Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò láìṣí ìwé wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 4 sí December 18, 2000. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Dáfídì kò jẹ́ kí Ábíṣáì pa Ṣíméì nítorí pé Dáfídì jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí Ṣíméì fi kàn án. (2 Sám. 16:5-13) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-E 5/1 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 3.]
2. Kì í ṣe pé ẹ̀rí ọkàn tí a kọ́ dáradára tí ó sì mọ́ ń mú ká ní àjọṣe onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún pọn dandan fún ìgbàlà wa. (Héb. 10:22; 1 Pét. 1:15, 16) [w98-YR 9/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 4]
3. Kò ṣeé ṣe láti lóye Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní kíkún àyàfi bí a bá mọ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. [w85-YR 5/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 4]
4. Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù ni a lè fi wéra pẹ̀lú ogójì ọdún ìṣàkóso Sólómọ́nì tó kún fún àlàáfíà àti aásìkí. (1 Ọba 4:24, 25, 29) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 6/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 5.]
5. Òkú Ábíjà tí a sin lọ́nà tó bójú mu jẹ́ ẹ̀rí ṣíṣe kedere pé ó jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo tó wá láti ilé Jèróbóámù tó fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà. (1 Ọba 14:10, 13) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 4/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 11.]
6. Pé ẹnì kan ni a ti batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kan túmọ̀ sí pé ẹni náà ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó dàgbà dénú. [w98-YR 10/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 2]
7. Jèhófà fún Èlíjà ní ìgboyà tó kọjá ohun tí ẹ̀dá lè ní, ó sì dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. (1 Ọba 18:17, 18, 21, 40, 46) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2.]
8. Kìkì nítorí àtirí ọrọ̀ Sólómọ́nì ni ọbabìnrin Ṣébà fi rìnrìn àjò jíjìnnà wá sí Jerúsálẹ́mù. [w85-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
9. Ìfọ́jú tí a mú wá sórí agbo ọmọ ogun Síríà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó tẹnu Èlíṣà wá dájúdájú jẹ́ ìfọ́jú inú, níwọ̀n bó ti ṣeé ṣe fún wọn láti rí Èlíṣà, àmọ́ tí kò ṣeé ṣe fún wọn láti mọ̀ pé òun ni. (2 Ọba 6:18, 19) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 70 àti 71 ìpínrọ̀ 10.]
10. Gbígbé “Gbólóhùn Ẹ̀rí” èyí ti a mẹ́nu kan ní 2 Àwọn Ọba 11:12 wọ̀ wulẹ̀ jẹ́ ìṣe àyẹ́sí kan ni, èyí tó ń ṣàpèjúwe pé ìtumọ̀ tí ọba bá fún Òfin Ọlọ́run òun náà la gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gbà tí a sì gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 6.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
11. Níbàámu pẹ̀lú 1 Jòhánù 2:15-17, kí ló yẹ káwọn òbí tó ka òfin Ọlọ́run sí rọ àwọn ọmọ wọn láti yàgò fún nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ wọn sọ́nà nínú yíyan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó bójú mu? [w98-YR 7/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3]
12. Kí ni ohun tó wà nínú 2 Sámúẹ́lì 18:8, èyí tó sọ pé: “Igbó ṣe èyí tí ó pọ̀ ní jíjẹ àwọn ènìyàn náà run ju èyí tí idà ṣe” túmọ̀ sí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-E 3/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2.]
13. Àwọn wo lónìí la lè fi wé àwọn ìbátan Gòláyátì tó jẹ́ ọkùnrin, ìyẹn àwọn Réfáímù, kí ni wọ́n sì ń tiraka láti ṣe? (2 Sám. 21:15-22) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 1/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 8.]
14. Àwọn wo ló yẹ kó jàǹfààní jù látinú ìlànà Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbọràn èyí tó wà ní 1 Sámúẹ́lì 15:22, 23? [w85-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5]
15. Ìlànà pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọkùnrin tí a pa fún rírú òfin Sábáàtì? (Núm. 15:35) [w98-YR 9/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2]
16. Nípa ṣíṣe kí ni a fi lè fára wé ọbabìnrin Ṣébà, ẹni tó rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn láti wá gbọ́ “ọgbọ́n Sólómọ́nì”? (1 Ọba 10:1-9) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 7/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 àti 2.]
17. Níbàámu pẹ̀lú 1 Àwọn Ọba 17:3, 4, 7-9, 17-24, ọ̀nà mẹ́ta wo ni Èlíjà gbà fi ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà hàn? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 4/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 4.]
18. Kí ló dé tí kíkọ̀ tí Nábótì kọ̀ láti yọ̀ǹda ọgbà àjàrà rẹ̀ fún Áhábù kò ṣe fi hàn pé olóríkunkun èèyàn ni? (1 Ọba 21:2, 3) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 8/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 18.]
19. Ọ̀nà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Àwọn Ọba 6:16 ti gbà fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níṣìírí lónìí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 6/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 5.]
20. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí gbà fi yẹra fún ríra ipò? [w98-YR 11/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 5]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí __________________________ borí òun, kí ó sì tìtorí bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò wu __________________________. (Òwe 29:25; Mát. 10:28) [w98-YR 7/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 5]
22. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jẹ́rìí níwájú Àgírípà Ọba, ó lo __________________________, ní títẹnu mọ́ àwọn kókó tí òun àti Àgírípà __________________________. (Ìṣe 26:2, 3, 26, 27) [w98-YR 9/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]
23. Nítorí tí a __________________________ Ọlọ́run, àwọn kan lè rò pé kì í ṣe ẹni gidi, àmọ́ ṣíṣe __________________________ déédéé tó sì tún jinlẹ̀ yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti “rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:27) [w98-YR 9/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
24. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ọ̀ràn __________________________, ọ̀gágun Síríà, nígbà míì __________________________ díẹ̀ lè yọrí sí èrè ńlá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 2/1 ojú ìwé 3 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 1.]
25. Gẹ́gẹ́ bí ọkàn àyà Jèhónádábù ti wà pẹ̀lú ti Jéhù Ọba, __________________________ náà lónìí ń fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba Jéhù Títóbi jù náà, __________________________, tí àwọn __________________________ ń ṣojú fún lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. (2 Ọba 10:15, 16) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 1/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 5 àti 6.]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. (Sátánì; Jèhófà; Jóábù) ló sún Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ nípa ‘kíka iye Ísírẹ́lì.’ (2 Sám. 24:1) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 7/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2.]
27. Níbàámu pẹ̀lú 1 Àwọn Ọba 8:1 àti Oníwàásù 1:1, Sólómọ́nì kó àwọn ènìyàn jọ láti (kọ́ tẹ́ńpìlì; lé àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì dà nù; jọ́sìn Jèhófà). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 3.]
28. Sáà ogún ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ tẹ́ńpìlì àti ilé rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ni a lè fi wéra pẹ̀lú sáà àtúnṣe nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti ti ètò àjọ, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní (1919; 1923; 1931) tó sì wá sópin ní (1938; 1942; 1950). (1 Ọba 9:10) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 3/1 àpótí ojú ìwé 20.]
29. Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó ní 2 Àwọn Ọba 2:11 ń tọ́ka sí (ibi ẹ̀mí tí Ọlọ́run ń gbé; àgbáálá ọ̀run tí a lè fojú rí; àyíká tó sún mọ́ ayé, níbi táwọn ẹyẹ ti ń fò, tí afẹ́fẹ́ sì ń fẹ́ níbẹ̀.) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 9/15 àpótí ojú ìwé 15.]
30. (Hẹ́rọ́dù Ńlá; Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì; Tìbéríù Késárì) ni ẹni tó pàṣẹ ìkànìyàn, èyí tó wá yọrí sí bíbí tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù dípò tí ì bá fi jẹ́ ní Násárétì. [w98-YR 12/15 àpótí ojú ìwé 7]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sí ìsàlẹ̀ yìí:
Sm. 15:4; 2 Sám. 12:28; 2 Sám. 15:18-22; 2 Ọba 3:11; Kól. 3:13
31. A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ipò orí nínú ìṣètò ìṣàkóso ti Jèhófà. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 63 ìpínrọ̀ 30]
32. Ìdúróṣinṣin wa ti ètò àjọ Jèhófà àti àwọn tó ń ṣojú fún un gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 63 ìpínrọ̀ 30]
33. Mímọrírì àánú Jèhófà lè sún ẹnì kan láti ṣàkóso ara rẹ̀ kó sì gbójú fo àwọn àbùkù dá. [w98-YR 11/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3]
34. Àǹfààní ló jẹ́ láti fi aájò àlejò hàn sí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn àkànṣe ká sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ fún wọ́n. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 11/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1.]
35. Ẹnì kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run á ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dúró ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti san gbèsè tó jẹ, kódà bí àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ bá tiẹ̀ mú kí nǹkan ṣòro ju ohun tó lérò tẹ́lẹ̀ lọ. [w98-YR 11/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1]