Sùúrù La Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
1. Báwo ni Jèhófà ṣe fi sùúrù bá àwọn èèyàn lò?
1 Ọlọ́run máa ń ṣe sùúrù gan-an fún àwọn ẹ̀dá èèyàn. (Ẹ́kís. 34:6; Sm. 106:41-45; 2 Pét. 3:9) Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí à ń ṣe kárí ayé jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbawájú jù lọ tí Jèhófà gbà ń fi ìfẹ́ ní sùúrù fún aráyé. Jèhófà ti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú aráyé fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún, síbẹ̀ ó ṣì ń bá a lọ láti máa fa àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
2. Báwo la ṣe lè lo sùúrù nígbà tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa?
2 Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-Dé-Ilé: À ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ sùúrù Jèhófà nípa wíwàásù “láìdábọ̀” ní ìpínlẹ̀ tí àwọn èèyàn kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. (Ìṣe 5:42) A máa ń fi sùúrù fara da ìdágunlá, ìfiniṣẹ̀sín àti àtakò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Máàkù 13:12, 13) A tún máa ń lo sùúrù nípa pípadà lọ bomi rin irúgbìn òtítọ́ tí a gbìn, kódà nígbà tí kò rọrùn láti bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa nílé.
3. Kí nìdí tá a fi nílò sùúrù nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tá a sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Béèyàn bá gbin irúgbìn, ó ní láti ṣe sùúrù fún irúgbìn náà láti dàgbà. A lè máa bójú tó o, àmọ́ a kò lè fipá mú un láti yára dàgbà. (Ják. 5:7) Bákan náà, díẹ̀díẹ̀ lèèyàn máa ń dàgbà nípa tẹ̀mí, ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ló sì máa ń jẹ́. (Máàkù 4:28) Ó lè ṣòro fún àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti fi ìsìn èké tàbí àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu sílẹ̀. A ò gbọ́dọ̀ fipá mú ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé kó ṣe ìyípadà kíákíá. Ó gba pé ká ní sùúrù fún àwọn àkókò kan kí ẹ̀mí Ọlọ́run lè ṣiṣẹ́ nínú ọkàn ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.—1 Kọ́r. 3:6, 7.
4. Báwo ni sùúrù ṣe lè mú ká jẹ́rìí lọ́nà tó gbéṣẹ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
4 Àwọn Mọ̀lẹ́bí Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà: Lóòótọ́, ó wù wá gan-an pé kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n a máa fi hàn pé a ní sùúrù nípa dídúró di àkókò tó wọ̀ tá a lè sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún wọn, ó sì yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ fi ìsọfúnni tó pọ̀ jù pá wọn lórí. (Oníw. 3:1, 7) Ní báyìí ná, ká máa hùwà rere kí wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ látara wa, ká sì máa wà ní ìmúratán láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ pẹ̀lú ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. (1 Pét. 3:1, 15) Kò sí àní-àní pé tá a bá ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó máa mú kó gbéṣẹ́, ó sì máa múnú Baba wa ọ̀run dùn.