókù lò láàárín ara wa, ìyẹn àwọn bíi kásẹ́ẹ̀tì, àwo CD tàbí ti DVD àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tí a kì í fi sóde. Kò pọn dandan kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan àwọn ìtẹ̀jáde tá a mẹ́nu bà kẹ́yìn yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọ̀ranyàn pé kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní gbogbo kásẹ́ẹ̀tì fídíò àtàwọn àwo DVD tá a ti ṣe jáde.
5 Yálà a gba ìtẹ̀jáde tàbí a ò gbà á, ó yẹ ká mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa àti pé ojúṣe wa ni láti máa fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà kárí ayé. Ó sì yẹ ká fojú pàtàkì wo àǹfààní yìí kódà bá ò tiẹ̀ ní ọrẹ tó pọ̀ tó láti fi ṣètìlẹ́yìn.
6 A nírètí pé àlàyé yìí á túbọ̀ mú ká fẹ́ láti máa ní ìmọrírì tó pọ̀ sí i fáwọn ìtẹ̀jáde tó ń wá látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ náà. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré, nípasẹ̀ ojú tá a fi ń wo àwọn ìtẹ̀jáde wa àti bá a ṣe ń lò wọ́n, kí àwọn nǹkan ńlá lè tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ síkàáwọ́ wa lọ́jọ́ iwájú.