ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 12/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 11

Orin 50

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Bí ìjọ bá ní àwọn ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ tàbí ìwé Olukọ Nla, sọ bí a ṣe lè lò wọ́n dáadáa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò ọlidé. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti wo fídíò The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò rẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ December 25. Àwọn tí wọ́n ní fídíò náà lè fún àwọn tí kò ní láti wò ó, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jọ wò ó pa pọ̀.

15 min: “Máa Ní Ìbẹ̀rù Jèhófà Lọ́kàn Lọ́jọ́ Gbogbo.”a Fi àlàyé nípa ìbẹ̀rù Ọlọ́run kún un, èyí tí ó wà lójú ìwé 26 nínú Jí! January 8, 1998. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní gbígbámúṣé tó wà nínú níní ìbẹ̀rù Jèhófà lọ́kàn.

20 min: “Má Ṣe Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ṣohun Tẹ́gbẹ́ Ń Ṣe Ní Ipa Lórí Àǹfààní Tí O Ní Láti Wàásù.” Àsọyé àti àwọn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò. Ké sí àwọn kan lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti kojú ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe pé kí wọ́n sọ ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà tí wọ́n fi lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìwàásù láìka ohun tí wọ́n kojú sí.

Orin 78 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 18

Orin 94

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Sọ àwọn ètò àkànṣe tó wà fún iṣẹ́ ìsìn pápá nínú oṣù December 25 àti January 1. Dáhùn ìbéèrè yìí: Ǹjẹ́ ó burú ká kópa nínú àwọn ayẹyẹ tó ṣeé ṣe kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni níwọ̀n ìgbà tí kì í bá ṣe nítorí ìsìn ni wọ́n fi ń ṣe é?—Wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 178 sí 180.

12 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2001.” Àsọyé tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí pé kí wọ́n máa bá Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nìṣó, kí wọ́n sì máa sapá láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wọn ní ilé ẹ̀kọ́.

18 min: “Ǹjẹ́ O Ń Wàásù Láìṣojo?”b Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Nípa lílo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 86, ṣàlàyé bí a ṣe lè túbọ̀ jẹ́ aláìṣojo kí a sì túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.

Orin 124 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 25

Orin 126

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ pé kí àwùjọ sọ ìrírí èyíkéyìí tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣàyẹ̀wò ìwé tí a óò fi lọni ní oṣù January.

10 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe ìfilọ̀ déètì tí ẹ óò ṣe àpéjọ àyíká tó ń bọ̀, kí o sì rọ gbogbo ìjọ láti lọ lọ́jọ́ méjèèjì. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n sapá lákànṣe láti ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn wá. Bí wọ́n bá lọ sí àpéjọ náà, ó lè mú kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé.

25 min: “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Fídíò Náà, The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fún àwùjọ nímọ̀ràn lórí bí a ṣe lè fi fídíò yìí sún àwọn ẹlòmíràn gbégbèésẹ̀. (1999 Yearbook, ojú ìwé 51 àti 52) Ní oṣù February, a óò ṣàyẹ̀wò fídíò kejì nínú ọ̀wọ́ yìí, èyí tó ń jẹ́ The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book.

TÀBÍ: “Ìdí Tóo Fi Lè Gbára Lé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.” Àsọyé àti ìlóhùnsí àwùjọ, tí a gbé karí àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, July 15, 1999, ojú ìwé 4 sí 8.

Orin 151 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 1

Orin 171

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Bí ìjọ yín yóò bá yí àwọn àkókò tí ẹ ń ṣe ìpàdé padà lọ́dún tuntun, fi pẹ̀lẹ́tù rọ gbogbo ìjọ pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé déédéé ní àwọn àkókò tí a yí wọn padà sí. Ẹ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn yòókù nípa ìyípadà èyíkéyìí tó bá ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ìwé ìléwọ́ tó ń fi ìṣètò tuntun náà hàn. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣù August ti orílẹ̀-èdè yìí àti ti ìjọ yín. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù December sílẹ̀.

12 min: Bí A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìpadàbẹ̀wò. Bàbá kan bá ìdílé rẹ̀ jíròrò nípa bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ máa méso jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ó tẹnu mọ́ àwọn ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó fi yẹ láti máa padà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó bá fi ìfẹ́ hàn. Nípa lílo àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, July 1, 1999, ojú ìwé 22, ìpínrọ̀ 18, wọ́n múra sílẹ̀ láti lọ ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò kan. Gbogbo wọn gbà pé àwọn ti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn kan tẹ́lẹ̀ tó yẹ kí àwọn tún ṣèbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ wọn. Olúkúlùkù wọn ṣàpèjúwe bí ẹni tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ṣe nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn mìíràn nínú ìdílé sì dábàá ohun tí yóò sọ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí yóò lò nígbà tó bá ṣe ìpadàbẹ̀wò síbẹ̀. Wọ́n wá àwọn kókó kan nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, èyí tí wọ́n lè lò lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àwọn òbí yìí jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn fi ohun tí yóò sọ nígbà tó bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò dánra wò. Wọ́n wéwèé àkókò kan pàtó láti lọ ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

25 min: “Àyẹ̀wò Tó Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Ìjẹ́kánjúkánjú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5, 10, àti 11. Ṣàyẹ̀wò bí iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń tẹ̀ síwájú ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Rọ gbogbo àwọn tó ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kí wọ́n ka àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996 lẹ́ẹ̀kan sí i kí wọ́n lè mú kí òye ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn túbọ̀ pọ̀ sí i. Jíròrò ìpínrọ̀ 5 àti 25 nínú àkìbọnú yẹn.

Orin 212 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́