ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/01 ojú ìwé 7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Pípéjọpọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Tí Ó Bẹ̀rù Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 12/01 ojú ìwé 7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun

Ìtumọ̀ kan tá a lè fún ìbẹ̀rù ni “ọ̀wọ̀ pàtàkì tàbí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, pàápàá irú èyí tí ẹnì kan ní fún Ọlọ́run.” Ìyẹn jẹ́ ìbẹ̀rù lọ́nà yíyẹ tí Ìwé Mímọ́ pè ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” (Sm. 111:10) Ní ìdà kejì, oríṣi ìbẹ̀rù mìíràn ló gba ayé Sátánì tó yí wa ká kan. Báwo la ṣe lè yẹra fún irú ìbẹ̀rù tí kò yẹ bẹ́ẹ̀ bí a ti ń sapá láti mú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tó jinlẹ̀ dàgbà fún Jèhófà? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tuntun fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002 yóò dáhùn ìbéèrè yìí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ẹ Bẹ̀rù Ọlọ́run, Kí Ẹ sì Fi Ògo fún Un.” (Ìṣí. 14:7) A ó mọ ọ̀pọ̀ àǹfààní tí olúkúlùkù wa àti gbogbo wa lápapọ̀ bí ètò àjọ kan lè jẹ látinú bíbẹ̀rù Jèhófà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbẹ̀rù lè túmọ̀ sí ṣíṣàníyàn tàbí gbígbọ̀n jìnnìjìnnì àti kí èèyàn máa lọ́ra láti kojú ìṣòro, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà.” (Sm.128:1) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà yóò jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè borí àwọn ìṣòro tá a ń dojú kọ nítorí ìjọsìn tòótọ́. A óò rí bí a ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti mú irú ìbẹ̀rù yíyẹ bẹ́ẹ̀ dàgbà fún Ọlọ́run, èyí ní ti gidi yóò mú kí wọ́n fẹ́ láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn, èrò inú, àti okun wọn. (Máàkù 12:30) Ọjọ́ àkọ́kọ́ yóò wá sópin pẹ̀lú àsọyé tí ó ní àkọlé náà, “Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Ẹni Tí O Nífẹ̀ẹ́” èyí tí alábòójútó àgbègbè yóò sọ. Òun yóò ṣàlàyé bí a ṣe lè wà lójúfò láti dènà akitiyan Èṣù láti fà wá kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, lọ́dọ̀ ìdílé wa, àti lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa.

“Bẹ̀rù Jèhófà, Má Ṣe Bẹ̀rù Èèyàn” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpínsọ àsọyé alápá mẹ́rin tí a ó sọ ní ọjọ́ kejì. Àsọyé yìí á jẹ́ ká mọ ìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ fàyè gba ìbẹ̀rù èyíkéyìí tí ó lè ṣèdíwọ́ fún wa tá ò fi ní lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún tàbí tá ò fi ní lè ní ẹ̀rí ọkàn tó dára nílé ìwé àti lẹ́nu iṣẹ́, bákan náà á jẹ́ ká mọ bí a ò ṣe ní fàyè gbà á. Àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí a ó sọ náà, “Bẹ̀rù Ọlọ́run Kí O sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́,” la gbé ka àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra, àwọn tí a sọ nínú Ìṣípayá orí 14. Àpéjọ àyíká náà á wá sópin pẹ̀lú àsọyé tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ẹ Máa Bá A Lọ́ ní Rírìn Nínú Ìbẹ̀rù Jèhófà,” tí ó jẹ́ ìtọ́sọ́nà tó ń fúnni níṣìírí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àwòkọ́ṣe, àsọyé ìbatisí, àti àkópọ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tún wà lára àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà tí o kò ní fẹ́ kí wọ́n ròyìn fún ọ. Ké sí àwọn tí o ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti bá ọ wá. Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága kó tó pẹ́ jù. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù yíyẹ fún Jèhófà, a sì ń fi ògo fún un nípa ṣíṣàìtàsé apá èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ alárinrin yìí!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́