ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 15
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 15

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 26. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Kí ni Jòhánù Olùbatisí pe Jésù nítorí ipa ìfirúbọ tí ó kó? (Jòhánù 1:29)

2. Ilẹ̀ wo ni “apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá” tí ọ̀pọ̀ ènìyàn Gọ́ọ̀gù ti wá? (Ìsíkíẹ́lì 38:2, 15)

3. Kí ni “ẹgbẹ́ búburú” máa ń bà jẹ́? (1 Kọ́ríńtì 15:33)

4. Lọ́nà wo ni àwọn ènìyàn tó dàgbà dénú gbà ń “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́”? (Hébérù 5:14)

5. Kí ni Ábúsálómù àti Ádóníjà ṣe nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti já ipò ọba gbà? (2 Sámúẹ́lì 15:1; 1 Àwọn Ọba 1:5)

6. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe wí, kí ni kò lè sọ fún ọwọ́ pé: “Èmi kò nílò rẹ”? (1 Kọ́ríńtì 12:21)

7. Ta ni baba Jóṣúà? (Jóṣúà 1:1)

8. Ibo ni Míkà sọ pé “òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí” ní ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́? (Míkà 4:1)

9. Ibo ni a ti sọ òkúta pa Ákáánì àti agbo ilé rẹ̀? (Jóṣúà 7:24)

10. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìgbàgbọ́, kí ni ó sọ pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run? (Hébérù 11:6)

11. Ta ni ọmọ-ọmọ Kéènì? (Jẹ́nẹ́sísì 4:18)

12. Ìran wo ni Sọ́ọ̀lù Ọba ti wá? (1 Sámúẹ́lì 9:21)

13. Wòlíì wo ni Ọlọ́run tipasẹ̀ rẹ̀ fún Dáfídì ní yíyàn ìjìyà mẹ́ta nítorí tí ó fi ìkùgbù ka iye ènìyàn? (1 Kíróníkà 21:9-12)

14. Àwọn wo ni wọ́n jẹ̀bi bíbá Bábílónì Ńlá ṣe àgbèrè? (Ìṣípayá 17:2)

15. Oṣù wo ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí oṣù kìíní nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ ti àwọn Júù? (Ẹ́sítérì 3:7)

16. Ta ló ṣíwájú àwọn ọba alájọṣe tó mú Lọ́ọ̀tì, ọmọ arákùnrin Ábúráhámù, nígbèkùn? (Jẹ́nẹ́sísì 14:9)

17. Àwọn oríṣi aṣọ méjì wo ni wọ́n dárúkọ, tó mú kí Ahasáyà mọ̀ pé Èlíjà ló ránṣẹ́ pé àkéte àìsàn ọba ni yóò di àkéte ikú rẹ̀? (2 Àwọn Ọba 1:8)

18. Iṣẹ́ wo ni àwọn arákùnrin omidan Ṣúlámáítì yàn fún un, tó mú kí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú? (Orin Sólómọ́nì 1:6)

19. Báwo ni ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé ṣe yàn láti kọ orúkọ Ọlọ́run?

20. Orúkọ wo la fún Ọba-Ajagun náà, Jésù, tí a sì kọ sórí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀? (Ìṣípayá 19:16)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ”

2. Mágọ́gù

3. “Ìwà rere”

4. ‘Nípasẹ̀ lílò’

5. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú kí a ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, pẹ̀lú 50 ọkùnrin tí ń sáré níwájú rẹ̀

6. Ojú

7. Núnì

8. “Orí àwọn òkè ńláńlá”

9. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Ákórì

10. “Pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a”

11. Írádì

12. Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì

13. Gádì

14. “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé”

15. Nísàn

16. Kedoláómà, ọba Élámù

17. Ẹ̀wù tí a fi irun ṣe àti ìgbànú awọ

18. Olùtọ́jú àwọn ọgbà àjàrà

19. Yahweh

20. “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́