ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/15 ojú ìwé 31
  • Ẹ Gbáralé Okun Tí Ọlọrun Fifúnni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Gbáralé Okun Tí Ọlọrun Fifúnni
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jiya Ibi Ki O Si Kọni Pẹlu Iwatutupẹlẹ
  • Waasu Ọ̀rọ̀ Naa!
  • Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Òtítọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Tímótì—“Ojúlówó Ọmọ Nínú Ìgbàgbọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • 2 Tímótì 1:7—“Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ìbẹ̀rù”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/15 ojú ìwé 31

Ẹ Gbáralé Okun Tí Ọlọrun Fifúnni

Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati Inu Timoti Keji

JEHOFA fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ní agbara lati farada awọn adanwo ati inunibini. Bawo sì ni Timoti ati awọn Kristian miiran ṣe nilo okun ti Ọlọrun fifunni to! Iná run Romu bajẹ ni 64 C.E., àhesọ si sọ pe Olu-ọba Nero ni o fà á. Lati daabobo araarẹ̀, oun dẹbi fun awọn Kristian, eyi ni kedere sún ìgbì inunibini kan bẹrẹ. O ṣeeṣe pe ni akoko yẹn (ni nnkan bii 65 C.E.) apọsteli Pọọlu ni a fisẹwọn ni Romu lẹẹkan sii. Bi o tilẹ jẹ pe o dojukọ iku, oun nigba naa kọ lẹta rẹ keji si Timoti.

Lẹta Pọọlu mura Timoti silẹ lati dena awọn apẹhinda ki o si duro gbọnyin ni oju inunibini. O fun un ni iṣiri lati maa baa lọ ninu nini itẹsiwaju o si sọ nipa awọn ipo Pọọlu ninu ẹ̀wọ̀n. Lẹta naa tun ran awọn onkawe lọwọ lati gbarale okun ti Ọlọrun fifunni.

Jiya Ibi Ki O Si Kọni Pẹlu Iwatutupẹlẹ

Ọlọrun nfi okun fun wa lati farada inunibini gẹgẹ bi olupokiki ihin rere naa. (1:1-18, NW) Pọọlu ko gbagbe Timoti lae ninu awọn adura rẹ, o si ranti igbagbọ alaini agabagebe rẹ̀. Ọlọrun fun Timoti ‘kii ṣe ẹmi ojo, bikoṣe ẹmi agbara, ifẹ, ati yiyekooro ero inu.’ Nitori naa ki oun maṣe tiju ninu jijẹrii ati jijiya ibi fun ihin rere. A tun rọ ọ lati “maa di apẹẹrẹ ọnà awọn ọ̀rọ̀ yiyekooro mu” eyi ti o gbọ lati ẹnu Pọọlu, ani gẹgẹ bi awa ti nilati rọ̀ timọtimọ laigbagbẹrẹ mọ ojulowo otitọ Kristian bi o tilẹ jẹ pe awọn miiran yipada kuro ninu rẹ̀.

Awọn ohun ti Pọọlu fi kọni ni a nilati fi le awọn oloootọ eniyan lọwọ ti wọn yoo fi kọ awọn ẹlomiran. (2:1-26) Timoti ni a rọ̀ lati jẹ ọmọ ogun rere ti Kristi, ti o jẹ oloootọ nigba ti o ba njiya ibi. Pọọlu funraarẹ jiya ninu ide ẹwọn fun wiwaasu ihinrere. O fun Timoti ni iṣiri lati sa gbogbo ipa rẹ lati fi araarẹ han ni aṣiṣẹ tí Ọlọrun tẹwọgba, ni kikọ awọn ọ̀rọ̀ asán ti nba ohun mimọ jẹ. A sì sọ fun un pe ẹru Oluwa gbọdọ fun awọn ẹlomiran ni itọni pẹlu iwàtútùpẹ̀lẹ́.

Waasu Ọ̀rọ̀ Naa!

Okun ti Ọlọrun fifunni ni a o nilo lati dojukọ awọn ọjọ ikẹhin ki a sì di otitọ Iwe Mimọ mu. (3:1-17, NW) Lati inu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ni awọn ọkunrin ti wọn nfi ‘igbagbogbo kẹkọọ sibẹ ti wọn ko lè de oju imọ pipeye otitọ lae’ yoo ti dide. ‘Iru awọn eniyan buruku ati awọn afàwọ̀rajà’ bẹẹ ‘yoo maa lọ lati buburu si buburu jáì, wọn o maa ṣinilọna a o sì maa ṣi wọn lọna.’ Bi o ti wu ki o ri, Timoti nilati ‘maa baa lọ ninu awọn ohun ti oun ti kọ.’ Bẹẹ ni awa pẹlu gbọdọ ṣe, ni mimọ pe ‘gbogbo Iwe Mimọ ni Ọlọrun mísí o sì lere fun ẹkọ, ifibawitọnisọna, mimu awọn nnkan tọ́ taarata, ati bibaniwi ninu òdodo, ki eniyan Ọlọrun le yẹ ni kikun, ti a ti mu gbaradi patapata fun iṣẹ daradara gbogbo.’

Timoti nilati dena awọn apẹhinda ki o si ṣaṣepari iṣẹ ojiṣẹ rẹ. (4:1-22) Oun le ṣe bẹẹ nipa ‘wiwaasu ọrọ naa’ ki o si tẹramọ ṣiṣe e. Eyi ṣe pataki, niwọnbi ijọ naa ti dojukọ “asiko ijangbọn” nitori pe awọn kan nkọni ni ẹkọ igbagbọ eke. Awọn Ẹlẹrii Jehofa tun rọ̀mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nisinsinyi, ni wiwaasu rẹ ní kanjukanju ninu ijọ ati fun awọn eniyan lẹhin ode, ani ni awọn ipo ti ko rọgbọ paapaa. Pọọlu “pa igbagbọ mọ,” bi o tilẹ jẹ pe awọn kan ti kọ̀ ọ́ ti. Ṣugbọn ‘Oluwa fi agbara fun un, pe nipasẹ rẹ ki a le ṣe aṣepari iwaasu naa ni kikun.’ Njẹ ki awa pẹlu gbarale okun ti Ọlọrun fifunni ki a si maa baa niṣo ni wiwaasu ihin rere naa.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ọmọ-ogun Rere Kan: Pọọlu rọ Timoti pe: “Gẹgẹ bi ọmọ ogun rere ti Kristi Jesu ko ipa tìrẹ ninu jijiya ibi. Ko si eniyan kan ti nṣiṣẹsin bi ọmọ ogun ti nmu araarẹ̀ wọnu iṣẹ-aayan ìṣòwò, ki o baa le jèrè itẹwọgba ẹni naa ti o forukọ rẹ silẹ bii ọmọ ogun kan.” (2 Timoti 2:3, 4, NW) Afẹsẹrìn ọmọ ogun Romu kan ‘jiya ibi’ nigba ti o ba ngbe awọn ohun ija wiwuwo, aake, apẹ̀rẹ̀, ìwọ̀n ounjẹ fun ọjọ mẹta, ati awọn nnkan miiran. (Josephus’ Wars of the Jews, Ìwé kẹta, ori-iwe karun-un) Oun ko lepa awọn anfaani iṣẹ òwò, nitori pe iyẹn ko le tẹ ọ̀gá rẹ lọrun, inawo rẹ̀ ni a sì nbojuto. Lọna ti o farajọra, Kristian kan jiya awọn adanwo ti o sopọ mọ jijẹ “ọmọ ogun rere ti Kristi.” Bi o tilẹ jẹ pe oun le ṣiṣẹ ounjẹ oojọ lati mu awọn ohun aigbọdọmaṣe ti Iwe Mimọ ṣẹ, oun ko gbọdọ jẹ ki kikọwọnu nini awọn ohun ti ara lọna aiyẹ mu un dawọ jija ija ogun tẹmi duro. (1 Tẹsalonika 2:9) Ni jijẹrii lati ile de ile, oun fagbara lo “idà ẹ̀mí, eyiini ni, ọ̀rọ̀ Ọlọrun,” oun sì ṣèrànlọ́wọ́ lati da awọn eniyan silẹ lominira kuro lọwọ ìṣìnà isin. (Efesu 6:11-17, NW; Johanu 8:31, 32) Niwọnbi o ti mu ẹmi lọwọ, jẹ ki gbogbo awọn ọmọ ogun Kristian maa baa lọ lati tẹ Jesu Kristi ati Jehofa Ọlọrun lọrun ni ọ̀nà yii.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́