Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
JEHOFA sọ fún Abramu pé: “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, . . . sí ilẹ̀ kan tí èmi ó fi hàn ọ́: èmi ó sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi ó sì bùsí i fún ọ, èmi ó sì sọ orúkọ rẹ di ńlá.” (Genesisi 12:1, 2) Abramu jẹ́ ẹni ọdún 75 nígbà náà. Ó ṣègbọràn ó sì fi pẹ̀lú ọgbọ́n ṣe sùúrù fún gbogbo ìyókù ìgbésí-ayé rẹ̀, ní gbígbáralé Jehofa.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Ọlọrun ṣe ìlérí yìí fún Abrahamu (Abramu) onísùúrù pé: “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísíi èmi ó mú ọ bísíi.” Aposteli Paulu fikún un pé: “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí ó fi sùúrù dúró, ó rí ìlérí náà gbà.”—Heberu 6:13-15.
Kí ni sùúrù? Àwọn ìwé atúmọ̀-èdè túmọ̀ rẹ̀ sí agbára ìṣe “láti fi pẹ̀lẹ́tùù dúró de ohun kan” tàbí láti fi “àmúmọ́ra” hàn “lábẹ́ ìsúnnibínú tàbí ìgalára.” Nítorí náà sùúrù rẹ ní a ń fi sábẹ́ ìdánwò nígbà tí o bá níláti dúró de ẹnìkan tàbí ohun kan, tàbí nígbà tí a bá mú ọ bínú tàbí tí o bá wà lábẹ́ másùnmáwo. Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ ẹnìkan tí ó ní sùúrù máa ń séraró; aláìnísùúrù a máa kánjú a sì máa ń tètè mú un bínú.
Ayé Aláìnísùúrù Wa ti Òde-Òní
Ní pàtàkì jùlọ ní àwọn agbègbè ìgboro ìlú, ìtẹnumọ́ ni a gbékarí ìkánjú wìrìwìrì kìí ṣe sùúrù. Fún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú tí ènìyàn pọ̀ sí, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí agogo bá dún ní òwúrọ̀. Ìyẹn ni ó máa ń bẹ̀rẹ̀ rọ̀tìrọ̀tì—láti dé ibìkan, láti rí ẹnìkan, láti jèrè ohun kan. Ó ha yanilẹ́nu nígbà náà pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn jẹ́ onígbòónára àti aláìnísùúrù?
Inú ha máa ń bí ọ nígbà tí o bá dojúkọ àìdójú-ìwọ̀n àwọn ẹlòmíràn bí? “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí i pé kí àwọn ẹlòmíràn máa pẹ́ lẹ́yìn,” ní Albert wí. Ọ̀pọ̀ yóò gbà pé dídúró de ẹnìkan tí ó ti dánidúró kọjá àkókò tí a fàdéhùn sí lè fa másùnmáwo, pàápàá jùlọ bí ààlà àkókò kan bá wà tí a níláti lébá. Nípa ti Mọ́gàjí Newcastle, òṣèlú ilẹ̀ Britain ti ọ̀rúndún kejìdínlógún, a sọ wí pé: ‘Ó pàdánù ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ní òwúrọ̀, ó sì gbìyànjú láti lé e bá títí ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà ṣùgbọ́n kò lè lé e bá.’ Bí o bá níláti gbáralé irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò ha máa ní sùúrù nìṣó bí?
Nígbà tí o bá ń wa ọkọ̀ ìrìnnà, ǹjẹ́ o tètè máa ń bínú, ní lílọ́tìkọ̀ láti dúró, tàbí a ha ń mú kí o sáré jù bí? Nínú irú àwọn àyíká-ipò bẹ́ẹ̀, àìnísùúrù sábà máa ń yọrísí ìjábá. Ní 1989, níbi tí a ń pè ní West Germany nígbà náà, iye ìjàm̀bá tí ó ju 400,000 lọ lójú ọ̀nà mọ́tò yọrísí ìfarapa tàbí ikú. Okùnfà 1 nínú 3 lára ìwọ̀nyí jẹ́ sísáré jù tàbí wíwakọ̀ súnmọ́ mọ́tò tí ó wà níwájú jù. Nítorí náà, dé ìwọ̀n àyè kan ó kérétán, àìnísùúrù ni ó fa ìfarapa tàbí ikú iye àwọn ènìyàn tí ó ju 137,000 lọ. Ẹ wo iye owó tí ìyẹn jẹ́ láti san fún àìnísùúrù!
Ann ṣàròyé pé, “Ó máa ń ṣòro fún mi láti máa mú sùúrù nìṣó nígbà tí ẹnìkan bá ń dá ọ̀rọ̀ mọ́ mi lẹ́nu ní gbogbo ìgbà, tàbí nígbà tí ẹnìkan bá ń fọ́nnu jù.” Karl-Hermann gbà pé sùúrù òun ni “àwọn ọmọdé tí wọn kò ní ọ̀wọ̀ fún àgbàlagbà” ń pèníjà.
Ìwọ̀nyí àti àwọn ipò ọ̀ràn mìíràn lè mú kí o jẹ́ aláìnísùúrù. Báwo, nígbà náà, ni ó ṣe lè mú sùúrù púpọ̀ síi dàgbà?
Jehofa Lè Fokun fún Sùúrù Rẹ
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ronú pé sùúrù ń fi àìlèṣèpinnu tàbí àìlera hàn. Bí ó ti wù kí ó rí, fún Jehofa ó jẹ́ àmì agbára. Òun fúnraarẹ̀ “ń mú sùúrù . . . nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó ṣègbé, bíkòṣe kí gbogbo ènìyàn kí ó wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Peteru 3:9) Nítorí náà láti fokun fún àmúmọ́ra tìrẹ, rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Jehofa kí o sì gbáralé e pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ. Mímú ipò-ìbátan rẹ pẹ̀lú Ọlọrun lókun síi ni ìgbésẹ̀ ṣíṣepàtàkì kanṣoṣo síhà mímú sùúrù dàgbà.
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ṣekókó láti mọ ète Jehofa fún orí ilẹ̀-ayé àti aráyé. Abrahamu “ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀ [Ìjọba Ọlọrun]; èyí tí Ọlọrun tẹ̀dó tí ó sì kọ́.” (Heberu 11:10) Lọ́nà kan náà, yóò ṣàǹfààní láti pa ojú-ìwòye tí ó mọ́lẹ̀ kedere mọ́ nípa àwọn ìlérí àtọ̀runwá àti láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú dídúró de Jehofa. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé sùúrù, jìnnà réré sí fífi ìlọ́tìkọ̀ hàn, ń jèrè àwọn ènìyàn sínú ìjọsìn tòótọ́ níti gidi. Fún ìdí yìí, “kà á sí pé, sùúrù Oluwa wa ìgbàlà ni.”—2 Peteru 3:15.
Bí àwọn àyíká-ipò tìrẹ fúnraàrẹ bá dán sùúrù rẹ wò dé ìwọ̀n tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá gèjíà ń kọ́? Àwọn aláìgbàgbọ́ ha ń fi ọ sábẹ́ ìgalára tí ń múnibínú bí? Àmódi ha ti mú ọ fún àkókò tí ó dàbí èyí tí kò ní dópin bí? Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, fi ohun tí ọmọlẹ́yìn náà Jakọbu sọ sọ́kàn. Lẹ́yìn títọ́ka sí àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe tí àwọn wòlíì filélẹ̀ nípa fífi sùúrù hàn, ó ṣípayá àṣírí ṣíṣewọ̀ọ̀ lábẹ́ másùnmáwo mímúná. Jakọbu wí pé: “Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? jẹ́ kí ó gbàdúrà.”—Jakọbu 5:10, 13.
Fi tọkàntara béèrè nínú àdúrà pé kí Ọlọrun fún sùúrù rẹ lókun kí ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàkóso ẹ̀mí rẹ lábẹ́ àdánwò. Yíjúsí Jehofa léraléra, òun yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dá àwọn àyíká-ipò tàbí ìwà àwọn ẹlòmíràn èyí tí ń gbé ìhalẹ̀mọ́ni kan ní pàtàkì karí ìbàlẹ̀-ọkàn rẹ mọ̀. Gbígbàdúrà ṣáájú àwọn ipò kan tí ó lè dán ọ wò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbéjẹ́ẹ́.
Ojú-Ìwòye tí Ó Tọ́ Nípa Ara-Ẹni àti Àwọn Ẹlòmíràn
Láti ní ipò-ọkàn píparọ́rọ́, o gbọ́dọ̀ wo araàrẹ àti àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà yíyẹ. Èyí ṣeéṣe nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, nítorí tí ó fihàn pé olúkúlùkù ti jogún àìpé àti nítorí náà wọ́n ní àwọn àìdójú-ìwọ̀n. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìmọ̀ Bibeli yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dàgbà nínú ìfẹ́. Ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì láti lè fi sùúrù hàn sí àwọn ẹlòmíràn.—Johannu 13:34, 35; Romu 5:12; Filippi 1:9.
Ìfẹ́ àti ìháragàgà láti dáríjinni lè mú kí ara rọ̀ ọ́ pẹ̀sẹ̀ nígbà tí inú rẹ bá ru. Bí ẹnìkan bá ní àwọn ìwà tí ó máa ń bí ọ nínú, ìfẹ́ yóò rán ọ létí pé àwọn ìwà náà ni ohun tí kò tẹ́ ọ lọ́rùn, kìí ṣe ẹni náà. Ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn àìlera tìrẹ fúnraàrẹ ti gbọ́dọ̀ dán sùúrù Ọlọrun wò tí ó sì ti gbọ́dọ̀ mú àwọn ẹlòmíràn bínú.
Ojú-ìwòye títọ̀nà nípa araàrẹ yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi sùúrù dúró. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ ha ti ń nàgà fún àwọn àǹfààní nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa, kìkì láti rí i pé a já ọ kulẹ̀ bí? Ìwọ ha ṣàkíyèsí pé sùúrù rẹ ń yára lọ sí òpin bí? Bí ìyẹn bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà rántí pé ọ̀pọ̀ àìnísùúrù ní gbòǹgbò wọn nínú ìgbéraga. ‘Onísùúrù ọkàn sàn ju ọlọ́kàn ìgbéraga lọ,’ ni Solomoni wí. (Oniwasu 7:8) Bẹ́ẹ̀ni, ìgbéraga jẹ́ ìdíwọ́ pàtàkì kan fún mímú sùúrù dàgbà. Kìí ha ṣe òtítọ́ pé ó túbọ̀ máa ń rọrùn fún ẹnìkan tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn láti fi pẹ̀lẹ́tùù dúró bí? Nítorí náà, mú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn dàgbà, yóò sì túbọ̀ ṣeéṣe fún ọ láti fi àlááfíà ọkàn tẹ́wọ́gba ìdádúró.—Owe 15:33.
Sùúrù Ń Mú Èrè Dídọ́ṣọ̀ Wá
A mọ Abrahamu ní pàtàkì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Romu 4:11) Síbẹ̀, sùúrù mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tọ́jọ́. Kí ni èrè rẹ̀ fún dídúró de Jehofa?
Ìgbẹ́kẹ̀lé Jehofa nínú Abrahamu ń pọ̀ síi. Orúkọ Abrahamu tipa bẹ́ẹ̀ di ńlá àwọn ọmọ ìran rẹ̀ sì di orílẹ̀-èdè ńlá. Gbogbo ìdílé orí ilẹ̀-ayé lè bùkún fún araawọn nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ̀. Abrahamu ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọrun àní gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ-irú Ẹlẹ́dàá náà. Èrè títóbi jù èyíkéyìí ha ti wà fún ìgbàgbọ́ àti sùúrù Abrahamu bí?
“Oluwa kún fún ìyọ́nú” sí àwọn Kristian tí wọ́n ń fi sùúrù farada àdánwò. (Jakọbu 5:10, 11) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń gbádùn ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ nítorí ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Nígbà náà, nínú ọ̀ràn tìrẹ, bí o bá dúró de Jehofa tí o sì fi sùúrù farada àdánwò, àmúmọ́ra rẹ yóò yọrísí ìtẹ́wọ́gbà àti ìbùkún Jehofa.
Sùúrù ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn Ọlọrun ní gbogbo apá ìgbésí-ayé. Méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ Jehofa, tí wọ́n ń jẹ́ Christian àti Agnes, ṣàwárí èyí nígbà tí wọ́n pinnu láti wọnú àdéhùn ìgbéyàwó. Wọ́n dá àdéhùn ìgbéyàwó náà dúró nítorí ọ̀wọ̀ wọn fún àwọn òbí Christian, tí wọ́n nílò àkókò láti mọ Agnes dáradára. Ipa wo ni ìṣesí yìí ní?
“Kìkì lẹ́yìn náà ni a tó mọ bí sùúrù wa ti ní ìtumọ̀ púpọ̀ tó fún àwọn òbí mi,” ní Christian ṣàlàyé. “Fífi tí a fi sùúrù dúró kò ba ipò-ìbátan náà tí ó wà láàárín èmi àti aya mi jẹ́. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó so ipò-ìbátan tí a ní pẹ̀lú àwọn òbí mi papọ̀ mọ́ra.” Bẹ́ẹ̀ni, sùúrù ń mú érè dídọ́ṣọ̀ wá.
Sùúrù tún ń gbé àlááfíà ga. Àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ yóò fi ìmoore hàn pé ìwọ kò sọ gbogbo ìfàsẹ́yìn wọn di nǹkan bàbàrà. Ìparọ́rọ́ àti òye rẹ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣe àṣìṣe yóò ṣèdíwọ́ fún àwọn ìgbésẹ̀ tí ń kótìjúbáni. Òwe ilẹ̀ China kan sọ pé: “Sùúrù lákòókò ìbínú yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ làásìgbò ọlọ́gọ́rùn-ún ọjọ́.”
Sùúrù ń mú àkópọ̀ ànímọ́ rẹ sunwọ̀n síi, nítòótọ́ ni o ń mú àwọn ànímọ́ rere mìíràn dángbinrin pẹ̀lú ọ̀dà tí ń mú kí wọ́n wà títílọ. Ó ń mú kí ìgbàgbọ́ rẹ tọ́jọ́, kí àlááfíà rẹ lálòpẹ́, kí ìfẹ́ rẹ sì jẹ́ aláìyẹsẹ̀. Níní sùúrù yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀ bí o ti ń sọ inúrere, ìwàrere-ìṣeun, àti ìwàtútù di àṣà. Ṣíṣe sùúrù ń gbé okun náà ró tí ó ṣekókó fún mímú ìpamọ́ra àti ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà.
Nígbà náà, fi sùúrù dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí Jehofa, ìwọ yóò sì ní ìdánilójú ọjọ́-ọ̀la àgbàyanu kan. Bíi ti Abrahamu, ǹjẹ́ kí ìwọ náà lè “ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.”—Heberu 6:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi sùúrù hàn, gẹ́gẹ́ bí Abrahamu ti ṣe