Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 10
Orin 58
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò Our Whole Association of Brothers láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ June 24. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 15 àti Jí! July 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà lójú ìwé 4 láti fi Jí! July 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ka gbogbo àpilẹ̀kọ náà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, ṣe àfikún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí àwọn kókó mìíràn látinú Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1998.
20 min: “Fífúnrúgbìn Yanturu Máa Ń Mú Ìbùkún Jìngbìnnì Wá.”a Fi àwọn àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1992, ojú ìwé 15 sí 16, ìpínrọ̀ 14 sí 17.
Orin 220 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 17
Orin 136
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Jẹ́ Kí Ohun Tó O Ní Tẹ́ Ọ Lọ́rùn.”b Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbé tá a gbé ìmọ̀ràn yìí karí Ìwé Mímọ́, kó o ka ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí bí àkókò bá ṣe wà sí, kó o sì ṣàlàyé wọn.
Orin 197 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 24
Orin 52
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Tọkọtaya kan ni kó ṣe àṣefihàn yìí. Kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, kí wọ́n wá lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July 8 lọni. Kí ìyàwó fi Ilé Ìṣọ́ lọni, kí ọkọ sì fi Jí! lọni. Lo àbá kejì tó wà lójú ìwé 4 láti fi Jí! July 8 lọni.
12 min: Sọ àwọn ìrírí táwọn ará nínú ìjọ ti ní tàbí kí o ṣàṣefihàn rẹ̀, bóyá (1) nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí fún onírúurú àwùjọ ẹ̀yà tàbí àwọn ẹni tó ń sọ èdè mìíràn, tàbí (2) nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láwọn ọ̀nà mìíràn yàtọ̀ sí ìwàásù ilé-dé-ilé àti ìjẹ́rìí òpópónà. Ní ìmúrasílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, fún olúkúlùkù níṣìírí láti wá ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n lè lò fún ọ̀kan nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a máa fi lọni ní oṣù July àti August.—Wo àpótí náà, “Àwọn Ìtẹ̀jáde Mìíràn,” tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January 2002.
25 min: “Ìdí Tá A Fi Nífẹ̀ẹ́ Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa.” Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò fídíò Our Whole Association of Brothers pẹ̀lú àwùjọ ní tààràtà, kí o lo kìkì àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Ní àfidípò, jíròrò “Ìjọsìn Tòótọ́ Ń So Àwọn Èèyàn Pọ̀ Ṣọ̀kan.” Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 2001, ojú ìwé 5 sí 7.
Orin 95 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 1
Orin 83
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù June sílẹ̀. Ní kí àwọn ará sọ èwo nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ ni wọ́n ń wéwèé láti fi lọni ni oṣù July àti ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa lò.
15 min: Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Tọ́ka sí àwọn apá tó mú kí ìwé pẹlẹbẹ náà wúlò gan-an fún ríran àwọn ọmọdé, àwọn ti kò kàwé púpọ̀ tàbí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wéé kà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwọn àlàyé inú ìwé náà rọrùn ó sì mọ́gbọ́n dání. (Wo ẹ̀kọ́ 2, 8, àti 12.) Fi hàn bá a ṣe lè lo àwọn àwòrán inú rẹ̀ láti fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́kàn. Dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo ìwé pẹlẹbẹ yìí lọ́nà gbígbéṣẹ́. Kí àwọn òbí fi bá àwọn ọmọ wọn kéékèèké ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Fún olúkúlùkù níṣìírí láti fi lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbàkigbà tó bá tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
15 min: “Ǹjẹ́ O ‘Fẹ́’ Láti Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́?”c Fún gbogbo àwọn ará nínú ìjọ níṣìírí láti ní ẹ̀mí ìmúratán láti ṣèrànwọ́.
Orin 156 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.