ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/02 ojú ìwé 2
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 6/02 ojú ìwé 2

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ìlànà wo ló yẹ ká tẹ̀ lé ní ti ìwọṣọ àti ìmúra wa nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì àti àwọn ilé mìíràn tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ń lò?

Nígbà tá a bá ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì, bóyá láti lọ rìn yíká ọgbà náà tàbí láti lọ kí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, “aṣọ wa, imura wa ati iwa wa gbọdọ rí bakan naa pẹlu ohun tí a reti lati ọ̀dọ̀ wa nigba tí a bá nlọ si awọn ipade fun ijọsin ní Gbọngan Ijọba.” (om-YR 131) Àmọ́, a ti ṣàkíyèsí pé nígbà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́, wọ́n sábà máa ń múra lọ́nà ṣákálá. Irú ìmúra bẹ́ẹ̀ kò bójú mu tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi wọ̀nyí. Ìrísí wa ní láti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, kí ó wà létòlétò kó sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, èyí tí yóò máa fi ìwàlétòlétò àti iyì tó yẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run han.—1 Tím. 2:9, 10.

Èyí ṣe pàtàkì gan-an nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì àti àwọn ilé mìíràn tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ń lò, nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ló ń wo àwọn àlejò wọ̀nyí. Ohun tí irú àwọn ẹni tó ń wò wá bá rí lè mú kí wọ́n máa ronú òdì nípa àwa èèyàn Ọlọ́run àti ètò àjọ rẹ̀. Á dára láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àtàwọn mìíràn tó lè fẹ́ẹ́ ṣèbẹ̀wò sọ̀rọ̀, ká sì rán wọn létí pé ó ṣe pàtàkì kí ìwọṣọ àti ìmúra wọn bójú mu. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì yóò mọrírì rẹ̀ bẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Níwọ̀n bí a ti jẹ́ Kristẹni òjíṣẹ́, a ní láti kíyè sára kí ìrísí wa má bàa fa ìkọ̀sẹ̀ lọ́nàkọnà. (2 Kọ́r. 6:3, 4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa hùwà tó bójú mu, ká sì máa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́