Ìgbàgbọ́ Ń jẹ́ Kí A Mú Sùúrù, Kí A Sì Kún fún Àdúrà
“Ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.”—JÁKỌ́BÙ 5:8.
1. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ronú lórí Jákọ́bù 5:7, 8?
“WÍWÀNÍHÌN-ÍN” Jésù Kristi tí a ti dúró dè tipẹ́tipẹ́ ti di òkodoro òtítọ́ nísinsìnyí. (Mátíù 24:3-14) Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi ní ìdí láti ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn sọ pé: “Ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa. Wò ó! Àgbẹ̀ a máa dúró de èso ṣíṣeyebíye ilẹ̀ ayé, ní mímú sùúrù lórí rẹ̀ títí yóò fi rí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kúrò. Ẹ̀yin pẹ̀lú ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.”—Jákọ́bù 5:7, 8.
2. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ àwọn tí Jákọ́bù kọ̀wé sí?
2 Àwọn tí Jákọ́bù kọ lẹ́tà rẹ̀ tí ó ní ìmísí sí ní láti mú sùúrù, kí wọ́n sì yanjú onírúurú àwọn ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ń hùwà lọ́nà tí ó ta ko ohun tí a ń retí lọ́dọ̀ àwọn tí ó sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, ó pọn dandan láti ṣe nǹkan kan nípa àwọn ìfẹ́ ọkàn pàtó kan tí ó ti dàgbà nínú àwọn ọkàn àyà kan. Ó yẹ kí a dá ìtòròmini pa dà sáàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọnnì. Wọ́n nílò ìmọ̀ràn lórí mímú sùúrù àti kíkún fún àdúrà pẹ̀lú. Bí a ti ń gbé ohun tí Jákọ́bù sọ fún wọn yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ kí a wo bí a ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa.
Ìfẹ́ Ọkàn Àìtọ́ Ń Pani Run
3. Kí ni àwọn ohun tí ó fa gbọ́nmisi-omi-ò-to nínú ìjọ, kí sì ni a lè rí kọ́ nínú èyí?
3 Nígbà náà lọ́hùn-ún, kò sí àlàáfíà láàárín àwọn kan tí wọ́n sọ pé Kristẹni ni àwọn, ìfẹ́ ọkàn àìtọ́ sì ni ohun tí ó fa ipò yí. (Jákọ́bù 4:1-3) Asọ̀ ń dá rúgúdù sílẹ̀, àwọn kan sì ń dá arákùnrin wọn lẹ́jọ́ lọ́nà àìnífẹ̀ẹ́. Èyí ń ṣẹlẹ̀ nítorí pé ìfàsí ọkàn fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń bá ìforígbárí nìṣó láàárín àwọn ẹ̀yà ara wọn. Àwa fúnra wa lè ní láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ láti dènà ìfàsí ọkàn ti ẹran ara fún ipò ọlá, agbára, àti àwọn ohun ìní kí a má baà ṣe ohunkóhun tí yóò dabarú àlàáfíà ìjọ. (Róòmù 7:21-25; Pétérù Kíní 2:11) Láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kan, ojúkòkòrò ti gbèrú dórí níní ẹ̀mí ìkórìíra tí ń súnni pànìyàn. Níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti mú ìfẹ́ ọkàn àìtọ́ wọn ṣẹ, wọ́n ń bá ìjàkadì wọn nìṣó láti lé góńgó wọn bá. Bí a bá ní irú ìfẹ́ ọkàn àìtọ́ bẹ́ẹ̀, a lè béèrè ṣùgbọ́n a kì yóò rí gbà, níwọ̀n bí Ọlọ́run wa tí ó jẹ́ mímọ́ kì í ti í dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀.—Ẹkún Jeremáyà 3:44; Jòhánù Kẹta 9, 10.
4. Èé ṣe tí Jákọ́bù fi pe àwọn kan ní “panṣágà obìnrin,” báwo sì ni ó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa lórí wa?
4 Ẹ̀mí ayé, ìlara, àti ìgbéraga wà láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kan. (Jákọ́bù 4:4-6) Jákọ́bù pe àwọn kan ní “panṣágà obìnrin” nítorí pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi panṣágà nípa tẹ̀mí. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 16:15-19, 25-45) Dájúdájú, a kò fẹ́ di ẹni ayé nínú ẹ̀mí ìrònú, ọ̀rọ̀ sísọ, àti nínú ìwà, nítorí pé ìyẹn yóò sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn wá pé “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” jẹ́ apá kan ìrònú búburú, tàbí “ẹ̀mí,” tí ó wà nínú ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Númérì 16:1-3; Orin Dáfídì 106:16, 17; Oníwàásù 4:4) Nítorí náà, bí a bá wá rí i pé ó yẹ kí a bá ìlara, ìgbéraga, tàbí àwọn ìrònú búburú mìíràn jà, ẹ jẹ́ kí a wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ipá yẹn, tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ń pèsè, lágbára ju “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara.” Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Jèhófà ń kọ ojú ìjà sí agbéraga, òun yóò fún wa ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ bí a bá bá àwọn ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ jà.
5. Láti gbádùn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí ni àwọn ohun àbéèrè fún tí a gbọ́dọ̀ kúnjú?
5 Báwo ni a ṣe lè rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà? (Jákọ́bù 4:7-10) Láti gbádùn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí i, kí a tẹ́wọ́ gba àwọn ìpèsè rẹ̀, kí a sì gba ohun yòó wù tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 8:28) A tún gbọ́dọ̀ “kọ ojú ìjà sí,” tàbí ‘dúró lòdì sí,’ Èṣù. Òun yóò ‘sá kúrò lọ́dọ̀ wa’ bí a bá ń bá a nìṣó láti dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí alátìlẹ́yìn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà. Jésù yóò ràn wá lọ́wọ́, ẹni tí ó ń ká àwọn ẹni ibi inú ayé lọ́wọ́ kò tí ohunkóhun kò fi lè ṣe ìpalára tí ó wà pẹ́ títí sí wa. Má sì ṣe gbàgbé èyí láé pé: Nípa àdúrà, ìgbọ́ràn, àti ìgbàgbọ́, a ń fà mọ́ Ọlọ́run, ó sì ń fi hàn pé òun wà nítòsí wa.—Kíróníkà Kejì 15:2.
6. Èé ṣe tí Jákọ́bù fi pe àwọn Kristẹni kan ní “ẹlẹ́ṣẹ̀”?
6 Èé ṣe tí Jákọ́bù fi lo ọ̀rọ̀ náà “ẹlẹ́ṣẹ̀” fún àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run? Nítorí pé wọ́n jẹ̀bi “ogun” àti ẹ̀mí ìkórìíra tí ń súnni pànìyàn—àwọn ìṣarasíhùwà tí kò yẹ Kristẹni. (Títù 3:3) “Ọwọ́” wọn kún fún iṣẹ́ búburú, tí ó béèrè wíwẹ̀mọ́. Ó tún yẹ kí wọ́n wẹ “ọkàn àyà” wọn, orísun ìsúnniṣe, mọ́ gaara. (Mátíù 15:18, 19) Àwọn “aláìnípinnu” wọ̀nyẹn ń ṣèhín ṣọ̀hún ní ti ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé. Níwọ̀n bí a ti fi àpẹẹrẹ búburú wọn kìlọ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò nígbà gbogbo kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ má baà ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.—Róòmù 7:18-20.
7. Èé ṣe tí Jákọ́bù fi sọ fún àwọn kan láti “ṣọ̀fọ̀ kí wọ́n sì sunkún”?
7 Jákọ́bù sọ fún àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti ‘bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíṣẹ̀ẹ́ kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ kí wọ́n sì sunkún.’ Bí wọ́n bá fi ìbànújẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run hàn, yóò jẹ́ ẹ̀rí ìrònúpìwàdà. (Kọ́ríńtì Kejì 7:10, 11) Lónìí, àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ ń wá ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé. Bí ẹnì kankan nínú wa bá ń lépa irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀, kò ha yẹ kí a ṣọ̀fọ̀ lórí ipò àìlera tẹ̀mí tí a wà, kí a sì gbé ìgbésẹ̀ kíákíá láti mú ọ̀ràn tọ́? Ṣíṣe àwọn àtúnṣe tí ó pọn dandan àti rírí ìdáríjì Ọlọ́run gbà yóò mú kí a ní ìmọ̀lára aláyọ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́ àti ìfojúsọ́nà onídùnnú fún ìyè ayérayé.—Orin Dáfídì 51:10-17; Jòhánù Kíní 2:15-17.
Ẹ Má Ṣe Dá Ara Yín Lẹ́jọ́
8, 9. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a sọ̀rọ̀ lòdì sí tàbí kí a dá ẹnì kíní kejì lẹ́jọ́?
8 Ẹ̀ṣẹ̀ ni láti sọ̀rọ̀ lòdì sí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni. (Jákọ́bù 4:11, 12) Síbẹ̀, àwọn kan ń ṣe lámèyítọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, bóyá nítorí ẹ̀mí ìrònú jíjẹ́ olódodo lójú ara wọn tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ gbé ara wọn ga nípa títẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlòmíràn. (Orin Dáfídì 50:20; Òwe 3:29) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí ‘sọ̀rọ̀ lòdì sí’ tọ́ka sí ẹ̀tanú, ó sì dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ẹ̀sùn tí a fẹ̀ lójú tàbí ẹ̀sùn èké. Èyí jẹ́ dídá arákùnrin lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò bára dé. Báwo ni èyí ṣe jẹ́ ‘sísọ̀rọ̀ lòdì sí òfin Ọlọ́run àti dídá a lẹ́jọ́’? Tóò, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ‘fi ọgbọ́n féfé pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan’ wọ́n sì ń fi ọ̀pá ìdiwọ̀n tiwọn dájọ́. (Máàkù 7:1-13) Lọ́nà tí ó jọra, bí a bá dá arákùnrin kan lẹ́bi tí ó sì jẹ́ pé Jèhófà kì yóò dá a lẹ́bi, a kò ha ti ‘ń dá òfin Ọlọ́run lẹ́jọ́’ tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń dọ́gbọ́n sọ pé òfin náà kò pegedé bí? Bí a bá sì ń ṣe lámèyítọ́ arákùnrin wa lọ́nà tí kò tọ́, a kì yóò mú òfin ìfẹ́ ṣẹ.—Róòmù 13:8-10.
9 Ẹ jẹ́ kí a rántí èyí pé: “Ẹnì kan ni ó wà tí ó jẹ́ afúnnilófin àti onídàájọ́”—Jèhófà. ‘Pípé ni òfin’ rẹ̀, kò sì lábùkù. (Orin Dáfídì 19:7; Aísáyà 33:22) Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó ní ẹ̀tọ́ láti fi ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ìlànà lélẹ̀ fún ìgbàlà. (Lúùkù 12:5) Nítorí náà, Jákọ́bù béèrè pé: “Ta ni ọ́ tí o fi ní láti máa ṣèdájọ́ aládùúgbò rẹ?” Kì í ṣe ẹ̀tọ́ wa láti máa dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́, kí a sì dá wọn lẹ́bi. (Mátíù 7:1-5; Róòmù 14:4, 10) Ríronú lórí ipò ọba aláṣẹ àti àìṣègbè Ọlọ́run àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tiwa yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún fífi jíjẹ́ olódodo lójú ara wa dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́.
Yẹra fún Dídára-Ẹni-Lójú Lọ́nà Ìṣògo
10. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a máa ronú nípa Jèhófà nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́?
10 Ó yẹ kí a máa ronú nípa Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo. (Jákọ́bù 4:13-17) Láìka Ọlọ́run sí, àwọn tí ó dá ara wọn lójú sọ pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la àwa yóò lọ sí ìlú ńlá kan, a óò lo ọdún kan níbẹ̀, àwa yóò ṣòwò, a óò sì jèrè.’ Bí a ‘bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara wa ṣùgbọ́n tí a kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,’ ẹ̀mí wa lè pin lọ́la, kí a má sì ní àǹfààní láti sin Jèhófà. (Lúùkù 12:16-21) Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti sọ, a dà bí ìkùukùu òwúrọ̀ “tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.” (Kíróníkà Kíní 29:15) Kìkì nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ni a fi lè nírètí fún ìdùnnú tí ó wà títí àti ìyè àìnípẹ̀kun.
11. Kí ni ó túmọ̀ sí láti sọ pé, “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inú Jèhófà”?
11 Dípò kí a máa fi ìfọ́nnu ṣàìka Ọlọ́run sí, ó yẹ kí a ní ẹ̀mí ìrònú yìí pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inú Jèhófà, àwa yóò wà láàyè a óò sì ṣe èyí tàbí èyíinì pẹ̀lú.” Sísọ pé, “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inú Jèhófà” fi hàn pé a ń gbìyànjú láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Ó lè pọn dandan láti ṣòwò láti gbọ́ bùkátà ìdílé wa, láti rìnrìn àjò nínú iṣẹ́ Ìjọba náà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n kí a má ṣe fọ́nnu. “Irúfẹ́ . . . ìyangàn bẹ́ẹ̀ burú” nítorí pé kò ka gbígbáralé Ọlọ́run sí.—Orin Dáfídì 37:5; Òwe 21:4; Jeremáyà 9:23, 24.
12. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Jákọ́bù 4:17 túmọ̀ sí?
12 Ó hàn gbangba pé láti parí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa dídá ara ẹni lójú àti ṣíṣògo, Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́ síbẹ̀ tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé Ọlọ́run ni òun gbára lé. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, “ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” Dájúdájú, ìlànà kan náà ni ó kan kíkùnà lọ́nàkọnà láti ṣe ohun tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa.—Lúùkù 12:47, 48.
Ìkìlọ̀ Nípa Ọrọ̀
13. Kí ni Jákọ́bù sọ nípa àwọn tí ń ṣi ọrọ̀ wọn lò?
13 Nítorí pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mélòó kan ti di onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí tí wọ́n ń kan sáárá sí àwọn ọlọ́rọ̀, Jákọ́bù sọ̀rọ̀ líle nípa àwọn ọlọ́rọ̀ kan. (Jákọ́bù 5:1-6) Àwọn ènìyàn ayé tí ń lo ọrọ̀ wọn lọ́nà tí kò tọ́ yóò ‘sunkún, wọn yóò hu nítorí ìṣẹ́ tí ń bọ̀ wá sórí wọn’ nígbà tí Ọlọ́run yóò san wọ́n lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. Ní ayé ìgbàanì, ọrọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní pàtàkì jẹ́ irú àwọn nǹkan bí aṣọ, ọkà, àti wáìnì. (Jóẹ́lì 2:19; Mátíù 11:8) Mélòó kan nínú àwọn wọ̀nyí lè jẹrà tàbí “di èyí tí kòkòrò òólá ti lá,” ṣùgbọ́n Jákọ́bù ń tẹnu mọ́ àìjámọ́-nǹkan-kan ọrọ̀, kì í ṣe bíbàjẹ́ tí ó lè bà jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wúrà àti fàdákà kì í dípẹtà, bí a bá kó wọn pa mọ́, wọn yóò di aláìníyelórí bí àwọn nǹkan tí ó ti dípẹtà. “Ìpẹtà” fi hàn pé a kò lo ọrọ̀ nípa ti ara lọ́nà rere. Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa rántí pé “ohun kan tí ó dà bí iná” ni ohun tí àwọn tí ó gbọ́kàn lé ohun ìní ti ara “ti tò jọ pa mọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” nígbà tí ìbínú Ọlọ́run yóò dé sórí wọn. Níwọ̀n bí a ti ń gbé ní “ìgbà ìkẹyìn,” irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ní ìtumọ̀ àkànṣe fún wa.—Dáníẹ́lì 12:4; Róòmù 2:5.
14. Báwo ni àwọn ọlọ́rọ̀ ṣe sábà máa ń hùwà, kí ni ó sì yẹ kí a ṣe nípa ìyẹn?
14 Àwọn ọlọ́rọ̀ sábà máa ń rẹ́ àwọn olùkórè wọn jẹ, àwọn tí owó ọ̀yà wọn tí a kò san ‘ń ké jáde’ fún ẹ̀san. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 4:9, 10.) Àwọn ọlọ́rọ̀ inú ayé “ti gbé nínú fàájì.” Ní fífi adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kẹ́ra bà jẹ́, wọ́n mú ọkàn àyà sísanra, tí ó ti yigbì dàgbà, wọn yóò sì máa ṣe èyí síbẹ̀ ní “ọjọ́” tí a yàn fún fífikú pa wọ́n. Wọ́n ‘ń dáni lẹ́bi tí wọ́n sì ń ṣìkà pa olódodo.’ Jákọ́bù béèrè pé: “Òun kò ha ń ta kò yín bí?” Ṣùgbọ́n ìtumọ̀ míràn sọ pé, “olódodo; òun kì í ta kò yín.” Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gbọ́dọ̀ ṣojúsàájú sí àwọn ọlọ́rọ̀. A gbọ́dọ̀ fi ire tẹ̀mí ṣáájú nínú ìgbésí ayé.—Mátíù 6:25-33.
Ìgbàgbọ́ Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Mú Sùúrù
15, 16. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ láti mú sùúrù?
15 Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́rọ̀ inú ayé tí ń ni àwọn ènìyàn lára, Jákọ́bù wá fún àwọn Kristẹni tí a ń ni lára níṣìírí láti mú sùúrù. (Jákọ́bù 5:7, 8) Bí àwọn onígbàgbọ́ bá fi sùúrù fàyà rán ìṣòro wọn, a óò san wọ́n lẹ́san fún ìṣòtítọ́ nígbà wíwàníhìn-ín Kristi, nígbà tí ìdájọ́ yóò wá sórí àwọn tí ń ni wọ́n lára. (Mátíù 24:37-41) Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn ní láti dà bí àgbẹ̀ tí ń fi sùúrù dúró de òjò àkọ́rọ̀ ìgbà ìwọ́wé, nígbà tí ó lè gbin nǹkan, àti òjò àrọ̀kúrò ìgbà ìrúwé tí ń mú èso jáde. (Jóẹ́lì 2:23) Ó yẹ kí àwa pẹ̀lú mú sùúrù, kí a sì fìdí ọkàn àyà wa múlẹ̀ gbọn-in, pàápàá jù lọ níwọ̀n bí “wíwàníhìn-ín Olúwa” Jésù Kristi ti dé!
16 Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ní sùúrù? (Jákọ́bù 5:9-12) Sùúrù ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe kérora tàbí mí ìmí ẹ̀dùn nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá mú wa bínú. Bí a bá fi ẹ̀mí tí ń pani lára ‘mí ìmí ẹ̀dùn lòdì sí ara wa lẹ́nì kíní kejì,’ Jésù Kristi tí í ṣe Adájọ́ yóò dá wa lẹ́bi. (Jòhánù 5:22) Níwọ̀n bí “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, tí ó sì “ń dúró níwájú àwọn ilẹ̀kùn,” ẹ jẹ́ kí a gbé àlàáfíà lárugẹ nípa mímú sùúrù pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa, tí ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìdánwò ìgbàgbọ́. A ń fún ìgbàgbọ́ tiwa lókun nígbà tí a bá rántí pé Ọlọ́run san Jóòbù lẹ́san nítorí pé òun fi sùúrù forí ti àwọn àdánwò rẹ̀. (Jóòbù 42:10-17) Bí a bá lo ìgbàgbọ́ tí a sì mú sùúrù, a óò rí i pé “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.”—Míkà 7:18, 19.
17. Èé ṣe tí Jákọ́bù fi sọ pé, “Ẹ dẹ́kun bíbúra”?
17 Bí a kò bá mú sùúrù, a lè ṣi ahọ́n wa lò nígbà tí a bá wà lábẹ́ másùnmáwo. Fún àpẹẹrẹ, a lè fi ìwàǹwára búra. Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun bíbúra,” ní kíkìlọ̀ nípa ìbúra ṣeréṣeré. Fífìgbà gbogbo máa fi ìbúra fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ tún dà bí àgàbàgebè. Nípa báyìí, ó yẹ kí a wulẹ̀ sọ òtítọ́, ní jíjẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni wa túmọ̀ sí bẹ́ẹ̀ ni, àti bẹ́ẹ̀ kọ́ wa, bẹ́ẹ̀ kọ́. (Mátíù 5:33-37) Dájúdájú, Jákọ́bù kò sọ pé ó burú láti búra láti sọ òtítọ́ ní kóòtù.
Ìgbàgbọ́ àti Àwọn Àdúrà Wa
18. Lábẹ́ àwọn àyíká ipò wo ni a ti gbọ́dọ̀ “máa bá a lọ ní gbígbàdúrà” kí a sì máa fi “àwọn sáàmù ṣe orin kọ”?
18 Àdúrà gbọ́dọ̀ kó ipa ṣíṣe kókó nínú ìgbésí ayé wa bí a óò bá ṣàkóso ahọ́n wa, bí a óò bá mú sùúrù, bí a óò bá sì pa ìgbàgbọ́ tí ó yè kooro mọ́ nínú Ọlọ́run. (Jákọ́bù 5:13-20) Pàápàá jù lọ nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò ó yẹ kí a “máa bá a lọ ní gbígbàdúrà.” Bí ara wa bá yá gágá, ẹ jẹ́ kí a máa fi “àwọn sáàmù ṣe orin kọ,” bí Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ṣe nígbà tí ó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀. (Máàkù 14:26, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé) Nígbà míràn, a lè kún fún ìmoore púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ sí Ọlọ́run tí a óò fi máa kọrin ìyìn nínú ọkàn àyà wa pàápàá. (Kọ́ríńtì Kíní 14:15; Éfésù 5:19) Ẹ sì wo bí ó ṣe jẹ́ ohun ìdùnnú tó láti fi orin gbé Jèhófà ga ní àwọn ìpàdé Kristẹni!
19. Kí ni ó yẹ kí a ṣe bí a bá di aláìsàn nípa tẹ̀mí, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí a gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀?
19 A lè máà fẹ́ kọrin bí a bá ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí, bóyá nítorí ìwà àìtọ́ kan tàbí ìkùnà láti jẹun déédéé lórí tábìlì Jèhófà. Bí a bá wà nínú ipò yẹn, ẹ jẹ́ kí a fi ìrẹ̀lẹ̀ pe àwọn alàgbà kí wọ́n lè ‘gbàdúrà lé wa lórí.’ (Òwe 15:29) Wọn yóò tún ‘fi òróró pa wá ní orúkọ Jèhófà.’ Gẹ́gẹ́ bí òróró atunilára lórí egbò, àwọn ọ̀rọ̀ atunilára wọn àti ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yóò ṣèrànwọ́ láti mú ìsoríkọ́, iyè méjì, ìbẹ̀rù dín kù. ‘Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò mú wa lára dá’ bí a bá fi ìgbàgbọ́ tiwa tì í lẹ́yìn. Bí àwọn alàgbà bá rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ni ó fa àìsàn wa nípa tẹ̀mí, wọn yóò fi inú rere mú kí àṣìṣe wa ṣe kedere sí wa, wọn yóò sì gbìyànjú láti ràn wá lọ́wọ́. (Orin Dáfídì 141:5) Bí a bá sì fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn, a lè ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà wọn, yóò sì dárí jì wá.
20. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí a sì gbàdúrà fún ẹnì kíní kejì?
20 ‘Jíjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní gbangba fún ara wa lẹ́nì kíní kejì’ yẹ kí ó ṣiṣẹ́ bí ohun tí yóò ká wa lọ́wọ́ kò láti máa dẹ́ṣẹ̀ lọ. Ó yẹ kí ó fún ẹ̀mí ìyọ́nú fún tọ̀túntòsì níṣìírí, ànímọ́ tí yóò sún wa láti máa ‘gbàdúrà fún ara wa lẹ́nì kíní kejì.’ A lè ní ìgbàgbọ́ pé èyí yóò ṣàǹfààní nítorí pé àdúrà “olódodo”—ẹnì kan tí ń lo ìgbàgbọ́, tí Ọlọ́run sì wò bí adúróṣánṣán—ń ṣàṣeparí ohun púpọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. (Pétérù Kíní 3:12) Wòlíì Èlíjà ní àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó bíi tiwa, ṣùgbọ́n àwọn àdúrà rẹ̀ gbéṣẹ́. Ó gbàdúrà, òjò kò sì rọ̀ fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Nígbà tí ó gbàdúrà lẹ́ẹ̀kan sí i, òjò rọ̀.—Ọba Kìíní 17:1; 18:1, 42-45; Lúùkù 4:25.
21. Kí ni a lè ṣe bí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan bá di ẹni tí a ‘ṣì lọ́nà kúrò nínú òtítọ́’?
21 Bí mẹ́ńbà ìjọ kan bá di ẹni tí a ‘ṣì lọ́nà kúrò nínú òtítọ́,’ tí ó ń yapa kúrò nínú ẹ̀kọ́ àti ìwà títọ́ ńkọ́? Ó lè ṣeé ṣe fún wa láti yí i pa dà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ràn Bíbélì, àdúrà, àti àwọn ìrànwọ́ mìíràn. Bí a bá ṣàṣeyọrí, èyí yóò pa á mọ́ sábẹ́ ìràpadà Kristi, yóò sì gbà á là kúrò nínú ikú tẹ̀mí àti ìdálẹ́bi sí ìparun. Nípa ríran ẹni tí ó ti ṣìnà náà lọ́wọ́, a ń bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a bá wí náà bá yí pa dà kúrò nínú ipa ọ̀nà àìtọ́ rẹ̀, tí ó ronú pìwà dà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àforíjì, a óò láyọ̀ pé a ṣiṣẹ́ síhà bíbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.—Orin Dáfídì 32:1, 2; Júúdà 22, 23.
Ohun Tí Ó Wà fún Gbogbo Wa
22, 23. Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù nípa lórí wa?
22 Ní kedere, lẹ́tà Jákọ́bù ní ohun kan tí ó ṣàǹfààní fún gbogbo wa. Ó fi bí a ṣe lè kojú àwọn àdánwò hàn wá, ó gbà wá nímọ̀ràn nípa yíyẹra fún ìṣègbè, ó sì rọ̀ wá láti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ rere. Jákọ́bù rọ̀ wá láti ṣàkóso ahọ́n wa, láti dènà ipa tí ayé lè ní lórí ẹni, kí a sì gbé àlàáfíà lárugẹ. Ó yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí a jẹ́ onísùúrù, kí a sì kún fún àdúrà.
23 Lóòótọ́, àwọn ẹni àmì òróró Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni Jákọ́bù fi lẹ́tà rẹ̀ ránṣẹ́ sí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ kí gbogbo wa jẹ́ kí ìmọ̀ràn rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wa. Àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù lè fún ìgbàgbọ́ tí ń sún wa láti gbé ìgbésẹ̀ onípinnu nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lókun. Lẹ́tà tí a mí sí láti ọ̀run yìí sì ń gbé ìgbàgbọ́ tí ń wà pẹ́ títí ró, èyí tí ó mú kí a jẹ́ onísùúrù, tí ń kún fún àdúrà, Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà lónìí, nígbà “wíwàníhìn-ín Olúwa” Jésù Kristi.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí ó fi pọn dandan fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mélòó kan láti yí ẹ̀mí ìrònú àti ìwà wọn pa dà?
◻ Ìkìlọ̀ wo ni Jákọ́bù fún àwọn ọlọ́rọ̀?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a mú sùúrù?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a máa gbàdúrà déédéé?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ó yẹ kí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mélòó kan túbọ̀ jẹ́ onísùúrù pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ó yẹ kí àwọn Kristẹni mú sùúrù, nífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì kún fún àdúrà