ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 2/1 ojú ìwé 17-21
  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ronú Nípa Sùúrù Jèhófà
  • Ronú Nípa Sùúrù Àwọn Wòlíì
  • “Ìfaradà Jóòbù”
  • “Ọjọ́ Jèhófà Yóò Dé”
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Sùúrù La Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 2/1 ojú ìwé 17-21

Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà

“Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, . . . ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù.”—2 Pétérù 3:9.

1. Ẹ̀bùn tí kò láfiwé wo ni Jèhófà ti ṣe tán láti fún ọmọ aráyé?

JÈHÓFÀ fẹ́ láti fún wa ní ohun kan tí ẹnikẹ́ni mìíràn ò lè fún wa. Ohun tó fani mọ́ra gan-an tó sì ṣeyebíye ni, síbẹ̀ kò ṣeé fowó rà kì í sì í ṣe ohun téèyàn ń kà sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. Ohun tó fẹ́ fún wa ni ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ìyẹn ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 3:16) Ìyẹn á mà múnú wa dùn gan-an o! Kò ní sáwọn nǹkan tó ń fa ìbànújẹ́ mọ́, ìyẹn àwọn nǹkan bíi gbọ́nmi-si omi-ò-to, ìwà ipá, àìríjẹ-àìrímu, ìwà ọ̀daràn, àìsàn, àti ikú pàápàá. Àwọn èèyàn yóò wà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tí kò lẹ́gbẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Ìjọba Ọlọ́run. À ń retí Párádísè yẹn lójú méjèèjì!—Aísáyà 9:6, 7; Ìṣípayá 21:4, 5.

2. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi tíì pa ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì yìí run?

2 Jèhófà pàápàá ń dúró de ìgbà tóun máa sọ ayé di Párádísè. Ó ṣe tán, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo ni. (Sáàmù 33:5) Inú rẹ̀ kì í dùn tó bá ń wo àwọn èèyàn tó ń tàpá sáwọn ìlànà òdodo rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń fojú di àṣẹ rẹ̀ tí wọ́n sì tún ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìdí pàtàkì kan wà tí kò tíì jẹ́ kó mú ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì yìí kúrò. Àwọn ìdí náà ní í ṣe pẹ̀lú bóyá Jèhófà ni ọba aláṣẹ tó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso tàbí kì í ṣòun. Láti yanjú ọ̀ràn yìí, Jèhófà fi ànímọ́ pàtàkì kan tó fani mọ́ra hàn. Ànímọ́ náà ni sùúrù, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní lóde òní.

3. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti ti Hébérù tá a tú sí “sùúrù” nínú Bíbélì? (b) Àwọn ìbéèrè wò la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

3 Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì kan wà tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “sùúrù” nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ohun tó túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni “kéèyàn rọ́kú,” ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sábà máa ń tú u sí “ìpamọ́ra,” ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni wọ́n sì tú u sí “mímú sùúrù.” Ìtumọ̀ abẹ́nú tí “sùúrù” ní nínú èdè Gíríìkì àti èdè Hébérù ni kéèyàn lè mú nǹkan mọ́ra, kó jẹ́ ẹni tí kì í yára bínú. Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú sùúrù Jèhófà? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú sùúrù àti ìfaradà Jèhófà àti tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́? Báwo la ṣe mọ̀ pé sùúrù Jèhófà kì í ṣe èyí tí yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí gbére? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

Ronú Nípa Sùúrù Jèhófà

4. Kí ni àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa sùúrù Jèhófà?

4 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa sùúrù Jèhófà, ó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan. Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:8, 9) Jọ̀wọ́ kíyè sí kókó méjì tí ibí yìí mẹ́nu kàn, èyí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye sùúrù Jèhófà.

5. Báwo ni ojú tí Jèhófà fi ń wo àkókò ṣe ń nípa lórí àwọn ohun tó ń ṣe?

5 Kókó àkọ́kọ́ ni pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àkókò yàtọ̀ sí ojú táwa èèyàn fi ń wò ó. Bí ọjọ́ kan péré ni ẹgbẹ̀rún ọdún ṣe rí lójú Jèhófà, nítorí pé òun wà láàyè títí láé. Kò sí ọ̀ràn pé àkókò ò sí fún un tàbí kó máa kánjú nítorí pé àkókò ń lọ, síbẹ̀ kò fi ohun tó fẹ́ ṣe láti yanjú ìṣòro ọmọ aráyé falẹ̀. Nítorí pé ọgbọ́n Jèhófà kò lópin, ó mọ ìgbà tó dára jù lọ láti ṣe ohun tó máa ṣe gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn láǹfààní. Ó sì ń fi sùúrù dúró de ìgbà tí àkókò náà máa tó. Àmọ́ o, a ò gbọ́dọ̀ rò pé Jèhófà kò fẹ́ ṣe ohunkóhun nípa ìyà èyíkéyìí tó lè máa jẹ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lákòókò tó fi ń dúró yìí. Ọlọ́run tó ní “ìyọ́nú” ni, Bíbélì sì pè é ní ìfẹ́. (Lúùkù 1:78; 1 Jòhánù 4:8) Ó máa mú ìpalára èyíkéyìí tó lè dé bá àwọn èèyàn rẹ̀ lákòókò ráńpẹ́ tó fi fàyè gba ìyà yìí kúrò.—Sáàmù 37:10.

6. Èrò wo ni kò yẹ ká ní nípa Ọlọ́run, kí sì nìdí?

6 Lóòótọ́, kì í rọrùn láti máa dúró de ohun kan téèyàn fẹ́ kó tètè tẹ òun lọ́wọ́. (Òwe 13:12) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé tẹ́nì kan ò bá tètè ṣe ohun tó ṣèlérí pé òun máa ṣe, àwọn èèyàn lè máa rò pé nǹkan náà ò fìgbà kan wu onítọ̀hún ṣe. Kò ní bọ́gbọ́n mu rárá láti rò pé Ọlọ́run ò fẹ́ mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ o! Tá a bá lọ rò pé fífi nǹkan falẹ̀ ni sùúrù Ọlọ́run túmọ̀ sí, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì, ká rẹ̀wẹ̀sì, kíyẹn sì mú ká dẹni tó ń tòògbé nípa tẹ̀mí. Ohun tó tiẹ̀ burú jùyẹn lọ ni pé àwọn tí Pétérù kìlọ̀ nípa wọn tẹ́lẹ̀ lè tàn wá jẹ, ìyẹn àwọn olùyọṣùtì tí wọn ò nígbàgbọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ló máa ń fini ṣẹ̀sín, tí wọ́n máa ń sọ pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”—2 Pétérù 3:4.

7. Báwo ni sùúrù Jèhófà ṣe kan fífẹ́ tó fẹ́ káwọn èèyàn ronú pìwà dà?

7 Kókó kejì tá a tún lè fà yọ nínú ọ̀rọ̀ Pétérù ni pé Jèhófà ní sùúrù nítorí pé ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà. Jèhófà yóò pa àwọn tó kọ̀ láti yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú tí wọ́n ń tọ̀ run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò ní inú dídùn sí ikú àwọn ẹni búburú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fẹ́ káwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n sì yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn, kí wọ́n sì máa wà láàyè nìṣó. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Ìdí nìyẹn tó fi ń mú sùúrù tó sì ń rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti kéde ìhìn rere náà ní gbogbo ayé káwọn èèyàn lè láǹfààní àtiwà láàyè.

8. Kí la lè kọ́ nípa sùúrù Ọlọ́run tá a bá ronú lórí bó ṣe bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò?

8 A tún lè rí sùúrù Ọlọ́run nínú ọ̀nà tó gbà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì lò. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ló fi fara da àìgbọràn wọn. Léraléra ló ń tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́, àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, àti èyí tí mo fi ránṣẹ́ sí yín nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó ṣeni láàánú pé àwọn èèyàn náà ‘kò fetí sílẹ̀.’—2 Àwọn Ọba 17:13, 14.

9. Báwo ni sùúrù Jésù ṣe rí bíi ti Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́?

9 Níkẹyìn, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá, ọmọ náà sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti pàrọwà fún àwọn Júù pé kí wọ́n bá Ọlọ́run làjà. Jésù ní sùúrù bíi ti Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́. Jésù mọ̀ dájú pé wọn ò ní pẹ́ pa òun, síbẹ̀ ó kédàárò pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ.” (Mátíù 23:37) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀, kò jọ ọ̀rọ̀ òǹrorò adájọ́ kan tó ń wá bóun ṣe máa fìyà jẹ ẹnì kan. Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó sì ń mú sùúrù fúnni ni. Bíi ti Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jésù fẹ́ káwọn èèyàn náà ronú pìwà dà kí wọ́n lè bọ́ nínú ìdájọ́ mímúná tó ń bọ̀. Àwọn kan fi ọkàn tó dáa gba ìkìlọ̀ tí Jésù fún wọn, wọ́n sì yè bọ́ nínú ìdájọ́ mímúná tó wá sórí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.—Lúùkù 21:20-22.

10. Ọ̀nà wo ni sùúrù Ọlọ́run gbà ṣe wá láǹfààní?

10 Ǹjẹ́ sùúrù Ọlọ́run ò yani lẹ́nu? Pẹ̀lú bí àìgbọràn ọmọ aráyé ṣe pọ̀ tó, Jèhófà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn mìíràn láǹfààní láti wá mọ òun ká sì ní ìrètí àtirí ìgbàlà. Pétérù kọ̀wé sáwọn tó jẹ́ Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pétérù 3:15) Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé sùúrù Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti rí ìgbàlà? Ǹjẹ́ kì í ṣe àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa mú sùúrù fún wa nìṣó bá a ṣe ń sìn ín lójoojúmọ́?—Mátíù 6:12.

11. Kí ni òye tá a ní nípa sùúrù Jèhófà yóò mú ká ṣe?

11 Tá a bá lóye ìdí tí Jèhófà fi mú sùúrù, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi sùúrù dúró de ìgbàlà tí yóò mú wá, a ò sì ní ronú láé pé ńṣe ló ń fi ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ falẹ̀. (Ìdárò 3:26) Bá a ṣe ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run mọ àkókò tó dára jù lọ láti dáhùn àdúrà náà. Yàtọ̀ síyẹn, òye tá a ní yìí tún ń mú kó wù wá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nípa fífi sùúrù bíi tirẹ̀ hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará wa àtàwọn tá à ń wàásù fún. Àwa náà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, ohun tá a fẹ́ ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà káwọn náà lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun bíi tiwa.—1 Tímótì 2:3, 4.

Ronú Nípa Sùúrù Àwọn Wòlíì

12, 13. Níbàámu pẹ̀lú Jákọ́bù 5:10, báwo ni sùúrù tí wòlíì Aísáyà ní ṣe mú kó ṣàṣeyọrí?

12 Ríronú nípa sùúrù Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì ànímọ́ yẹn ká sì gbìyànjú láti ní i. Kò rọrùn fún èèyàn aláìpé láti ní sùúrù, àmọ́ ohun tó ṣeé ṣe ni. A rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ìgbàanì. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ fi àwọn wòlíì, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà ṣe àpẹẹrẹ jíjìyà ibi àti mímú sùúrù.” (Jákọ́bù 5:10) Ìtùnú àti ìṣírí ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé àwọn kan ti borí àwọn ìṣòro tó jọ èyí táwa náà ní.

13 Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé wòlíì Aísáyà nílò sùúrù nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Jèhófà sì fi èyí hàn nípa sísọ fún un pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ní àgbọ́túngbọ́, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe lóye; kí ẹ sì rí ní àrítúnrí, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ní ìmọ̀ kankan.’ Mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́, sì mú kí etí wọn gan-an gíràn-án, sì lẹ ojú wọn gan-an pọ̀, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kí ọkàn-àyà wọn má sì lóye, kí wọ́n má sì yí padà ní tòótọ́, kí wọ́n má sì rí ìmúláradá gbà fún ara wọn.” (Aísáyà 6:9, 10) Pẹ̀lú báwọn èèyàn náà ṣe ya aláìgbọràn tó, Aísáyà fi sùúrù kéde ìkìlọ̀ Jèhófà fún ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ! Bákan náà ni sùúrù yóò ṣe ran àwa náà lọ́wọ́ láti ni ìfaradà nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tá a ń ṣe, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

14, 15. Kí ló ran Jeremáyà lọ́wọ́ láti borí ìpọ́njú àti ìrẹ̀wẹ̀sì?

14 Láìsí àní-àní, báwọn wòlíì wọ̀nyẹn ṣe ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ, kì í ṣe ìṣòro àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn nìkan ni wọ́n dojú kọ, àwọn èèyàn tún ṣenúnibíni sí wọn pẹ̀lú. Wọ́n fi Jeremáyà sínú àbà, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n nínú “ilé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀,” wọ́n sì sọ ọ́ sínú ìkùdu kan. (Jeremáyà 20:2; 37:15; 38:6) Àwọn èèyàn tí Jeremáyà fẹ́ ràn lọ́wọ́ gan-an ló sì ṣe inúnibíni yìí sí i. Síbẹ̀, Jeremáyà ò bínú sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò gbẹ̀san. Ó mú sùúrù, ó sì fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún.

15 Inúnibíni àti ìfiniṣẹ̀sín kò pa Jeremáyà lẹ́nu mọ́, kò sì pa àwa náà lẹ́nu mọ́ lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà míì. Jeremáyà náà rẹ̀wẹ̀sì. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà di okùnfà ẹ̀gàn àti ìfiṣeyẹ̀yẹ́ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Mo sì wí pé: ‘Èmi kì yóò mẹ́nu kàn án, èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.’” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ṣé Jeremáyà wá fi iṣẹ́ ìwàásù sílẹ̀ ni? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nínú ọkàn-àyà mi, ó sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra sú mi, èmi kò sì lè fara dà á.” (Jeremáyà 20:8, 9) Kíyè sí i pé nígbà tí Jeremáyà ń ronú ṣáá nípa báwọn èèyàn ṣe ń fòun ṣe yẹ̀yẹ́, ńṣe ni inú rẹ̀ ń bà jẹ́. Àmọ́ nígbà tó wá ń ronú nípa bí iṣẹ́ náà ṣe dára tó àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ padà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jèhófà tún wà pẹ̀lú Jeremáyà “bí alágbára ńlá,” ó fún un lókun láti fi ìtara àti ìgboyà kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jeremáyà 20:11.

16. Kí la lè ṣe tí ayọ̀ wa ò fi ní bà jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà?

16 Ǹjẹ́ wòlíì Jeremáyà láyọ̀ nínú iṣẹ́ rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Ó sọ fún Jèhófà pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà.” (Jeremáyà 15:16) Inú Jeremáyà dùn pé òun láǹfààní láti jẹ́ aṣojú fún Ọlọ́run tòótọ́, òun sì ń wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó yẹ kínú àwa náà máa dùn. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa tún ń dùn bí inú àwọn áńgẹ́lì ọ̀run ṣe ń dùn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba ìhìn Ìjọba náà jákèjádò ayé, tí wọ́n ń ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ti wà lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Lúùkù 15:10.

“Ìfaradà Jóòbù”

17, 18. Ọ̀nà wo ni Jóòbù gbà fi ìfaradà hàn, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

17 Lẹ́yìn tí Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì ayé ìgbàanì tán, ó tún kọ̀wé pé: “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfaradà” níbi yìí ní ìtumọ̀ kan tó fara jọ ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù lò fún “sùúrù” nínú ẹsẹ tó ṣáájú ìyẹn. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan ń tọ́ka sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì, ó kọ̀wé pé: “Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjèèjì yẹn ni pé ọ̀kan ń tọ́ka sí sùúrù tàbí ìfaradà tá a máa ń ní nígbà táwọn èèyàn bá ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wa, èkejì sì ń tọ́ka sí sùúrù tàbí ìfaradà tá a máa ń ní nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú.”

18 Ojú Jóòbù rí màbo. Gbogbo ọrọ̀ tó ní ṣègbé, àwọn ọmọ rẹ̀ kú, àrùn kan tó ń roni lára gan-an tún kọ lù ú. Wọ́n tún sọ fún un pé Jèhófà ló ń fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Kì í ṣe pé Jóòbù kàn ń jìyà yẹn láìfọhùn o; ó kédàárò nípa ipò tó wà, ó tiẹ̀ fọgbọ́n sọ pé òdodo òun ju ti Ọlọ́run lọ. (Jóòbù 35:2) Àmọ́, kò fìgbà kankan ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́, kò sì yẹsẹ̀ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò bú Ọlọ́run bí Sátánì ṣe sọ pé ó máa ṣe. (Jóòbù 1:11, 21) Kí ni àbájáde rẹ̀? Jèhófà “bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:12) Jèhófà mú Jóòbù lára dá, ó sọ ọrọ̀ rẹ̀ di ìlọ́po méjì, ó sì fi ẹ̀mí gígùn tó kún fún ayọ̀ jíǹkí rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Bí Jóòbù ṣe fara da ìṣòro rẹ̀ láìyẹsẹ̀ yẹn tún mú kó ṣeé ṣe fún un láti túbọ̀ lóye Jèhófà sí i.

19. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí Jóòbù ṣe mú sùúrù tó sì fara da ìṣòro rẹ̀?

19 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí Jóòbù ṣe mú sùúrù tó sì fara da ìṣòro rẹ̀? Bíi ti Jóòbù, àìsàn lè ṣe àwa náà tàbí ká bára wa nínú àwọn ìṣòro mìíràn. A lè má lóye ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àdánwò kan pàtó tó dé bá wa. Síbẹ̀, ohun kan tó yẹ kó dá wa lójú ni pé: Tá a bá ń bá ìṣòtítọ́ wa nìṣó, a óò rí ìbùkún gbà. Ó dájú pé Jèhófà máa ń san ẹ̀san fáwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá a. (Hébérù 11:6) Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 10:22; 24:13.

“Ọjọ́ Jèhófà Yóò Dé”

20. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé?

20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ní sùúrù, síbẹ̀ olódodo ni, kò sì ní fàyè gba ìwà ibi títí lọ. Sùúrù rẹ̀ ní ààlà. Pétérù kọ̀wé pé: ‘[Ọlọ́run] kò fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì.’ Nígbà tí Ọlọ́run dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí, ó fi àkúnya omi pa àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run run. Jèhófà tún mú ìdájọ́ mímúná wá sórí Sódómù àti Gòmórà, ó sì pa wọ́n run yán-ányán-án. Àwọn ìdájọ́ mímúná wọ̀nyí fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.” Èyí sì mú un dá wa lójú pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé.”—2 Pétérù 2:5, 6; 3:10.

21. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní sùúrù àti ìfaradà, kókó wo la ó sì gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Nítorí náà ẹ jẹ́ ká máa mú sùúrù bíi ti Jèhófà, ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ẹ tún jẹ́ ká fara wé àwọn wòlíì nípa fífi sùúrù kéde ìhìn rere náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn tá a ń wàásù fún lè má tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ wa. Àwa náà lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu tá a bá ṣe bíi ti Jóòbù, tá a fara da àwọn àdánwò, tá ò sì jáwọ́ nínú híhu ìwà títọ́. Ó yẹ ká máa yọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nítorí bí ọ̀pọ̀ ìbùkún Jèhófà ṣe wà lórí ipa táwọn èèyàn rẹ̀ ń sà nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà jákèjádò ayé. A óò rí àwọn ó rí àwọn ìbùkún náà nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí Jèhófà fi ní sùúrù?

• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú sùúrù àwọn wòlíì?

• Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òun ní ìfaradà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

• Báwo la ṣe mọ̀ pé sùúrù Jèhófà láàlà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jésù ní sùúrù bíi ti Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún Jeremáyà nítorí sùúrù rẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún Jóòbù nítorí pé ó ní ìfaradà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́