ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/15 ojú ìwé 4-6
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Fi Ìwà Rẹ Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 7/15 ojú ìwé 4-6

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

  • Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́jọ kọjá ogún ìṣẹ́jú [8:20] ni ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ohùn orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọ, ó yẹ kí olúkúlùkù wa lọ jókòó ká lè bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà lọ́nà tó bójú mu. Àpéjọ náà máa parí ní aago mẹ́rin ku ìṣẹ́jú márùn-ún [3:55] ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday àti ọjọ́ Sátidé, ó sì máa parí ní aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [2:45] ní ọ̀sán Sunday.

  • ‘Fi Orin Gbé Jèhófà Lárugẹ’: Látìgbà àtijọ́ ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti máa ń fi orin yin Jèhófà, lóde oní pẹ̀lú, orin ṣì jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa. (Sm. 28:7) Ohùn orin la máa fi ń bẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan àpéjọ àgbègbè wa. Orin yìí kì í ṣe ohùn orin tó kàn ń dún lábẹ́lẹ̀ lásán, àmọ́ ńṣe la dìídì ṣètò rẹ̀ ká bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ká sì jọ́sìn rẹ̀. Torí náà, tí alága bá ṣèfilọ̀ pé ohùn orin ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, ńṣe ló yẹ ká lọ jókòó, ká sì máa tẹ́tí sí orin náà ká lè fi hàn pé a mọrírì rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn akọrin tó ń bá Watchtower kọrin ń ṣe. Lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí máa ń fi owó ara wọn rìnrìn-àjò lọ sí ìlú Patterson, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, láti gbé orín aládùn jáde fún ìgbádùn wa. Lẹ́yìn tá a bá ti fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohùn orin náà, gbogbo wa pátá á wa pa ohùn wa pọ̀ láti fi orin yin Jèhófà nípa kíkọ orin Ìjọba Ọlọ́run.

  • Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Àwọn tó ń bójú tó ibi ìgbọ́kọ̀sí máa darí wa síbi tá a máa gbé ọkọ̀ wa sí. A ò ní ìbi ìgbọ́kọ̀sí tó fẹ̀ tó, torí náà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ẹ̀yin àtàwọn ẹlòmíì lè jọ gbé mọ́tò kan dípò tí kálukú á fi gbé ọkọ̀ tiẹ̀ sọ́nà. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń bójú tó ibi ìgbọ́kọ̀sí.—1 Kọ́r. 13:4, 5.

  • Gbígba Àyè Ìjókòó Sílẹ̀: Tí wọ́n bá ti ń ṣí ilẹ̀kùn ibi tẹ́ ẹ ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè láràárọ̀ ọjọ́ àpéjọ, ẹ má ṣe máa sáré du àyè ìjókòó bí ìgbà tí ẹ̀ ń bára yín figa gbága. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ ká máa gba ti àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa rò, kódà tó bá gba pé ká jẹ́ kí wọ́n jókòó síbi tá a fẹ́ jókòó sí. Tá a bá ń lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, èyí á fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, àwọn tó ń kíyè sí wa á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ògo fún Ọlọ́run. (Jòh. 13:34, 35; 1 Kọ́r. 13:5; 1 Pét. 2:12) Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọ ọkọ̀ kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gbàyè sílẹ̀ fún. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe fi ohunkóhun gba àyè síbi tí ẹ kò ní jókòó sí. Èyí á jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì rí àyè jókòó sí. A ti ṣètò àyè ìjókòó tá a dìídì pèsè fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláìlera. Nígbà tó sì jẹ́ pé, àyè ìjókòó yìí kò pọ̀ púpọ̀, ẹni kan tàbí méjì péré tó bá ń bójú tó àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláìlera yìí ló lè jókòó sí ẹ̀gbẹ́ wọn.

  • Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu: Ó yẹ kí ìmúra wa bójú mu nígbà àpéjọ, kó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó má ṣe dà bí ìwọ̀kuwọ̀ tó wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí. (1 Tím. 2:9) Kódà tá a bá wà ní òtẹ́ẹ̀lì tá a dé sí tàbí tá a bá ń jáde àti nígbà tá a fẹ́ najú lọ ṣáájú àti lẹ́yin ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kò yẹ ká múra lọ́nà tí kò bójú mu tàbí kí ìmúra wa rí wúruwùru. Tá a bá múra lọ́nà tó bójú mu, yóò yá wa lára láti fi báàjì àpéjọ sáyà, ojú ò sì ní máa tì wá tá a bá láǹfààní láti wàásù. Ìmúra tó bójú mu àti ìwà rere wa nígbà àpéjọ àgbègbè wa tó ń bọ̀ yìí á jẹ́ kí àwọn tó lọ́kàn rere nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ń gbẹ̀mí là tá à ń sọ fún wọn, yóò sì tún múnú Jèhófà dùn gan-an.—Sef. 3:17.

  • Gba Tàwọn Míì Rò Tó O Bá Ń Lo Ẹ̀rọ Alágbèéká: A máa fi hàn pé a gba tàwọn míì rò nígbà tí àpéjọ náà bá ń lọ lọ́wọ́, tá a bá gbé ẹ̀rọ̀ alágbèéká wa tàbí àwọn ẹ̀rọ míì sí ipò tí kò fi ní ṣèdíwọ́ fún àwọn míì. Tá a bá ń lo kámẹ́rà, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀, ẹ̀rọ tablet tàbí àwọn nǹkan tó jọ ọ́, a fẹ́ gba tàwọn míì rò nípa ṣíṣàì dí wọn lọ́wọ́, ká má sì ṣe dí wọn lójú. A tún máa fi hàn pé a gba tàwọn míì rò tá a bá yẹra fún títẹ àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ká máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láì nídìí nígbà tí àpéjọ náà bá ń lọ lọ́wọ́.

  • Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ ọ̀sán wá dípò tẹ́ ẹ fi máa kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti lọ ra oúnjẹ lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè lo kúlà kékeré tó ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ lo àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò tó lè fọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

  • Ọrẹ: A lè fi hàn pé a mọyì ètò tá a ṣe láti mú kí àpéjọ yìí wáyé bá a bá fínnú fíndọ̀ fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Kí ẹni tó bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn kọ ọ́ síbẹ̀ pé “Watch Tower Society of Jehovah’s Witnesses” ni kí wọ́n sanwó náà fún. A tún lè lo káàdì ATM láti fi ṣètìlẹyìn.

  • Lílo Oògùn: Tó o bá ní oògùn tí ò ń lò, jọ̀wọ́ mú èyí tó máa tó ẹ lò dání wá sí àpéjọ, torí pé a lè máà ní irú oògùn bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kí àwọn tó bá ń lo abẹ́rẹ́ fún ìtọ̀ ṣúgà rí i dájú pé àwọn tọ́jú abẹ́rẹ́ náà dáadáa, kí wọ́n má ṣe jù ú sínú àwọn ike ìkólẹ̀sí tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti ti ibi tí wọ́n bá dé sí.

  • Ìránnilétí Nípa Ààbò: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rí i dájú pé kò sí ohunkóhun tó lè kọ́ni lẹ́sẹ̀ tàbí gbéni ṣubú. Lọ́dọọdún àwọn èèyàn sábà máa ń fara pa nítorí irú bàtà tí wọ́n ń wọ̀, pàápàá àwọn tó bá wọ bàtà gogoro. Torí náà, ó máa dáa kó o wọ bàtà tí kò ga, tó bójú mu tó máa jẹ́ kó o lè rìn láì fara pa.

  • Àga Ọmọdé Tó Ní Táyà Lẹ́sẹ̀ àti Àga Ìnàyìn: Ẹ má ṣe gbé àga ọmọdé tó ní táyà lẹ́sẹ̀ àti àga ìnàyìn wá sí àpéjọ àgbègbè. Àmọ́ ẹ lè gbé ìjókòó ọmọdé tó ṣeé dè sórí àga ní ẹ̀gbẹ́ òbí ọmọ náà wá.

  • Lọ́fíńdà: A máa fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò tí a bá lo àwọn lọ́fíńdà tó ní òórùn líle níwọ̀n tàbí ká tiẹ̀ má lò ó rárá, kí a má bàa ṣàkóbá fún àwọn tó níṣòro èémí.—1 Kọ́r. 10:24.

  • Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43): Bẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan nígbà àpéjọ àgbègbè, tí ẹni náà sì fìfẹ́ hàn, ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43). Ẹ lè mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí fún wọn ní Ilé Ìgbàwé tàbí kẹ́ ẹ fún akọ̀wé ìjọ yín ní gbàrà tẹ́ ẹ bá pa dà délé.

  • Búkà Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Níwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ẹ jẹ́ ká fi ìwà rere bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá wà nílé oúnjẹ. Ká múra lọ́nà tó yẹ Kristẹni. Kò bọ́gbọ́n mu láti lọ ra ọjà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.

  • Òtẹ́ẹ̀lì Àtàwọn Ilé Gbígbé Míì:

    1. Tí ẹ bá gba yàrá tẹ́ ẹ máa dé sí ní òtẹ́ẹ̀lì, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe gbà ju iye yàrá tẹ́ ẹ nílò lọ, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí iye èèyàn tó máa wà pẹ̀lú yín nínú yàrá pọ̀ ju iye tí wọ́n gbà láyè lọ.

    2. Má ṣe wọ́gi lé ètò tó o ṣe láti dé sí òtẹ́ẹ̀lì, àyàfi tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá wáyé, kó o sì sọ fún àwọn tó ń bójú tó òtẹ́ẹ̀lì náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí àwọn ẹlòmíì lè gba yàrá náà. (Mát. 5:37) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá owó rẹ pa dà fún ẹ tó o bá tètè sọ fún wọn kó tó ku ọjọ́ méjì ṣáájú ìgbà tó yẹ kó o dé síbẹ̀.

    3. Tó o bá gba ohun èlò tí wọ́n fi ń kó ẹrù, rí i pé o lò ó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kó o sì tètè dá a pa dà káwọn ẹlòmíì lè rí i lò.

    4. Ibi tí wọ́n bá sọ pé kó o ti dáná nìkan ni kó o ti máa dáná.

    5. Láwọn òtẹ́ẹ̀lì kan, wọ́n máa ń fi ìpápánu, kọfí, ọtí ẹlẹ́rìndòdò àtàwọn nǹkan míì sínú yàrá tẹ́ ẹ máa dé sí, jọ̀wọ́ má ṣe mú ju iye tó yẹ lọ.

    6. Rí i pé o fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé sọ̀rọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ yìí ń bójú tó èrò tó pọ̀. Wọ́n máa mọyì sùúrù, inú rere àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò tá a bá fi hàn sí wọn.

    7. Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa ní òtẹ́ẹ̀lì, níbi odò ìlúwẹ̀ẹ́, láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà, ní ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ibòmíì.

    8. Má ṣe dé sínú ilé gbígbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kò bá sọ pé kó o dé síbẹ̀ torí kí ibẹ̀ má bàa kún ju bó ṣe yẹ lọ. Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, kó o dé sí kìkì ibi tí wọ́n bá ní kó o dé sí. Kí àwọn arákùnrin má ṣe di alẹ́ sínú yàrá tó wà fún àwọn arábìnrin, wọn kò sì gbọ́dọ̀ sùn síbẹ̀. Àwọn arábìnrin pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yàrá tó wà fún àwọn arákùnrin.

    9. Bí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú nípa ibi tí wọ́n fi ọ́ sí, rí i dájú pé o fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kó o tó kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Kí ẹni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọ àgbègbè. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] pẹ̀lú lè yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí alágbàtọ́ wọn tàbí àgbàlagbà míì tá a bá fà wọ́n lé lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́