ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/02 ojú ìwé 6
  • Wíwọṣọ àti Mímúra ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwọṣọ àti Mímúra ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Aṣọ Tí Ó Wà Létòletò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 9/02 ojú ìwé 6

Wíwọṣọ àti Mímúra ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

1 “Gbogbo àwọn ọkùnrin ló de táì, kódà àtàwọn ọmọdékùnrin pàápàá. Gbogbo àwọn obìnrin, àtàgbà àtọmọdé wọn, ló wọ kaba tàbí síkẹ́ẹ̀tì tó bójú mu. Kò sẹ́ni tó wọ ṣòkòtò bí ọmọ ìta tàbí tó wọ ṣẹ́ẹ̀tì láì de táì. Kò sẹ́ni tó múra wúruwùru. Gbogbo ẹni tó pésẹ̀ ló jojú ní gbèsè.” Ohun tí ìròyìn kan sọ nìyí. Irú àwùjọ àwọn èèyàn wo ló ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ná? Ṣé ìpàdé àwọn olóṣèlú làwọn ẹni wọ̀nyí lọ ni? Àbí ibi tí eré ìdárayá ti wáyé? Àbí agbo ijó tàkasúfèé? Rárá o! Ìròyìn náà ń sọ nípa àwùjọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n lọ sí àpéjọ àgbègbè ńlá kan lọ́dún tó kọjá.

2 Ní ìlú mìíràn tí àpéjọ ti wáyé, oníròyìn kan ṣe àpèjúwe yìí nípa àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó pésẹ̀: “Gbogbo àwọn ọkùnrin ló mọ́ tónítóní, tí wọ́n wọ kóòtù ti wọ́n sì de táì. Àwọn obìnrin wọṣọ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ìmúra wọ́n sì gbayì.” Ẹlòmíràn tó tún kíyè sí wọn ni ọlọ́dẹ kan tó ń ṣọ́ àyíká. Ó sọ pé: “Ọmọlúwàbí èèyàn ni yín, ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fúnni, ẹ sì mọ́ tónítóní. Ohun tí mo rí yìí wù mí gan-an ni. Láyé ẹlẹ́gbin tá à ń gbé yìí, ńṣe lẹ̀yin ń gbìyànjú láti mú ìdọ̀tí ọ̀hún kúrò!” Àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí táwọn èèyàn ń sọ nípa wa yìí mà kúkú dára o! Ǹjẹ́ kò yẹ kí inú wa dùn pé àwọn èèyàn ń gbóríyìn gidigidi fún ẹgbẹ́ àwọn ará wa? Láìsí àní-àní, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn ló mú kí ìròyìn rere yẹn ṣeé ṣe nípasẹ̀ ìrísí wọn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ.

3 Kárí ayé, kò sí ibi tí wọn ò ti mọ̀ wá mọ́ ìrísí wa tó máa ń yàtọ̀ gédégédé sí ti gbogbo gbòò. (Mál. 3:18) Kí nìdí? Ó jẹ́ nítorí pé à ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká máa fi “aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara [wa] lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, . . . lọ́nà tí ó yẹ àwọn . . . tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.”—1 Tím. 2:9, 10.

4 Kí Ni Ìwọṣọ àti Ìmúra Rẹ Ń Fi Hàn Nípa Irú Ẹni Tó O Jẹ́? Aṣọ tá a wọ̀ àti ọ̀nà tá a gbà wọ̀ ọ́ ń sọ àwọn ohun kan pàtó nípa wa, ìyẹn ni, ohun tá a gbà gbọ́, ìṣarasíhùwà wa, àti ohun tó wà lọ́kàn wa. Ọ̀nà èyíkéyìí tá a gbà dá aṣọ wa máa ń sọ irú ẹni tá a jẹ́. A kò gbọ́dọ̀ gbé ìrònú àti ìwà ìbàjẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń hù nínú ayé lárugẹ láé. Ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn kì í ṣe bóyá àṣà ìwọṣọ kan layé ń gba tiẹ̀, àmọ́ ohun tó ṣe kókó ni pé, bóyá ó bójú mu fún ẹni tó bá sọ pé òún jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 12:2) Dípò tí a óò fi jẹ́ kí ìrísí wa máa fi ẹ̀mí jẹ́-n-ṣe-tèmi tàbí ìwà pálapàla hàn, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé lóòótọ́ là ń “yin Ọlọ́run lógo.”—1 Pét. 2:12.

5 Nígbà míì, ẹnì kan tó jẹ́ ẹni tuntun, ẹni tí kò tíì nírìírí, tàbí tó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí lè máa tẹ̀ lé àṣà ìwọṣọ àti ìmúra èyíkéyìí tí ayé ń gbé lárugẹ, láìkọ́kọ́ ronú lórí bí èyí ṣe máa nípa lórí ojú táwọn èèyàn á fi wo Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀. Gbogbo wa lè ṣe àyẹ̀wò fínnífínní láti mọ̀ bóyá ìrònú ayé ló ń darí wa. A lè sọ fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, tí a sì bọ̀wọ̀ fún, pé kó sọ ojú ìwòye rẹ̀ nípa ọ̀nà ìwọṣọ wa àti ìmúra wa láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, lẹ́yìn náà, ká wá fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìmọ̀ràn tó bá fún wa.

6 Àwọn kan gbà pé ó yẹ káwọn kíyè sára nípa bí àwọ́n ṣe máa múra nígbà tí àwọ́n bá wà ní gbọ̀ngàn àpéjọ. Àmọ́ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ kíyè sí ìmúra wọn mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń gbafẹ́ lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà bá ti parí. Máa tẹ̀ lé ìlànà gíga tó yẹ àwọn òjíṣẹ́ Kristẹni. (2 Kọ́r. 6:3, 4) Ní gbogbo ibi táwọn èèyàn bá wà, káàdì àpéjọ tá a lẹ̀ mọ́ àyà pẹ̀lú ìwọṣọ àti ìmúra wa tó bójú mu ló ń fi wá hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látàrí èyí, aṣọ wa ní láti máa wà létòlétò kó sì máa wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, èyí ni yóò máa fi hàn pé àwa “kì í ṣe apá kan ayé.”—Jòh. 15:19.

7 Ẹ jẹ́ ká sapá gan-an ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” ti ọdún yìí láti fi hàn pé a jẹ́ “ènìyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run” wa. Ojú rere táwọn èèyàn á fi wò wá tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò fi kún “ìyìn àti ìfùsì àti ẹwà” Jèhófà.—Diu. 26:19.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Bí A Ṣe Lè Yin Jèhófà Lógo:

■ Wọṣọ lọ́nà tó yẹ ẹni tó jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run.

■ Yẹra fún àṣà ìmúra tó ń fi ẹ̀mí ayé hàn.

■ Máa wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, èyí yóò fi hàn pé ò ń hùwà pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́