Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 25
Orin 112 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 12 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 14-16 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: “Ọgọ́rùn-ún Ọdún Rèé Tá A Ti Ń Polongo Ìjọba Ọlọ́run!”—Apá Kìíní. (Ìpínrọ̀ 1 sí 3) Ìjíròrò tó dá lórí ìpínrọ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́. Lẹ́yìn tó o bá ti béèrè ìbéèrè ìpínrọ̀ 3, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde méjì tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Ní kí wọ́n sọ díẹ̀ nínú àwọn ìrírí tí wọ́n ní nípa bí wọ́n ṣe ń wàásù nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde.
15 min: “Ọgọ́rùn-ún Ọdún Rèé Tá A Ti Ń Polongo Ìjọba Ọlọ́run!”—Apá Kejì. (Ìpínrọ̀ 4 sí 6) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tí ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5 àti 6, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì nípa bí wọ́n ṣe wá àyè fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
Orin 103 àti Àdúrà