Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ O ha bojumu fun obinrin Kristian kan lati lo ohun ọṣọ tabi eroja ìṣaralóge, ki o pa irun rẹ láró, tabi ki o tẹle awọn aṣa ti o farajọra bi?
Ni igba ti o ti kọja ati ni ọjọ wa, awọn kan ti wọn sọ pe wọn ntẹle Bibeli ti mu awọn ero alagbara ti o yatọ patapata dagba nipa iṣara lọsoọ.a
Awọn obinrin ninu awọn ṣọọṣi kan kọ lilo eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ ati ohun ọṣọ silẹ patapata. Fun apẹẹrẹ, iwe naa The Amish People rohin pe wọn “ká ìrísí nipa ti ara wọn lọwọ kò nitori wọn ronu pe mẹmba eyikeyi ti o ni ifẹ ọkan mimuna si ìrísí ti aye ni a nhalẹmọ, niwọn bi o ti je pe ifẹ ọkan [yẹn] ni a gbọdọ papọ sori awọn ironu ti ẹmi dipo ti ara. Awọn miiran . . . yoo fa ọrọ yọ lati inu Iwe mimọ.”
Iwe mimọ ti wọn fa ọrọ rẹ yọ nigba yẹn ni 1 Samuẹli 16:7: “Oluwa [“Jehofa,” NW] wi fun Samuẹli pe: ‘Maṣe wo oju rẹ tabi giga rẹ . . . Eniyan a maa wo oju, Oluwa a maa wo ọkan.’” Bi o ti wu ki o ri, ẹsẹ iwe yii nsọ nipa giga Eliabu arakunrin Dafidi. O han kedere lati inu ayika ọrọ naa pe Ọlọrun ko sọ nipa awọn aṣa ati itunraṣe, iru bii boya Dafidi tabi awọn arakunrin rẹ tọju irun wọn tabi lo awọn ohun ọṣọ sara awọn aṣọ wọn.—Jẹnẹsisi 38:18; 2 Samuẹli 14:25, 26; Luuku 15:22.
Eyi ṣakawe pe awọn kan ti wọn gbà pe awọn Kristian gbọdọ mura lọna ṣakala, lailo eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ tabi ohun ọṣọ eyikeyi, nwa itilẹhin nipasẹ awọn ẹsẹ iwe mimọ ti a ṣì lò. Nitootọ Bibeli ko pese itọni ni kikun lori imura ati itunraṣe; bẹẹ ni ko si fọwọsi awọn aṣa ìṣaralóge kan nigba ti o ka awọn miiran leewọ. Ohun ti o pese ni awọn amọna ti o bọgbọnmu. Ẹ jẹ ki a gbe awọn wọnyi yẹwo ki a si wo bi a ṣe le fi wọn silo lonii.
Apọsteli Pọọlu pese itọsọna ti a misi pe: “Bẹẹ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsi [“ti a ṣeto daradara,” NW] ṣe ara wọn ni ọṣọ, pẹlu itiju ati iwa airekọja, kii ṣe pẹlu irun dídì ati wura, tabi péálì tabi aṣọ olowo iyebiye.” (1 Timoti 2:9) Peteru kọ ohun kan naa: “Ọ̀ṣọ́ ẹni ti ki o ma jẹ ọ̀ṣọ́ ode, ti irun dídì, ati ti wura lílò, tabi ti aṣọ wiwọ. Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹni ti o farasin ni ọkan, ninu ọ̀ṣọ́ àìdibàjẹ́ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu, eyi ti i ṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.”—1 Peteru 3:3, 4.
Awọn ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “ṣe lọ̀ṣọ̀ọ́,” “ti a ṣeto daradara” ati “ọṣọ” jẹ awọn oriṣi ẹda koʹsmos, eyi ti o tun jẹ gbongbo ọrọ naa “ohun iṣaraloge,” ti o tumọ si “sisọ di ẹlẹwa paapaa awọ ara.” Nitori naa awọn ẹsẹ Bibeli wọnyi ran wa lọwọ lati dahun awọn ibeere lori ilo awọn ohun ìṣaralóge tabi eroja iṣaralọ́ṣọ̀ọ́, ohun ọṣọ ati awọn apa miiran lori ọṣọ obinrin.
Njẹ ohun ti Pọọlu ati Peteru nsọ ha ni pe awọn Kristian gbọdọ yẹra fun dídi irun wọn, wiwọ péálì ati ohun ọsọ wura, tabi, ni mimu un gbooro lilo awọn ohun ìṣaralóge? Bẹẹkọ. Lati jẹwọ pe itumọ rẹ niyẹn yoo tumọ si pe awọn Kristian arabinrin gbọdọ yẹra fun ‘wiwọ awọn ẹwu awọleke’ bakan naa. Sibẹ, Dọkaasi, ẹni ti Peteru jí dide, ni a fẹran nitori pe oun ṣe “awọn ẹwu awọleke” fun awọn arabinrin miiran. (Iṣe 9:39, NW) Fun idi yii, 1 Timoti 2:9 ati 1 Peteru 3:3, 4 ko tumọ si pe awọn arabinrin gbọdọ yẹra fun didi irun, lilo péálì, awọn ẹwu awọleke, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Kaka bẹẹ, Pọọlu ntẹnumọ aini naa fun iwọntunwọnsi ati ero inu ti o yè kooro ninu imura ati itunraṣe awọn obinrin. Peteru fihan pe awọn obinrin gbọdọ fi iye ti o ga ju sori ohun ti wọn jẹ ninu lọhun un ki wọn ba le jere awọn ọkọ wọn alaigbagbọ pada, ki wọn ma jẹ ki ìrísí ode tabi lilo eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ gbà wọn lọkan ju bi o ti yẹ lọ.
Ki a sọ ọ́ lọna ti o rọrun, Bibeli ko ka gbogbo igbiyanju lati mu ki ìrísí ara ẹni dara sii nipa lilo ohun ọṣọ leewọ. Awọn kan lara awọn iranṣẹ Ọlọrun, lọkunrin ati lobinrin, lo okuta ọṣọ iyebiye. (Jẹnẹsisi 41:42; Ẹkisodu 32:2, 3; Daniẹli 5:29) Ẹsiteri olootọ fohùnṣọ̀kan fun itọju gbigbooro lati ṣalekun ẹwa rẹ pẹlu awọn ororo ìṣaralóge ti a fi wọ́ ọ lara ati awọn lọfinda. (Ẹsiteri 2:7, 12, 15; fiwe Daniẹli 1:3-8.) Ọlọrun sọ pe oun lọna iṣapẹẹrẹ ṣe Isirẹli lọṣọọ pẹlu awọn ẹ̀gbà, ilẹkẹ ọrun kan, oruka imu kan ati awọn yẹrí eti. Awọn wọnyi ṣafikun sisọ ọ́ di ẹni ti o ní “ẹwa gidigidi.”—Esekiẹli 16:11-13.
Bi o ti wu ki o ri, akọsilẹ inu Esekiẹli gbe ẹkọ kan jade lodi si kiko afiyesi wa jọ sori ìrísí. Ọlọrun sọ pe: “Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwa ara rẹ, o si huwa panṣaga nitori okiki rẹ, o si da gbogbo agbere rẹ sori olukuluku ẹni ti nkọja.” (Esekiẹli 16:15; Aisaya 3:16, 19) Nitori naa, Esekiẹli 16:11-15 fun ọgbọn ti o wa ninu imọran Pọọlu ati Peteru lokun nipa ṣiṣai tẹnumọ irisi ode. Bi obinrin kan ba yan lati fi ohun ọṣọ ṣe ara rẹ loge, pipọ ati ọna ìgbàló rẹ̀ gbọdọ ba iwọntun wọnsi mu, ki o ma jẹ lọna aṣeju tabi lọna aṣehan tabi atàn yòyò.—Jakọbu 2:2.
Ki ni nipa ti ki obinrin Kristian kan maa lo awọn ohun ìṣaralóge, iru bii ìtọ́tè, ọdà àkùnsẹ́rẹ̀kẹ́, tabi tìróò ati lẹẹdi ìtọ́sí ìpéǹpéjú? Awọn awalẹpitan ni Isirẹli ati ni agbegbe rẹ ti ri awọn ike eroja ìṣaralọ́ṣòọ́, ati pẹlu awọn ohun elo ti a fi nlo wọn ati awọn jigi. Bẹẹni, awọn obinrin ni Gabasi atijọ lo ohun ìṣaralóge ti o jẹ aṣiwaju fun pupọ ninu awọn amujade ti ode oni. Orukọ ọmọbinrin Joobu naa Kẹrẹn-hapuki ni o jọ pe o tumọ si “Ìwo Ọda Dudu (Oju),” tabi ohun eelo kan fun kíkó ohun ìṣojulọ́ṣòọ́ si.—Joobu 42:13-15.
Awọn ohun ìṣaralóge kan ni a lo ni Isirẹli, sibẹ awọn apẹẹrẹ inu Bibeli fi ewu ti o wa ninu aṣeregee han. Ni ọdun pupọ lẹhin igba ti oun di ayaba ni Isirẹli, Jesebẹli ‘lé tiroo o si ta ori rẹ.’ (2 Ọba 9:30) Lẹhin naa nigba ti o nṣapejuwe bi Isirẹli ṣe wa afiyesi onifẹẹkufẹẹ awọn orilẹ ede abọriṣa, Ọlọrun sọ pe o ‘fi wura ṣe ara rẹ lọṣọọ, fi tiroo kun oju rẹ; o si ṣe ara rẹ daradara.’ (Jeremaya 4:30; Esekiẹli 23:40) Eyikeyi ninu awọn ẹsẹ Bibeli wọnyi tabi awọn ẹsẹ miiran ko sọ pe o lodi lati lo ọna atọwọda lati fi ṣalekun ìrísí ara ẹni. Sibẹ, itan Jesebẹli fihan pe oun tọ́ tiroo ti o pọ si oju tobẹẹ ti yoo fi ṣee ri lati okeere, koda fun Jehu ti o wa ni ode aafin. Ki ni ẹkọ ti a ri kọ? Maṣe lo eroja ìṣaralọ́sọ̀ọ́ ti o pọ ju, ni ọna aṣeregee kan.b
Dajudaju, ko si obinrin kan ti nlo ohun ọṣọ iyebiye tabi eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ ti yoo sọ pe awọn ọna ti oun ngba ṣe é ati iye iwọn ti oun nlo ko bojumu. Sibẹ, ko si tabi ṣugbọn pe nitori imọlara adara ẹni loju tabi labẹ agbara idari ipolowo akoninifa, obinrin kan le mu iwa aṣa lilo eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ lapọju dagba. Ìrísí ti o ma ngbeyọ le wá mọ́ ọn lara debi pe oun yoo kuna lati mọ pe o lodi si “iwọntun wọnsi ati iyekooro ero inu” ti ọpọ julọ awọn obinrin Kristian.—Wo Jakọbu 1:23, 24.
Ki a gba pe, awọn ohun ti a nifẹẹ si ko dọgba; awọn obinrin kan nlo eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ tabi ohun ọsọ oniyebiye diẹ tabi ki wọn má tilẹ lò rara, awọn miiran si nlo pupọ. Nitori naa o ba ọgbọn mu lati maṣe ṣe idajọ ẹni ti nlo iwọn eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ tabi ohun ọṣọ oniyebiye ti o yatọ. Koko abajọ miiran ni aṣa adugbo. Nitori pe a tẹwọgba awọn aṣa kan ni ilẹ miiran (tabi gbajumọ ni awọn igba atijọ) ko tumọ si pe wọn bojumu ni adugbo lonii.
Ọlọgbọn obinrin Kristian kan yoo maa ṣagbeyẹwo imura rẹ lati igba de igba, ni bibi ara rẹ leere tootọ tootọ pe: ‘Njẹ mo ha maa nwọ ohun ọsọ oniyebiye tabi eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ ti o pọju (tabi tànyòyò ju) ni ọpọ igba ju pupọ awọn Kristian ni adugbo mi bi? Mo ha nmu imura mi ba ti awọn sànmọ̀rí onifaaji ajọra ẹni loju tabi awọn gbajumọ oṣere asan mu, tabi emi ha njẹ ki imọran ti o wa ninu 1 Timoti 2:9 ati 1 Peteru 3:3, 4 dari mi ni pataki bi? Bẹẹni, njẹ imura mi ha mọniwọn niti gidi, ti o si nfi ogidi ọwọ han fun awọn ero ati imọlara awọn ẹlomiran bi?’—Owe 31:30.
Awọn obinrin ti wọn ni ọkọ Kristian le beere lọwọ wọn fun ọrọ akiyesi ati imọran. Pẹlupẹlu, nigba ti a ba beere pẹlu otitọ-inu imọran ti o ranni lọwọ ni a le ri gba lati ọdọ awọn arabinrin miiran. Ṣugbọn dipo yiyiju si ọrẹ kan ti o fẹran iru ohun kan naa, o le dara ju lati ba awọn arabinrin agbalagba ti a bọwọ fun iwadeedee ati ọgbọn wọn sọrọ. (Fiwe 1 Ọba 12:6-8.) Bibeli sọ pe ki awọn agba obinrin ọlọ́wọ̀ maa “tọ awọn ọmobinrin . . . lati jẹ alairekọja, mimọ . . . , ki ọrọ Ọlọrun ki o maṣe di isọrọ odi si.” (Titu 2:2-5) Ko si Kristian ti o dagba denu kan ti yoo fẹ ki aisi iwọntunwọnsi ninu ilo ohun ọṣọ iyebiye tabi eroja iṣara lọṣọ rẹ mu ki Ọrọ Ọlọrun tabi awọn eniyan rẹ “di isọrọ odi si.”
Akọsilẹ Bibeli nipa Tamari fihan pe imura obinrin kan le fi í hàn yàtọ̀, ti o si ngbe ihin iṣẹ alagbara jade. (Jẹnesisi 38:14, 15) Iru ihin iṣẹ wo ni aṣa irun ati àwọ̀ irun (bi a ba pa á laro), tabi ilo awọn ohun ọsọ ati awọn ohun ìṣaralóge ti Kristian obinrin kan ngbeyọ jade? O ha jẹ pe: Ẹni yii jẹ iranṣẹ Ọlọrun oniwọntunwọnsi, ti o wàdeede, ti o si mọ tonitoni?
Ẹni kan ti o ri awọn Kristian ninu iṣẹ-isin papa, tabi ti o lọ si awọn ipade wa, ni a gbọdọ mú ori rẹ wu lọna rere. Awọn ti nṣakiyesi wa ni a saba maa ńwú lori ni gbogbogboo. Ọpọjulọ awọn obinrin Kristian ni ko fun awọn ará ita ni idi lati pari ero si pe wọn mura wúruwùru ni ọwọ́ kan, tabi pe wọn jẹ aláṣerégèé ninu imura tabi ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́ wọn ni ọwọ keji. Kaka bẹẹ, wọn nmura ni ọna “ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ iwa bi Ọlọrun.”—1 Timoti 2:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni ọrundun kẹta Sanmani Tiwa., Tertullian jẹwọ pe awọn obinrin “ti wọn fi awọn eroja elegboogi pa awọ ara, kun ẹrẹkẹ wọn pẹlu ohun iṣara lóge pupa, mu oju wọn hàn ketekete pẹlu tiróò dẹṣẹ, si I.” O tun ṣariwisi awọn ti wọn pa irun wọn láró. Ni ṣiṣi awọn ọrọ Jesu ti o wa ninu Matiu 5:36 lo, Tertullian fẹsun kan pe: “Wọn tako Oluwa! ‘Kiyesii!’ wọn sọ pe, ‘dipo iru funfun tabi dudu, awa ṣe [irun wa] ni alawọ ìyeyè.’” O fikun un pe: “Iwọ tilẹ le ri awọn eniyan ti oju nti nitori pe wọn darugbo, ti wọn si gbiyanju lati yi irun funfun wọn pada si dudu.” Ero ara-ẹni ti Tertullian niyẹn. Ṣugbọn nṣe ni oun nlọ́ awọn ọran po, nitori gbogbo ariyanjiyan rẹ ni a gbé ka ori oju iwoye rẹ pe awọn obinrin ni wọn ṣokunfa idalẹbi iran eniyan, nitori naa wọn gbọdọ ‘maa rin kiri bii Efa, ki wọn maa ṣọfọ ki wọn si maa ronupiwada’ nitori ‘itiju ẹṣẹ akọkọ.’ Bibeli ko sọ iru awọn nnkan bẹẹ; Ọlọrun ka ipo ẹṣẹ araye si Adamu lọrun.—Roomu 5:12-14; 1 Timoti 2:13, 14.
b Ni aipẹ yii ile iṣẹ eto irohin ni United States gbe iwa ibajẹ oniwaasu ori tẹlifisọn kan jade kedere, nigba ti iyawo rẹ ti o jẹ amugba lẹgbẹ rẹ gba iru afiyesi kan naa. Gẹgẹ bi irohin ṣe wi, a tọ ọ dagba lati gbagbọ pe lilo “eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ ati wiwo sinima” jẹ ẹṣẹ, sibẹ lẹhin naa oun yi ero rẹ pada ti a si wa mọ ọn si alaṣeju ni lilo “eroja ìṣaralọ́ṣòọ́ lapọju ti o dabi ère gbigbẹ.”
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Awọn awari iwalẹpitan lati Aarin Ila-oorun: Apoti ohun ìṣaralóge ti a fi ehin erin ṣe, dígí, ati awọn ilẹkẹ oniwura, ati okuta oniwura pupa kan
[Credit Line]
Mẹtẹẹta: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.