Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù September: Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? la ó lò. Ká sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fẹ́ni náà. Báwọn tó o wàásù fún bá sọ pé àwọn ti ní ìwé yìí lọ́wọ́, ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wọn ní ṣókí, kí wọ́n lè mọ bi ìwé náà ṣe lè ṣe wọ́n láǹfààní. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Bí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀, kó o sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la máa lò. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, a máa fún wọn ní ìwé Ẹ Máa Ṣọ́nà! December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tàbí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
◼ Níwọ̀n bí oṣù September ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Ní ọ̀kan nínú àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ṣe lóṣù December, a óò jíròrò fídíò tó dá lórí àwọn ọ̀nà tá a gbà ń wàásù, ìyẹn Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News. Kí ẹni tó bá fẹ́ fídíò yìí má ṣe jáfara láti béèrè nípasẹ̀ ìjọ.
◼ Nínú ọ̀sẹ̀ March 31, 2008 la máa sọ àkànṣe àsọyé tó wà fún sáà Ìṣe Ìrántí tọdún 2008. A ó ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Káwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ ọ́ ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú ọ̀sẹ̀ March 31.
◼ Kí alága àwọn alábòójútó tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ láwọn oṣù June, July àti August. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.—Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).
◼ A ti di báàjì àpéjọ àgbègbè tọdún 2007 mọ́ ara àwọn ìwé àti fọ́ọ̀mù tá à ń fi ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ lọ́dọọdún. Torí náà, kò ní pọn dandan pé kẹ́ ẹ béèrè fún wọn mọ́. Bí ìjọ èyíkéyìí bá fẹ́ báàjì sí i, inú fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14), ni kẹ́ ẹ kọ iye tẹ́ ẹ fẹ́ sí, kẹ́ ẹ sì fi ránṣẹ́. Àròpọ̀ iye ike báàjì táwọn ará bá fẹ́ géérégé ni kẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì o.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (ẹlẹ́yìn-rírọ̀, àwọ̀ dúdú tàbí pupa)—Gẹ̀ẹ́sì
Watch Tower Publications Index—2006—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwo CD Tó Tún Ti Wà Lọ́wọ́ Báyìí:
Kingdom Melodies—Lórí Àwo CD, Apá 4 (Àtúnṣe)
Kingdom Melodies—Lórí Àwo MP3
Watchtower Library Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò, Ẹ̀dà ti 2006—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwo DVD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News àti Our Whole Association of Brothers—Lórí Àwo DVD—Gẹ̀ẹ́sì