ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 8
  • Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tó o fi nílò sùúrù?
  • Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù?
  • Sùúrù La Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 8
Ara ọkọ kan ò balẹ̀ bó ṣe ń dúró de ìyàwọ́ ẹ̀ tó ń ra bàtà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù

“Ọkọ àti ìyàwó nílò sùúrù gan-an lójoojúmọ́. Ó lè má ṣòro fún ẹ láti máa ní sùúrù kó o tó ṣègbéyàwó, àmọ́, ó ṣe pàtàkì kí ìdílé kan tó lè ṣàṣeyọrí.”—John.

  • Kí nìdí tó o fi nílò sùúrù?

  • Báwo lo ṣe lè ní sùúrù?

  • “Sùúrù ṣe pàtàkì”

Kí nìdí tó o fi nílò sùúrù?

  • Ìgbéyàwó lè mú kó o túbọ̀ rí àwọn àṣìṣe ọkọ tàbí aya ẹ.

    “Tó bá ti ṣe díẹ̀ tẹ́nì kan ti ṣègbéyàwó, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ranjú mọ́ àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ọkọ tàbí aya rẹ̀. Tí èrò òdì yìí bá ń wá sí i lọ́kàn, ó lè tán an ní sùúrù.”—Jessena

  • Àìnísùúrù lè mú kó o sọ̀rọ̀ kó o tó ronú.

    “Mo máa ń tètè sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi, ó sì máa ń mú kí n sọ ohun tí kò yẹ nígbà míì. Àmọ́ ká ní mo ní sùúrù ni, mi ò bá fara balẹ̀ rò ó dáadáa, kí n sì máa bá tèmi lọ láì tiẹ̀ sọ nǹkan kan.”—Carmen.

    Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé, kí ẹni méjì tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́mìí sùúrù. Àmọ́, kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. John tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bíi tàwọn ànímọ́ dáadáa míì, àtiní sùúrù ò rọrùn tó pé kó bọ́ mọ́ọ̀yàn lọ́wọ́.” Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè máa ní sùúrù nìṣó.”

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù?

  • Nígbà tí ohun kan tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀ fẹ́ tán ẹ ní sùúrù.

    Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ sọ ohun tí kò dáa sí ẹ. Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá a pa dà fún un.

    Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe máa kánjú láti bínú, torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.”—Oníwàásù 7:​9, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

    Bó o ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù: Kọ́kọ́ dúró. Kó o tó fèsì, gbìyànjú láti gbà pé ohun kan ló fà á tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ fi sọ ohun tó sọ sí ẹ, kì í ṣe pé ó mọ̀ọ́mọ̀. Ìwé Fighting for Your Marriage sọ pé: Ohun tá a rò ni ọ̀pọ̀ lára wa sábà máa ń fi hùwà pa dà sí ọkọ tàbí ìyàwó wa dípò ohun tó ní lọ́kàn tàbí ohun tó sọ gangan.

    Ọkọ to fìbínú dáhùn nígbà tí ìyàwó ẹ̀ múnú bí i dà bí ìgbà téèyàn túbọ̀ kógi sí iná tó ń jó; ọkọ tó ń pa nǹkan mọ́ra nígbà tí ìyàwó ẹ̀ múnú bí i dà bí iná tó ń kú lọ

    Ká tiẹ̀ sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ múnú bí ẹ, sùúrù tó o ní lè paná ọ̀rọ̀ náà kàkà kó sọ ọ́ di ńlá. Bíbélì sọ pé “Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú.”—Òwe 26:20.

    “Tó bá ń wá sí ẹ lọ́kàn pé alátakò ni ìyàwó ẹ, kọ́kọ́ dúró, ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ràn ẹ̀, kó o sì ṣe nǹkan kan tó máa múnú ẹ̀ dùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Ethan.

    Rò ó wò ná:

    • Kí lo máa ń ṣe tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá sọ̀rọ̀ kan tàbí tó ṣe ohun kan tí kò bára dé sí ẹ?

    • Tírú ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀, báwo lo ṣe lè túbọ̀ mú sùúrù?

  • Nígbà tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń ṣe ohun kan léraléra, tó sì fẹ́ tán ẹ ní sùúrù.

    Àpẹẹrẹ: Ọkọ tàbí ìyàwó ẹ máa ń pẹ́ lẹ́yìn, inú sì máa ń bí ẹ gan-an bó ṣe ń dá ẹ dúró.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Kólósè 3:13.

    Bó o ṣe lè fi hàn pé o ní sùúrù: Bí àjọṣe ẹ̀yin méjèèjì ṣe máa dáa sí i ló yẹ kó gbawájú kì í ṣe ire tara ẹ nìkan. Bi ara ẹ pé, ‘Tí mo bá fa ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, ṣé ó máa ràn wá lọ́wọ́ àbí ó máa pa wá lára?’ Rántí pé, “gbogbo wa ni a maá ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jémíìsì 3:2) Èyí fi hàn pé ìwọ náà ní àwọn ibi tó o kù sí.

    “Nígbà míì, ó rọrùn fún mi láti mú sùúrù fáwọn ọ̀rẹ́ mi ju ọkọ mi lọ. Ó jọ pé ohun tó fà á ni pé mo sábà máa ń wà pẹ̀lú ọkọ mi, mo sì máa ń rí àwọn àṣìṣe ẹ̀. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà tí ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn ní ni sùúrù, ó máa ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fúnni, ó sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìdílé.”—Nia

    Rò ó wò ná:

    • Ṣé o máa ń ní sùúrù fún ọkọ tàbí ìyàwó ẹ tó bá ṣàṣìṣe?

    • Báwo lo ṣe lè túbọ̀ ní sùúrù nígbà míì?

“Sùúrù ṣe pàtàkì”

Jessena àti ọkọ rẹ̀, Hayden

“Kí ìdílé tó lè ṣàṣeyọrí, sùúrù ṣe pàtàkì. Torí pé èèyàn aláìpé làwọn méjèèjì tó fẹ́ra wọn, oríṣiríṣi ìṣòro ló máa yọjú, kódà ohun tó ti mọ́ ẹnì kan lára lè máa múnú bí ẹnì kejì. Tí a ò bá ní sùúrù àwọn ìṣòro yìí á dà bí ikán tó ń jẹ ilé run, ó sì máa ba ayọ̀ ìdílé jẹ́.”—Jessena àti ọkọ rẹ̀, Hayden.

Àtúnyẹ̀wò: Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù Nínú Ìdílé

Nígbà tí ohun kan tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀ fẹ́ tán ẹ ní sùúrù

Kó o tó fèsì, gbìyànjú láti gbà pé ohun kan ló fà á tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ fi sọ ohun tó sọ sí ẹ, kì í ṣe pé ó mọ̀ọ́mọ̀.

Nígbà tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń ṣe ohun kan léraléra, tó sì fẹ́ tán ẹ ní sùúrù

Bí àjọṣe ẹ̀yin méjèèjì ṣe máa dáa sí i ló yẹ kó gbawájú, kì í ṣe ire tara ẹ nìkan. Rántí pé, ìwọ náà ní àwọn ibi tó o kù sí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́