◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́jọ kọjá ogún ìṣẹ́jú [8:20] ni ohùn orin máa bẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Tí ohùn orin bá ti bẹ̀rẹ̀, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago mẹ́rin ku ìṣẹ́jú márùn-ún [3:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá [2:50] ní ọ̀sán Sunday.
◼ Àpéjọ Àgbáyé: Àpéjọ àgbáyé máa wáyé láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ẹ fi sọ́kàn pé a ti yan àwọn ìjọ àtàwọn aṣojú láti ilẹ̀-òkèèrè tó máa lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé yìí lẹ́yìn tí wọ́n ti fara balẹ̀ gbéṣirò lé iye ìjókòó tó wà níbẹ̀, àyè ìgbọ́kọ̀sí àti iye yàrá òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n lè rí lò. Báwọn akéde bá lọ sí àpéjọ tí a kò yàn wọ́n sí, ńṣe ni èrò tó máa wà níbẹ̀ á pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Tó o bá fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè tó yàtọ̀ sí èyí tí a yan ìjọ rẹ sí, má ṣe lọ sí àpéjọ àgbáyé.
◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Àwọn olùtọ́jú èrò máa darí yín síbi ìgbọ́kọ̀sí bẹ́ ẹ bá ṣe ń dé. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 13:4, 5.
◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbénú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún. A ti ṣètò àyè ìjókòó tá a dìídì pèsè fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláìlera. Nígbà tó sì jẹ́ pé, àyè ìjókòó yìí kò pọ̀ púpọ̀, ẹni kan tàbí méjì péré tó bá ń bójú tó àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláìlera yìí ló lè jókòó sí ẹ̀gbẹ́ wọn.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Àwọn arábìnrin wa tó wé gèlè tó lè dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú máa fi hàn pé àwọn ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò tí wọ́n bá tú gèlè wọn nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́.
◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ ra oúnjẹ lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.
◼ Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọyì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn kọ ọ́ síbẹ̀ pé “Watch Tower” ni kí wọ́n sanwó náà fún. Kí ẹni náà kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.
◼ Lílo Oògùn: Tó o bá ní oògùn tí ò ń lò, jọ̀wọ́ mú èyí tó máa tó ẹ lò dání wá sí àpéjọ, torí pé a lè máà ní irú oògùn bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí àwọn tó bá ń lo abẹ́rẹ́ fún ìtọ̀ ṣúgà rí i dájú pé àwọn tọ́jú abẹ́rẹ́ náà dáadáa, kí wọ́n má ṣe jù ú sínú àwọn ike ìkólẹ̀sí tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti ti ibi tí wọ́n bá dé sí.
◼ Ìránnilétí Nípa Ààbò: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rí i dájú pé kò sí ohunkóhun tó lè kọ́ni lẹ́sẹ̀ tàbí gbéni ṣubú. Lọ́dọọdún àwọn èèyàn sábà máa ń fara pa nítorí irú bàtà tí wọ́n ń wọ̀, pàápàá àwọn tó bá wọ bàtà gogoro. Torí náà, ó máa dáa kó o wọ bàtà tí kò ga, tó bójú mu tó máa jẹ́ kó o lè rìn láì fara pa.
◼ Àga Ọmọdé Tó Ní Táyà Lẹ́sẹ̀ àti Àga Ìnàyìn: Ẹ má ṣe gbé àga ọmọdé tó ní táyà lẹ́sẹ̀ àti àga ìnàyìn wá sí àpéjọ àgbègbè. Àmọ́ ẹ lè gbé ìjókòó ọmọdé tó ṣeé dè sórí àga ní ẹ̀gbẹ́ òbí ọmọ náà wá.
◼ Lọ́fíńdà: A máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tí a bá ṣọ́ra fún lílo àwọn lọ́fíńdà tó ní òórùn líle, kí a má bàa ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—1 Kọ́r. 10:24.
◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43): Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè, tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43). Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín ní gbàrà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.
◼ Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ ká fi ìwà rere bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá wà nílé oúnjẹ. Ká múra lọ́nà tó yẹ Kristẹni. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra ọjà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.
◼ Ilé Gbígbé:
Tí ẹ bá gba yàrá tẹ́ ẹ máa dé sí ní ọ̀tẹ́ẹ̀lì, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe gbà ju iye yàrá tẹ́ ẹ nílò lọ, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí iye èèyàn tó máa wà pẹ̀lú yín nínú yàrá pọ̀ ju iye tí wọ́n gbà láyè lọ.
Má ṣe wọ́gi lé ètò tó o ṣe láti dé sí òtẹ́ẹ̀lì, àyàfi tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá wáyé, kó o sì sọ fún àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí àwọn ẹlòmíì lè gba yàrá náà. (Mát. 5:37) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá owó rẹ pa dà fún ẹ tó o bá tètè sọ fún wọn kó tó ku ọjọ́ méjì ṣáájú ìgbà tó yẹ kó o dé síbẹ̀.
Tó o bá gba ohun èlò tí wọ́n fi ń kó ẹrù, rí i pé o lò ó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kó o sì tètè dá a pa dà káwọn ẹlòmíì lè rí i lò.
Ibi tí wọ́n bá sọ pé kó o ti dáná nìkan ni kó o ti máa dáná. Má ṣe dáná nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, torí ìyẹn kò ní fi hàn pé o mọyì nǹkan tẹ̀mí.
Láwọn òtẹ́ẹ̀lì kan, wọ́n máa ń fi ìpápánu, kọfí, ọtí ẹlẹ́rìndòdò àtàwọn nǹkan míì sínú yàrá tẹ́ ẹ máa dé sí, jọ̀wọ́ má ṣe mú ju iye tó yẹ lọ.
Rí i pé o fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé sọ̀rọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ yìí ń bójú tó èrò tó pọ̀. Wọ́n máa mọyì sùúrù, inú rere àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò tá a bá fi hàn sí wọn.
Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa ní òtẹ́ẹ̀lì, níbi odò ìlúwẹ̀ẹ́, láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà, ní ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ibòmíì.
Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá sọ pé kó o dé síbẹ̀. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, kó o dé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. Kí àwọn arákùnrin má ṣe di alẹ́ sínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yàrá tó wà fún àwọn arákùnrin.
Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ọ́ sí, rí i dájú pé o fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
◼ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.