Pípéjọpọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Tí Ó Bẹ̀rù Ọlọrun
“ÀWỌN ènìyàn níbi gbogbo ń yánhànhàn fún òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù—ìbẹ̀rù ìwà-ipá, ìbẹ̀rù àìníṣẹ́lọ́wọ́, àti ìbẹ̀rù àìsàn lílekoko. Àwa pẹ̀lú ní irú ìyánhànhàn bẹ́ẹ̀. . . . Nígbà náà, èéṣe, tí a fi ń jíròrò nípa bí a ṣe lè mú ìbẹ̀rù dàgbà?” Ìbéèrè tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè yẹn ni olùbánisọ̀rọ̀ tí ó sọ lájorí ọ̀rọ̀-àwíyé gbé dìde ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun,” èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní June 1994.
Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn tí ó pésẹ̀—lákọ̀ọ́kọ́ ní North America, àti lẹ́yìn náà ní Europe, Central àti South America, Africa, Asia, àti àwọn erékùṣù òkun—háragàgà láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè mú irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ dàgbà. Èéṣe? Nítorí pé ṣíṣàjọpín nínú àwọn ìbùkún tí Jehofa Ọlọrun ní fún àwọn ènìyàn rẹ̀ sinmilórí níní tí a bá ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Àwọn olùpéjọpọ̀ náà kórajọ kí wọ́n baà lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbẹ̀rù Ọlọrun, wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ nípa ànímọ́ Kristian tí ó ṣekókó yìí, lákòókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà.
“Bẹ̀rù Ọlọrun Kí O Sì Pa Òfin Rẹ̀ Mọ́”
Ìyẹn ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà, tí a gbékarí Oniwasu 12:13. Kí ni ó túmọ̀ sí láti bẹ̀rù Ọlọrun? Nínú apá àkọ́kọ́ gan-an lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, alága àpéjọpọ̀ ṣàlàyé pé ìbẹ̀rù Ọlọrun ń ṣàgbéyọ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ ńlá tí ó jinlẹ̀ fún Jehofa títíkan ìfòyà gbígbámúṣé láti máṣe mú un bínú. Irú ìbẹ̀rù Ọlọrun bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ti ojora; ó ń fúnni ní ìlera ó sì yẹ.
Báwo ni ìbẹ̀rù tí ń fúnni ní ìlera yìí ṣe ń ṣàǹfààní fún wa? Ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, “Ẹ Máṣe Ṣàárẹ̀ Kí Ẹ Sì Juwọ́sílẹ̀,” ṣàlàyé pé ìbẹ̀rù Ọlọrun yóò sún wa láti pa àwọn òfin Ọlọrun mọ́ pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀. Bí a bá fi ìfẹ́ fún Ọlọrun àti fún aládùúgbò pẹ̀lú rẹ̀, irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ yóò fi okun tẹ̀mí kún inú wa. Bẹ́ẹ̀ni, ìbẹ̀rù Ọlọrun lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún dídẹ̀rìn nínú eré-ìje fún ìyè àìnípẹ̀kun.
Apá tí ó kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀rí tí ó ṣeé fojúrí pé ìbẹ̀rù Ọlọrun lè gbé wa ró. Àwọn tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ bí ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀-ńlá fún Ọlọrun ṣe mú kí wọ́n máa báa lọ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà láìka àìbìkítà, àgunlá, tàbí inúnibíni sí àti bí ó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo ìfaradà kódà lójú àwọn àdánwò lílekoko tí ó jẹ́ ti ara-ẹni.
Ṣùgbọ́n, èéṣe tí àwọn ènìyàn kan fi ní ìbẹ̀rù Ọlọrun tí àwọn mìíràn kò sì ní? Nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Mímú Ìbẹ̀rù Ọlọrun Dàgbà àti Jíjàǹfààní Láti Inú Rẹ̀,” olùbánisọ̀rọ̀ tí ó sọ lájorí ọ̀rọ̀-àwíyé náà ṣàlàyé pé ní Jeremiah 32:37-39, Jehofa ṣèlérí pé Òun yóò fi ọkàn-àyà tí ó ní ìbẹ̀rù Ọlọrun fún àwọn ènìyàn Òun. Jehofa ń gbin ìbẹ̀rù Ọlọrun sínú ọkàn-àyà wa. Báwo? Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ní ìmísí, Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ ṣe ìsapá aláápọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí a sì lo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí ó ti ṣe ní kíkún. Èyí wémọ́ àwọn àpéjọpọ̀ àti ìpàdé ìjọ wa, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ láti bẹ̀rù rẹ̀.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣílétí náà láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìjíròrò àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ó yẹ kí Ìjọba náà gbà ní ipa lórí ìgbésí-ayé wa gẹ́gẹ́ bí Kristian sì tẹ̀lé e.
Lẹ́yìn náà ni àkọ́kọ́ nínú àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé mẹ́ta tí a gbékalẹ̀ ní àpéjọpọ̀ náà tẹ̀lé e. “Ìbẹ̀rù Ọlọrun Ń Sún Wa Láti Ṣègbọràn sí Àwọn Ohun Tí Ọlọrun Béèrè Fún” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé yìí tí ó pa àfiyèsí pọ̀ sórí ìdílé. Èyí tí ó tẹ̀lé e yìí jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ìmọ̀ràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu—tí ó sì gbéṣẹ́—èyí tí ó fi fúnni.
□ Fún àwọn ọkọ: Ìbẹ̀rù Ọlọrun níláti sún ọkùnrin kan láti fẹ́ràn aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara òun tìkára rẹ̀. (Efesu 5:28, 29) Ọkùnrin kan kò jẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ pa ara òun tìkára rẹ̀ lára, tàbí kí ó tẹ́ ara rẹ̀ lógo níwájú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kò sì jẹ́ ṣòfófó nípa àwọn àìdójú-ìwọ̀n tirẹ̀ fúnra rẹ̀. Nítorí náà, iyì àti ọ̀wọ̀ tí ó ń bù fún ara rẹ̀ ni ó níláti bù fún aya rẹ̀.
□ Fún àwọn aya: Ìbẹ̀rù Ọlọrun tí Jesu ní sún un ‘láti máa ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun nígbà gbogbo.’ (Johannu 8:29, NW) Èyí jẹ́ ìtẹ̀sí-ọkàn tí ó dára fún àwọn aya láti ṣàfarawé nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn.
□ Fún àwọn òbí: Àwọn Kristian òbí lè fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn nípa fífi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú àwọn ẹrù-iṣẹ́ jíjẹ́ òbí, kí wọ́n máa wo àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ogún kan láti ọ̀dọ̀ Jehofa. (Orin Dafidi 127:3) Góńgó àkọ́kọ́ fún àwọn òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn láti di ojúlówó Kristian.
□ Fún àwọn ọmọ: Jehofa fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni láti ṣègbọràn sí “awọn òbí” wọn “ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa.” (Efesu 6:1, NW) Fún ìdí èyí, láti ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn jẹ́ láti ṣègbọràn sí Ọlọrun.
Ọ̀rọ̀-àsọyé àsọkágbá fún ti ọjọ́ náà gún ọkàn ní kẹ́ṣẹ́, nítorí pé ó jíròrò ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí gbogbo wa ń ní ìrírí rẹ̀ nígbà tí ikú bá mú olólùfẹ́ wa kan lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní apá ìdajì ọ̀rọ̀-àsọyé náà, ohun kan tí ó yanilẹ́nu ṣẹlẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà mú inú àwùjọ dùn nípa ṣíṣèfilọ̀ ìwé pẹlẹbẹ titun náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Ìwé olójú-ewé 32, tí ó ní àwọ̀ mèremère yìí sọ ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí ó lè ran àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ láti lóye kí wọ́n sì kojú àwọn ìmọ̀lára àti ìmí-ẹ̀dùn tí ó máa ń jẹ jáde lẹ́yìn ikú olólùfẹ́ kan. O ha ti fìgbà kan rí ṣe aláìmọ ohun tí o lè sọ fún ẹnì kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ bí? Ẹ̀ka-ìpín kan nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí jíròrò bí a ṣe lè ran àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́. Bí wọ́n ti ń fetísílẹ̀ sí olùbánisọ̀rọ̀ náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń bẹ nínú àwùjọ ń ronú nípa ẹnì kan tí ó lè jàǹfààní láti inú ìwé pẹlẹbẹ titun yìí.
‘Ṣe Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Pẹ̀lú Ìbẹ̀rù Ọlọrun àti Ìbẹ̀rù-Ọlọ́wọ̀’
Ìyẹn ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ́ kejì, tí a gbékarí Heberu 12:28. (NW) Nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti òwúrọ̀ ni àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé kejì, “Àwọn Ìjọ Tí Ń Rìn Ní Ìbẹ̀rù Jehofa” wáyé. Apá àkọ́kọ́ bójútó lílọ sí àwọn ìpàdé. Wíwà wa ní àwọn ìpàdé ń fi ọ̀wọ̀ wa fún Ọlọrun àti àwọn ìpèsè rẹ̀ tẹ̀mí hàn. Nípa lílọ, a ń fihàn pé a bẹ̀rù orúkọ rẹ̀ a sì ń háragàgà láti ṣègbọràn sí ìfẹ́-inú rẹ̀. (Heberu 10:24, 25) Olùbánisọ̀rọ̀ kejì ṣàlàyé pé fún gbogbo ìjọ lódidi láti rìn nínú ìbẹ̀rù Jehofa, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe ipa tirẹ̀ láti pa ìwà rere mọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ tí ó gbẹ̀yìn sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní àti ojúṣe tí gbogbo Kristian ní—láti polongo ìhìnrere náà láìjuwọ́sílẹ̀. Báwo ni a óò ti ṣe máa bá a nìṣó ní wíwàásù ìhìnrere náà pẹ́ tó? Títí di ìgbà tí Jehofa bá sọ pé ó tó.—Isaiah 6:11.
“Ìdùnnú-Ayọ̀ Jehofa Ni Odi Agbára Yín” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó tẹ̀lé e, gẹ́gẹ́ bí a ti kárí rẹ̀ nísinsìnyí nínú àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé ìròyìn yìí. (Nehemiah 8:10) Èéṣe tí àwọn ènìyàn Jehofa fi ń ní ìdùnnú-ayọ̀? Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìdí mélòókan. Ọ̀kan tí ó ṣe pàtàkì gan-an ni pé ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọrun ń mú kí a jẹ́ ènìyàn onídùnnú-ayọ̀ jùlọ lórí ilẹ̀-ayé. Olùbánisọ̀rọ̀ náà rán àwọn olùpéjọpọ̀ létí láti rò ó wò ná, a ní àǹfààní wíwà lára àwọn ènìyàn tí Jehofa ti fa súnmọ́ Jesu Kristi. (Johannu 6:44) Ẹ wo ìdí lílágbára tí ìyẹn jẹ́ fún wa láti ní ìdùnnú-ayọ̀!
Kókó ìtẹnumọ́ ní gbogbo àpéjọpọ̀ ní ìrìbọmi jẹ́, ti àwọn Àpéjọpọ̀ “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” kò sì yàtọ̀ rárá. Nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ìyàsímímọ́ àti Baptismu Ní Ìbẹ̀rù Jehofa,” olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣèrìbọmi pín sí apá mẹ́rin: (1) A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀ kí a sì fi í sílò; (2) a gbọ́dọ̀ gbàdúrà; (3) a gbọ́dọ̀ kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nínú àwọn ìpàdé ìjọ; a sì tún (4) gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí orúkọ Jehofa àti Ìjọba rẹ̀.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Saturday bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kókó-ẹ̀kọ́ tí ń múnilọ́kànle náà “Àwọn Ènìyàn Tí Jehofa Kò Ṣátì.” Ní ọ̀rúndún 35 sẹ́yìn, nígbà tí orílẹ̀-èdè Israeli dojúkọ àwọn àkókò lílekoko, Jehofa fún wọn ní ẹ̀rí ìdánilójú nípasẹ̀ Mose, ní sísọ pé: “OLUWA Ọlọrun rẹ . . . kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kọ̀ ọ́.” (Deuteronomi 31:6) Jehofa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ìdánilójú yẹn nípa dídáàbòbo àwọn ọmọ Israeli nígbà tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n sì gbà á. Lónìí, nígbà tí a bá ń dojúkọ àwọn àdánwò lílekoko, àwa pẹ̀lú lè ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Jehofa kì yóò kọ̀ wá tì, bí a bá faramọ́ ọn tímọ́tímọ́ tí a sì kọbiara sí ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Báwo ni o ṣe lè rí ìdùnnú láti inú kíka Bibeli? Nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ka Bibeli Mímọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Lójoojúmọ́,” olùbánisọ̀rọ̀ náà dábàá pé kí a máa kà á pẹ̀lú ọkàn tí ń wádìí ọ̀ràn wò kí a sì máa béèrè àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Kí ni àkọsílẹ̀ yìí ń kọ́ mi nípa àwọn ànímọ́ Jehofa àti ọ̀nà rẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ dàbíi Jehofa ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí? Kíka Bibeli ní ọ̀nà yìí jẹ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni tí ń mérè wá.
Lẹ́yìn náà ni a wá darí àfiyèsí sí àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé kẹta lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, “Àwọn Ìpèsè Láti Ran Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Bẹ̀rù Jehofa Lọ́wọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa lè má ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nítorí ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí, ó dájú pé ó ń nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀. (2 Peteru 2:9) Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé yìí ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìpèsè mẹ́rin láti ọ̀dọ̀ Jehofa láti ràn wá lọ́wọ́ ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí: (1) Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Jehofa ń fún wa ní agbára láti ṣe àṣeparí àwọn iṣẹ́ tí ó ju agbára wa lọ fíìfíì. (2) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ń pèsè ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà fún wa. (3) Nípasẹ̀ ìràpadà, ó ń fún wa ní ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní. (4) Nípasẹ̀ ètò-àjọ rẹ̀, títíkan àwọn alàgbà, ó ń pèsè ìdarísọ́nà àti ìdáàbòbò fún wa. (Luku 11:13; Efesu 1:7; 2 Timoteu 3:16; Heberu 13:17) Nípa lílo gbogbo ìpèsè wọ̀nyí ní kíkún, yóò ṣeé ṣe fún wa láti lo ìfaradà kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ jèrè ìtẹ́wọ́gbà Jehofa.
Ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó gbẹ̀yìn ní ọ̀sán Saturday, tí a gbékarí àsọtẹ́lẹ̀ Malaki ni a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ọjọ́ Jehofa Tí Ń Múnikún-fún-Ẹ̀rù Ti Ń Súnmọ́lé.” Àwọn ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù ti wáyé rí nínú ìtàn, bí ó ti rí nígbà tí a mú ìdájọ́ ṣẹ sórí Jerusalemu ní 70 C.E. Ṣùgbọ́n ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù jùlọ nínú gbogbo ìrírí ẹ̀dá ènìyàn yóò jẹ́ ọjọ́ Jehofa tí ń bọ̀wá nígbà tí ‘a óò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí awọn wọnnì tí kò mọ Ọlọrun ati awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere nipa Jesu Oluwa wa.’ (2 Tessalonika 1:6-8, NW) Báwo ni ìyẹn yóò ti yá tó? Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Òpin ti súnmọ́lé! Jehofa mọ ọjọ́ àti wákàtí náà. Òun kì yóò yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò rẹ̀ padà. A késí wa láti fi sùúrù faradà á.”
Ó ṣòro láti gbàgbọ́ pé ọjọ́ méjì ti yára kọjá. Kí ni ọjọ́ tí ó gbẹ̀yìn yóò mú wá?
“Ẹ Bẹ̀rù Ọlọrun Kí Ẹ Sì Fi Ògo Fún Un”
Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ́ kẹta ni a gbékarí Ìṣípayá 14:7. (NW) Lákòókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀, ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé tẹnumọ́ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí ó fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa hàn yàtọ̀ sí gbogbo ètò ìsìn yòókù.
Nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Àjíǹde Àwọn Olódodo Yóò Wà,” olùbánisọ̀rọ̀ gbé ìbéèrè kan tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè dìde pé: “Lákòókò Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún yẹn, nígbà wo ni àwọn wọnnì tí wọ́n kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ní àwọn ọdún tí ó gbẹ̀yìn fún ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Satani yìí yóò jíǹde?” Kí ni ìdáhùn? Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé: “Bibeli kò sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kò ha bọ́gbọ́nmu pé àwọn wọnnì tí wọ́n kú ní ọjọ́ wa ní a óò tètè jíǹde kí wọ́n baà lè ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n la Armagedoni já nínú arabaríbí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí yóò wáyé títí jálẹ̀ Ọjọ́ Ìdájọ́? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́!” Àwọn olùlàájá yóò ha wà bí? Ó dájú pé wọn yóò wà. Àwọn ẹ̀kọ́ àti àpẹẹrẹ Bibeli tí ó mú èyí dánilójú ni a ṣàlàyé ní kedere nínú ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, “A Pa Wọ́n Mọ́ Láàyè La Ìpọ́njú Ńlá náà Já.”
Láti ìgbà pípẹ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti lóye rẹ̀ pé kádàrá méjì ni Bibeli nawọ́ rẹ̀ síni—ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise orí ilẹ̀-ayé fún ọ̀kẹ́ àìmọye àti ìwàláàyè àìlèkú ní òkè ọ̀run fún ìwọ̀nba àwọn ènìyàn tí wọn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. Ìrètí ti òkè ọ̀run ní a jíròrò nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Má Bẹ̀rù, Agbo Kékeré.” (Luku 12:32, NW) Níbi tí ipò ayé báa dé nísinsìnyí, agbo kékeré náà gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìbẹ̀rù; ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn gbọ́dọ̀ faradà á títí dé òpin. (Luku 21:19) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Jíjẹ́ aláìbẹ̀rù wọn ń ṣiṣẹ́ láti fún àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ní ìṣírí. Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ mú ìṣarasíhùwà àìbẹ̀rù dàgbà bí wọ́n ti ń fojúsọ́nà fún ìdáǹdè wọn lákòókò ìjọ̀ngbọ̀n títóbi jùlọ tí ayé tí ì rírí.”
Ní ìparí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀, àwùjọ náà fi ìdùnnú wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà Àwọn Yíyàn Tí Ìwọ Dojúkọ. Ní àwọn ọjọ́ Joṣua, àti ti wòlíì Elija pẹ̀lú, àwọn ọmọ Israeli dé orí kókó ìṣèpinnu. Wọ́n níláti ṣe ìpinnu kan. Elija wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó máa ṣiyèméjì? Bí Oluwa bá ni Ọlọrun, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: ṣùgbọ́n bí Baali bá ni ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” (1 Awọn Ọba 18:21) Lónìí, pẹ̀lú, aráyé ti dé orí kókó ìṣèpinnu. Àkókò kọ́ nìyí láti máa ṣe kámi-kàmì-kámi. Kí ni yíyàn tí ó tọ̀nà? Irú yíyàn kan náà tí Joṣua ìgbàanì ṣe ni. Ó wí pé: “Bí ó ṣe ti èmi àti ilé mi ni, OLUWA ni àwa ó máa sìn.”—Joṣua 24:15.
Bí ẹni pé lójijì, ọ̀sán pọ́n ní ọjọ́ Sunday àkókò sì tó fún ọ̀rọ̀-àwíyé fún gbogbo ènìyàn tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìdí Tí A Fi Níláti Bẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́ náà Nísinsìnyí.” Nínú Ìṣípayá 14:6, 7 (NW), a rọ gbogbo aráyé pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un.” Èéṣe tí ó fi jẹ́ kánjúkánjú láti bẹ̀rù Ọlọrun nísinsìnyí? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ náà ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, “wákàtí ìdájọ́ lati ọwọ́ rẹ̀ ti dé.” Nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, tí a ti gbégorí ìtẹ́ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun ní òkè ọ̀run, Jehofa yóò mú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan aláìmọ́, ọlọ̀tẹ̀ ti ìsinsìnyí wá sí ìparí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé èyí ni ọ̀nà kanṣoṣo náà tí a lè gbà mú ìtura wá fún àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun àti ọ̀nà tí a lè gbà yọ ilẹ̀-ayé tí ó jẹ́ ilé wa nínú ewu kí a sì pa á mọ́. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé apá tí ó gbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ni a wà yí, ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí a bẹ̀rù Ọlọrun òtítọ́ náà nísinsìnyí!
Lẹ́yìn àkópọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà fún ti ọ̀sẹ̀ yẹn, olùbánisọ̀rọ̀ tí ó gbẹ̀yìn gorí pèpéle. Ó ṣàlàyé pé, nítorí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà, ìbẹ̀rù Ọlọrun ti gbé ìtumọ̀ tí ó túbọ̀ ga síi rù fún àwọn olùpéjọpọ̀ náà. Ó tẹnumọ́ àwọn àǹfààní púpọ̀ tí àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun ń jẹ. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣèfilọ̀ ìmújáde fídíò titun—United by Divine Teaching. Ó tẹnumọ́ àwọn apá títayọ nínú àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbáyé ti “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” tí a ṣe ní 1993 sí 1994. Bí ọ̀rọ̀àsọyé náà ti ń parí lọ, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni a lè máa fojúsọ́nà fún ní ọdún tí ń bọ̀?’ Àpéjọpọ̀ àgbègbè ọlọ́jọ́-mẹ́ta ní ibi púpọ̀.
Ní ìparí, olùbánisọ̀rọ̀ náà pàfiyèsí sí Malaki 3:16, èyí tí ó sọ pé: “Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nígbàkugbà; Oluwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́, a sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa, tí wọ́n sì ń ṣe àṣàrò orúkọ rẹ̀.” Àwọn olùpéjọpọ̀ náà fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu tí ó ṣe kedere láti ronú lórí orúkọ Jehofa àti láti ṣiṣẹ́sìn ín pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọrun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn olùnàgà fún àǹfààní ìrìbọmi gbọ́dọ̀ máa fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn nìṣó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà “Àwọn Yíyàn Tí Ìwọ Dojúkọ” tẹ àìní náà láti ṣe ìpinnu pàtó nípa ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa mọ́ àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ lọ́kàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Inú àwọn olùpéjọpọ̀ dùn láti gba ìwé pẹlẹbẹ titun náà “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú”