Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Jẹ́ Kí N Rí Òun
GẸ́GẸ́ BÍ FLORENCE CLARK ṢE SỌ Ọ́
Mo di ọkọ mi tó ń ṣàìsàn gidigidi lọ́wọ́ mú. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọ Áńgílíkà, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ara ọkọ mi yá, mo sì ṣèlérí pé tí kò bá kú, màá wá Ọlọ́run títí n óò fi rí i. Lẹ́yìn náà, màá wá di tirẹ̀.
NÍGBÀ tí wọ́n bí mi lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù September ọdún 1937, orúkọ tí wọ́n sọ mí ni Florence Chulung. Àárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Oombulgurri tí wọ́n ń gbé lórí Òkè Kimberley tó tẹ́jú pẹrẹsẹ ní Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà ni wọ́n bí mi sí.
Mi ò lè gbàgbé ìgbà tí mo wà lọ́mọdé, tí mi ò lóhun tí mò ń rò, tínú mi sì máa ń dùn. Mo kọ́ àwọn ohun díẹ̀ nípa Ọlọ́run àti Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n màmá mi ló kọ́ mi láwọn ìlànà tó yẹ kí Kristẹni máa tẹ̀ lé. Ó máa ń ka Bíbélì fún mi déédéé, láti kékeré ni mo sì ti nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo tún nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí mi ń ṣe fún ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, mo fẹ́ láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀.
Ládùúgbò wa, tá a mọ̀ sí Forrest River Mission tẹ́lẹ̀, ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ló wà níbẹ̀, ó sì ní kíláàsì kìíní dé kíláàsì kárùn-ún. Wákàtí méjì péré ni mo máa ń fi kẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé náà láràárọ̀. Èyí túmọ̀ sí pé ẹ̀kọ́ tí mò ń gbà kò tó nǹkan, èyí ò sì múnú bàbá mi dùn. Ó fẹ́ káwọn ọmọ òun kọ́ ẹ̀kọ́ tó péye, nítorí náà ó pinnu láti fi Oombulgurri sílẹ̀ kó sì kó ìdílé wa lọ sí ìlú Wyndham. Inú mi bà jẹ́ gan-an lọ́jọ́ tá a kúrò níbẹ̀, àmọ́ nílùú Wyndham, ó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sílé ẹ̀kọ́ láti àárọ̀ títí dọ̀sán fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin, láti ọdún 1949 sí ọdún 1952. Mo dúpẹ́ gan-an pé bàbá mi jẹ́ kí n gba ẹ̀kọ́ yẹn.
Màmá mi ń bá dókítà kan ṣiṣẹ́ ládùúgbò wa, nígbà tí mo sì parí ilé ìwé lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, dókítà náà gbà mí síṣẹ́ nọ́ọ̀sì nílé ìwòsàn Wyndham. Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà, nítorí pé iṣẹ́ ṣòroó rí lákòókò yẹn.
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni mo pàdé Alec, ìyẹn òyìnbó kan tó ń bójú tó ẹran ọ̀sìn. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1964 nílùú Derby, níbi tí mo ti máa ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà déédéé. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wa. Mo sọ fún wọn pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wọn rárá mo sì ní wọn ò gbọ́dọ̀ wá sílé wa mọ́. Àmọ́ ohun kan tí wọ́n sọ jọ mí lójú, wọ́n ní Ọlọ́run ní orúkọ tirẹ̀ àti pé Jèhófà ni orúkọ náà.
“Ṣé O Ò Lè Gbàdúrà Fúnra Rẹ Ni?”
Ọdún 1965 ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í le koko fún mi. Jàǹbá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣẹlẹ̀ sí ọkọ mi, méjì lára jàǹbá náà ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà lórí ẹṣin rẹ̀, ọ̀kan tó kù sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. A dúpẹ́ pé gbogbo ibi tó fi pa ló san, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, jàǹbá mìíràn tún ṣẹlẹ̀ sí i lórí ẹṣin rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ó fi orí pa gan-an. Nígbà tí mo délé ìwòsàn tí wọ́n gbé e lọ, dókítà sọ fún mi pé ọkọ mi kò lè rù ú là. Orí mi lọ fee. Ni nọ́ọ̀sì kan bá sọ fún àlùfáà kan ládùúgbò náà pé kó wá bá mi, àmọ́ àlùfáà náà sọ pé: “Mi ò lè wá nísinsìnyí. Màá wá lọ́la!”
Mo sọ fún obìnrin kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé pé mo fẹ́ kí àlùfáà náà dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi kó sì gbàdúrà fún mi. Ohun tí obìnrin náà fi fèsì ni pé: “Kí ló ń ṣe ẹ́? Ṣé o ò lè gbàdúrà fúnra rẹ ni?” Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sáwọn ère inú ṣọ́ọ̀ṣì fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ asán ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ó jọ pé ọkọ mi ń kú lọ. Mo ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe máa ṣelé ayé mi tọ́kọ mi bá kú?’ Mo tún ń ro tàwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn Christine, Nanette, àti Geoffrey. Báwo layé wọn ṣe máa rí láìsí bàbá? Inú mi dùn pé, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta ọkọ mi sọ jí padà ó sì kúrò nílé ìwòsàn lọ́jọ́ kẹfà oṣù December ọdún 1966.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ọkọ mi yá lóòótọ́, àmọ́ jàǹbá náà ti ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ̀. Kì í sábà rántí nǹkan mọ́, ó sì tètè máa ń bínú sódì, bẹ́ẹ̀ ni ìṣesí rẹ̀ sì máa ń ṣàdédé yí padà. Ó ṣòro fún un láti bá àwọn ọmọ ṣe nǹkan pọ̀, ó sì máa ń bínú gan-an tí wọn ò bá hùwà bí àgbàlagbà. Kò rọrùn láti tọ́jú rẹ̀. Èmi ni mò ń bá a ṣe gbogbo nǹkan. Àní mo tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń kàwé àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé. Wàhálà tí mò ń ṣe láti tọ́jú rẹ̀ tí mo sì tún ń bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé yòókù gba gbogbo okun mi, ó sì wá di àìsàn ńlá sí mi lára. Lẹ́yìn ọdún méje tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí ọkọ mi, a jọ gbà pé ká fi ara wa sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ kí ara mi lè mókun padà.
Mo kó àwọn ọmọ mi mo sì gba ìlú Perth tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè wa lọ. Ṣáájú ká tó lọ síbẹ̀, àbúrò mi obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Kununurra, ìyẹn ìlú kékeré kan ní Ìlà Oòrùn Ọsirélíà. Ó fi àwòrán kan hàn mí nínú ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye.a Àwòrán náà ṣàpèjúwe Párádísè ilẹ̀ ayé tí Bíbélì ṣèlérí rẹ̀. Àbúrò mi tún fi hàn mí láti inú ìwé náà pé Ọlọ́run ní orúkọ kan, Jèhófà sì ni orúkọ náà. Èyí wú mi lórí gan-an. Nítorí pé wọn ò tíì sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi rí ní ṣọ́ọ̀ṣì, mo sọ pé gbàrà tí mo bá ti fìdí kalẹ̀ sílùú Perth ni màá fi tẹlifóònù wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn.
Síbẹ̀ náà, mo ṣì ń lọ́ra láti wá wọn kàn. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, agogo ilẹ̀kùn mi dún. Ọmọ mi ọkùnrin ló lọ sídìí ilẹ̀kùn ó sì sáré padà wá, ó ní: “Mọ́mì, àwọn tẹ́ ẹ sọ pé ẹ fẹ́ fi tẹlifóònù pè yẹn ti dé.” Ẹnu yà mí díẹ̀, mo sì sọ pé: “Sọ fún wọn pé mi ò sí nílé!” Ṣùgbọ́n ó fèsì pé: “Mọ́mì, ṣebí ẹ mọ̀ pé kò yẹ kí n purọ́.” Ara mi kó ṣìọ̀, ni mo bá lọ ṣílẹ̀kùn. Bí mo ṣe kí àwọn tó wá náà, mo rí i pé ẹnu yà wọ́n. Àṣé ẹlòmíràn tó ti kó kúrò nílé yẹn ni wọ́n wá wá. Mo ní kí wọ́n wọlé, bí mo ṣe da ìbéèrè bò wọ́n nìyẹn, wọ́n sì fún mi láwọn ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn látinú Bíbélì.
Ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye ni mo sì ń lò. Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mú kí ìfẹ́ mi láti mọ̀ nípa Ọlọ́run tún padà sọ jí. Lọ́sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, mo lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé ní gbogbo ọjọ́ Sunday, kò sì pẹ́ tí mo fi ń lọ sáwọn ìpàdé yòókù láàárín ọ̀sẹ̀. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí mò ń kọ́ fún àwọn èèyàn. Mo wá rí i pé ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kí ara mi yá sí i, ó mú kí ọpọlọ mi túbọ̀ jí pépé, ìrònú mi sì túbọ̀ já gaara sí i. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi nípàdé àgbègbè kan nílùú Perth.
Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì, mo wá lóye pé ohun mímọ́ ni Jèhófà ka ìgbéyàwó sí, títí kan ìlànà Bíbélì tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:13, tó sọ pé: “Obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló mú kí n padà sọ́dọ̀ Alec.
Mo Padà Sílùú Derby
Ọjọ́ kọkànlélógún oṣù June ọdún 1979 ni mo padà sílùú Derby lẹ́yìn tí mo ti fi ọkọ mi sílẹ̀ fún ohun tó lé lọ́dún márùn-ún. Àmọ́ ṣa o, bínú mi ṣe ń dùn bẹ́ẹ̀ lẹ̀rù tún ń bà mí, tí mo sì ń ronú nípa bí ọkọ mi ṣe máa ṣe nígbà tí mo bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé, ńṣe ni inú rẹ̀ dùn pé mo padà sọ́dọ̀ òun, àmọ́ ó sọ pé inú òun kò dùn pé mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dá a lábàá pé kí n máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì òun, èyí tí mò ń lọ tẹ́lẹ̀ kí n tó lọ sílùú Perth. Mo ṣàlàyé fún un pé mi ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti máa tẹrí ba fún un, mo sì ń ṣe ohun tó yẹ kí aya tó jẹ́ Kristẹni máa ṣe. Mo gbìyànjú láti bá a sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ìlérí àgbàyanu tó ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la, àmọ́ kò nífẹ̀ẹ́ sóhun tí mò ń sọ fún un.
Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, kì í ṣe pé Alec fara mọ́ ìsìn tí mo wá ń ṣe nísinsìnyí nìkan ni, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó ràn mí lọ́wọ́ kí n bàa lè máa lọ sáwọn ìpàdé àgbègbè àtàwọn àpéjọ mìíràn, títí kan àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Mo mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tó ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan fún mi pé kí n máa lò ó nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ohun ìní tó wúlò gan-an ló jẹ́ lápá ibi jíjìnnà réré tá à ń gbé yìí nílẹ̀ Ọsirélíà. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin, títí kan alábòójútó àyíká wa, sábà máa ń sùn nílé wa fún àwọn ọjọ́ mélòó kan. Èyí jẹ́ kí Alec mọ ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì jọ pé ó fẹ́ràn bí wọ́n ṣe máa ń wá sọ́dọ̀ wa yẹn.
Ọ̀rọ̀ Mi Rí Bíi Ti Ìsíkíẹ́lì
Mo gbádùn wíwá táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ mo ní ìṣòro kan. Èmi nìkan ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Derby. Ìlú Broome sì ni ìjọ tó sún mọ́ wa jù lọ wà, èyí tó jìn tó igba ó lé ogún [220] kìlómítà. Nítorí náà, mo pinnu láti máa sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn débi tágbára mi lè gbé e dé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mo ṣètò ara mi mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé. Iṣẹ́ yìí kò rọrùn fún mi rárá, àmọ́ mo máa ń rán ara mi létí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
Inú àwọn àlùfáà àgbègbè yẹn kò dùn sí iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àgàgà bí mo ṣe ń wàásù fáwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀. Wọ́n gbìyànjú láti dẹ́rù bà mí kí n má bàa wàásù mọ́. Àmọ́ ńṣe ni àtakò tí wọ́n ń ṣe sí mi túbọ̀ jẹ́ kí n pinnu láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó, mo sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo sábà máa ń rántí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Wò ó! Mo ti mú kí ojú rẹ le gan-an bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le gan-an bí iwájú orí wọn. Bí dáyámọ́ńdì, tí ó le ju akọ òkúta lọ, ni mo ti ṣe iwájú orí rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fòyà wọn, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú wọn kó ìpayà bá ọ.”—Ìsíkíẹ́lì 3:8, 9.
Láwọn àkókò kan, àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Ọsirélíà wá bá mi níbi tí mo ti ń rajà. Wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pariwo káwọn tó ń rajà lágbègbè yẹn lè gbọ́. Àmọ́ mi ò dá wọn lóhùn. Nígbà kan tí mo ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin kan, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò yẹn wá bá mi ó sì fẹ̀sùn kàn mí pé mi ò gba Jésù gbọ́. Ó já Bíbélì mi gbà mọ́ mi lọ́wọ́, ó fì í lójú mi, ó sì fi há mi lọ́wọ́ padà. Mo tẹjú mọ́ ọkùnrin náà, mo sì fi pẹ̀lẹ́tù sọ ohun tó wà nínú Jòhánù 3:16 fún un láìbẹ̀rù, mo jẹ́ kó mọ̀ pé mo gba Jésù gbọ́. Kẹ́kẹ́ pa mọ́ ọn lẹ́nu nítorí ìgboyà tí mo fi dá a lóhùn, ló bá kúrò lọ́dọ̀ mi láìsọ ohunkóhun mọ́.
Mo gbádùn wíwàásù fáwọn ọmọ ìbílẹ̀ tó wà lágbègbè ìlú Derby. Lágbègbè kan níbẹ̀, àlùfáà kan gbìyànjú láti dí mi lọ́wọ́ wíwàásù fáwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n gbé e kúrò níbẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn ibẹ̀. Ó ti pẹ́ tó ti ń wù mí láti jẹ́ míṣọ́nnárì bíi ti ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí mi, mo sì ti wá ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì náà báyìí, tí mò ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà fetí sí ìwàásù mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn kan lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nǹkan Tẹ̀mí Ń Jẹ Mí Lọ́kàn
Odindi ọdún márùn-ún ni èmi nìkan fi jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Derby. Kò rọrùn fún mi láti lókun nípa tẹ̀mí láìsí ìṣírí tó yẹ kí n máa rí gbà látinú pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn. Nígbà kan, ìrẹ̀wẹ̀sì mú mi, ni mo bá wakọ̀ jáde lọ. Nígbà tí mo máa padà dé lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, arábìnrin kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ méje ti ń dúró dè mí. Wọ́n kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wá fún mi láti ìjọ tó wà nílùú Broome tó jẹ́ ọ̀pọ̀ kìlómítà síbi tí mo wà. Látìgbà yẹn ni arábìnrin náà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Betty Butterfield, ti ṣètò láti máa wá sí Derby lẹ́ẹ̀kan lóṣù láti máa lo òpin ọ̀sẹ̀ lọ́dọ̀ mi. A jọ máa ń lọ wàásù a sì jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nílé mi. Èmi náà sì máa ń lọ sí Broome lẹ́ẹ̀kan lóṣù láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Àwọn arákùnrin ní Broome ràn mí lọ́wọ́ gan-an wọ́n sì máa ń rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn wá sí Derby lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ràn mí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n tún máa ń rọ àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin láti àwọn ìlú mìíràn pé tí wọ́n bá fẹ́ gba Derby kọjá kí wọ́n yà wò mí kí wọ́n sì bá mi jáde òde ẹ̀rí. Àwọn arìnrìn-àjò wọ̀nyí tún máa ń mú kásẹ́ẹ̀tì tó ní àsọyé nínú wá fún mi. Èmi àtàwọn kan lára wọn jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àwọn ìbẹ̀wò ráńpẹ́ yìí fún mi níṣìírí gan-an.
Ìrànwọ́ Ṣì Tún Ń Bọ̀ Lọ́nà
Mo tún rí ìṣírí gbà fún bí ọdún mélòó kan nígbà tí Arthur àti Mary Willis tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ bá wá láti apá gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà. Oṣù mẹ́ta ni wọ́n fi máa ń wá ràn mí lọ́wọ́ lákòókò tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí ooru tí wọ́n á sì tún padà. Arákùnrin Willis ló ń darí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìpàdé wa tó sì tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. A jọ máa ń lọ sáwọn ibi jíjìnnà réré tó wà ní Òkè Kimberley, a sì máa ń dé àwọn ibi tí wọ́n ti ń sin ẹran láwọn ibi jíjìnnà wọ̀nyí. Ìgbàkígbà tí Arákùnrin àti Arábìnrin Willis bá ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, ńṣe ló máa ń dà bíi pé nǹkan kan sọ nù nínú ìgbésí ayé mi.
Nígbà tó wá yá, lópin ọdún 1983, mo gba ìròyìn rere kan pé ìdílé kan, ìyẹn Danny àti Denise Sturgeon àtàwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́rin ń bọ̀ wá gbé ní Derby. Lẹ́yìn tí wọ́n dé, a wá ń ṣe àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ déédéé a sì jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Lọ́dún 2001, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Lónìí, ìjọ náà ti fìdí múlẹ̀ dáadáa nílùú Derby. Àwa mẹ́rìnlélógún ló jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀ báyìí, alàgbà méjì àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ló sì wà níbẹ̀, tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjọ. Nígbà mìíràn, a máa ń tó ọgbọ̀n èèyàn nípàdé wa.
Nígbà tí mo bá ronú padà sẹ́yìn, ọ̀nà tí Jèhófà gbà ràn mí lọ́wọ́ láti sìn ín máa ń múnú mi dùn gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ mi kò tíì dara pọ̀ mọ́ mi nínú ìgbàgbọ́, ó ṣì máa ń ràn mí lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn. Àwọn márùn-ún lára ìdílé mi ti di Ẹlẹ́rìí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi, ìyẹn àwọn ọmọ mi obìnrin méjì, àwọn ọmọ ọmọ mi obìnrin méjì àti ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ àbúrò mi. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan nínú ẹbí mi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà.
Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà fún oore tó ṣe fún mi tó jẹ́ kí n rí òun. Mo ti pinnu láti jẹ́ tirẹ̀ títí ayé.—Sáàmù 65:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ỌSIRÉLÍÀ
Wyndham
Òkè Kimberley
Derby
Broome
Perth
[Àwọn Credit Line]
Kangaroo and lyrebird: Lydekker; koala: Meyers
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Mò ń ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì nílé ìwòsàn Wyndham lọ́dún 1953
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìjọ Derby lọ́dún 2005