Àpótí Ìbéèrè
◼ Báwo ló ṣe yẹ ká múra nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ilé tá à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ilé míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń lò lágbàáyé la ti dìídì yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Àwọn ilé wọ̀nyí bójú mu, wọ́n mọ́ tónítóní, wọn ò sì rí wúruwùru, ìyẹn ló sì mú káwọn èèyàn máa fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n. Ká sòótọ́, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà láàárín àwọn ilé wọ̀nyí àtàwọn ohun tá à ń rí nínú ètò Sátánì. Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé kí ìrísí àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ilé wọ̀nyí jọ tàwọn tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Bá a ṣe jẹ́ Kristẹni, à ń “dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run” nínú ohun gbogbo, èyí sì kan wíwọ aṣọ tó bójú mu, kí ìmúra wa sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. (2 Kọ́r. 6:3, 4) Ó tún yẹ ká máa hùwà ọmọlúwàbí. Gbogbo ìgbà ló sì yẹ kí aṣọ àti ìmúra wa máa bá tàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run mu. Gbogbo ìwọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an àgàgà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Igieduma, oríléeṣẹ́ wa, tàbí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà kárí ayé.
Nígbà tí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà máa sọ̀rọ̀ lórí ìjẹ́pàtàkì aṣọ àti ìmúra wa, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa wà ní mímọ́ tónítóní, ká máa wọṣọ tó dáa ká sì máa múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì tá a bá ń lọ sóde ẹ̀rí tàbí tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Ìpínrọ̀ kìíní lójú ìwé 139 sọ pé: “Ká rántí pé ‘ilé Ọlọ́run’ ni Bẹ́tẹ́lì túmọ̀ sí. Nítorí náà, aṣọ wa, ìmúra wa àti ìwà wa kò gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí bó ṣe yẹ kó rí bá a bá ń lọ sí ìpàdé láti lọ jọ́sìn nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Ìlànà yìí ló yẹ káwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run máa fi sílò tí wọ́n bá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì, ì báà jẹ́ láti ìtòsí tàbí láti ọ̀nà jíjìn. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a mọrírì ilé náà a sì mọyì rẹ̀.—Sm. 29:2.
Aṣọ tá à ń wọ̀ gbọ́dọ̀ fi wá hàn bí ẹni “tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé [òun] ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tím. 2:10) Aṣọ tó bójú mu tá à ń wọ̀ àti ìmúra wa máa ń jẹ́ káwọn ẹlòmíì fojú tó dáa wo ìjọsìn Jèhófà. Àmọ́, a ti kíyè sí i pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ilé tá à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kì í kọbi ara sí irú aṣọ tí wọ́n máa ń wọ̀, àwọn kan tiẹ̀ máa ń wọ àwọn aṣọ tó ń ṣí ara sílẹ̀ pàápàá. Kò sígbà tírú àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀ yẹ àwọn Kristẹni. Lórí ọ̀ràn yìí títí kan àwọn apá ìjọsìn wa tó kù, a fẹ́ máa bá a lọ ní títẹ̀lé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tó ń fàwọn èèyàn Ọlọ́run hàn yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé, bá a ti ń ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.—Róòmù 12:2; 1 Kọ́r. 10:31.
Nítorí náà, nígbàkigbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa tàbí àwọn ilé míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń lò, yálà ẹ ti ṣètò lílọ síbẹ̀ ṣáájú ni o tàbí ẹ kàn fẹ́ fi ẹsẹ̀ kan yà síbẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ rìnrìn àjò afẹ́ wá ságbègbè ibẹ̀, ẹ máa bi ara yín pé: ‘Ṣé aṣọ tí mo wọ̀ àti bí mo ṣe múra bá ibi tí mò ń lọ tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì mọ́ tónítóní mu? Ṣó pọ́n Ọlọ́run tí mò ń sìn lé? Ṣé irú aṣọ tí mo wọ̀ yìí ò ní mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀ tàbí kó mú wọn bínú báyìí?’ Ǹjẹ́ ká máa fi hàn nínú ìmúra wa àti ọ̀nà tá à ń gbà wọṣọ pé gbogbo ìgbà là ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo!”—Títù 2:10.