Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fọwọ́ sí báwọn ará wa kan ṣe ń kóra jọ láyè ara wọn láti ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ tàbí torí àtimáa bára wọn jiyàn lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ?—Mát. 24:45, 47.
Rárá o. Àmọ́, lónírúurú ibi lágbàáyé, àwọn ará wa kan ti kóra jọ láyè ara wọn torí àtimáa ṣèwádìí àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí Bíbélì. Àwọn kan tiẹ̀ ti kóra jọ torí àtikọ́ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ojúlówó ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jẹ́ tàbí ayédèrú. Àwọn míì ń fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì. Wọ́n ti ní àwọn ìkànnì àti àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kí wọ́n lè máa jíròrò báwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn ṣe yé wọn sí láàárín ara wọn. Wọ́n tiẹ̀ ti ṣe àwọn ìpàdé àpérò kan, wọ́n sì ti tẹ àbárèbábọ̀ wọn jáde láti fi ṣàtìlẹ́yìn fún òtítọ́ tá à ń kọ́ ní ìpàdé ìjọ àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.
Lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé làwọn èèyàn Jèhófà ti ń gba ìtọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń rí ọ̀rọ̀ ìyànjú gbà ní ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ ńlá àti nínú àwọn ìwé tí ètò Jèhófà tẹ̀ jáde. Jèhófà ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pèsè ohun tá a nílò kí gbogbo àwa èèyàn rẹ̀ lè wà ní ìṣọ̀kan “rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà” ká sì lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (1 Kọ́r. 1:10; Kól. 2:6, 7) Ó dájú pé a mọrírì bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ló ń fún wa ní ìtọ́ni láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Nítorí náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kò fọwọ́ sí àwọn ìtẹ̀jáde tàbí àwọn ìpàdé àpérò èyíkéyìí, títí kan àwọn ìkànnì orí kọ̀ǹpútà tí kì í bá ṣe ẹrú náà ló dá a sílẹ̀ tàbí tí kì í bá ṣe ẹrú náà ló ń bójú tó o.—Mát. 24:45-47.
Ohun tó dáa ni kéèyàn fẹ́ lo làákàyè rẹ̀ láti kọ́wọ́ ti ìhìn rere náà. Bó ti wù kó rí, ohun yòówù tá a bá ń ṣe láyè ara wa ò gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ohun tí Jésù Kristi ń tipasẹ̀ ìjọ rẹ̀ ṣe lórí ilẹ̀ ayé lákòókò yìí. Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé káwọn Kristẹni máa ṣọ́ra fún àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kúdórógbó tó máa ń gba àkókò, irú bí “ìtàn ìlà ìdílé, èyí tí kì í yọrí sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n tí ń mú àwọn ìbéèrè fún ìwádìí jinlẹ̀ wá dípò pípín ohunkóhun fúnni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 1:3-7) Ńṣe ni kí gbogbo àwa Kristẹni yáa rí i pé a sapá láti “máa yẹ àwọn ìbéèrè òmùgọ̀ sílẹ̀ àti àwọn ìtàn ìlà ìdílé àti gbọ́nmi-si-omi-ò-to àti àwọn ìjà lórí Òfin, nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìlérè àti ìmúlẹ̀mófo.”—Títù 3:9.
A dá a lábàá pé káwọn tó bá fẹ́ wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ máa lo ìwé Insight on the Scriptures, “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” àtàwọn ìtẹ̀jáde wa míì bí irú àwọn tó tú pẹrẹ́-pẹrẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì, Aísáyà àti Ìṣípayá. Àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe àlàyé tó pọ̀ tó, tó sì lè wúlò fún wa nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà tá a bá ń ṣàṣàrò. Bá a bá ń lo àwọn ìwé náà, wọ́n máa jẹ́ ká lè “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run] nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye tí ẹ̀mí, kí [á] lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí [a] ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo, tí [a] sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.”—Kól. 1:9, 10.