ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 7/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 11

Orin 49

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! August 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! August 8.) Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará rí onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kojú ọ̀rọ̀ tó máa ń bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Ìyẹn ọ̀rọ̀ bíi, “Ọwọ́ mi dí.”—Wo Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 11 sí 12.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Mímú Ìhìn Rere Náà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Àwọn Tá A Bá Lè Rí.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2005, ojú ìwé 8.

Orin 88 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 18

Orin 173

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, jíròrò Ilé Ìṣọ́ August 15, 2000 ojú ìwé 32. Ṣàlàyé àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní ìṣètò kíka Bíbélì lójoojúmọ́ láìtàsé kódà nígbà ọludé àti láwọn ìgbà míì tọ́wọ́ bá dilẹ̀.

15 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kọkànlá.”b Ṣé àṣefihàn bí olùkọ́ ṣe ń kọ́ akéde tuntun bó ṣe máa ṣe ìpadàbẹ̀wò. Wọ́n jíròrò ohun tó bá onílé náà sọ nígbà tó kọ́kọ́ wàásù fún un, wọ́n wá pinnu kókó tó máa fa ẹni yẹn mọ́ra èyí tí wọ́n á sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà ìpadàbẹ̀wò. Wọ́n tún múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí àti ìbéèrè kan tó máa béèrè tó bá fẹ́ kádìí ìjíròrò náà. Ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ṣe ìdánrawò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n múra ni àṣefihàn náà máa parí sí.

20 min: Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Fọwọ́ Pàtàkì Mú Bíbélì. Ìbéèrè àti Ìdáhùn pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 24 sí 25, ìpínrọ̀ 3 sí 6. Ìbéèrè tó wà nínú ìwé náà ni kó o lò. Fi àlàyé kún un látinú ìwé pẹlẹbẹ náà Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 32.

Orin 10 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 25

Orin 138

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó, kó o sì tún ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu), láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! August 8. (Lo àbá kẹrin fún Jí! August 8.) Ẹ lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn láìjẹ́-bí-àṣà láàárín ọjà tàbí níbi kan tó bójú mu làwọn ibí térò máa ń pọ̀ sí.

10 min: Gbin Òtítọ́ sí Ọmọ Rẹ Lọ́kàn. (Diu. 6:7) Kí alàgbà kan sọ àsọyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí tá a gbé karí Ilé Ìṣọ́ August 15, 2002 ojú ìwé 30 sí 31. Ṣàlàyé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ atọ́nà nípa bí òbí tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè tọ́ ọmọ bí ẹnì kejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí.

20 min: “Gbèsè Tá A Jẹ Àwọn Èèyàn.”c Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2000, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 13.

Orin 82 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 1

Orin 187

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù July sílẹ̀. Ní kí àwọn ará ṣí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run wọn sí ojú ìwé 70, kó o wá fi ṣe ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàyẹ̀wò ìpínrọ̀ 1 sí 2 àti àpótí náà, “Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Máa Dáhùn Nípàdé.”

15 min: “Bó O Ṣe Lè Mú Káwọn Ọmọ Rẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣe àṣefihàn bí òbí kan ṣe ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó ṣe ṣókí. Ní ìparí àṣefihàn náà, ni kí òbí yẹn ṣàlàyé ṣókí nípa báwọn èèyàn ṣe lè fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn.

15 min: Ṣé Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó Bá Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Mu Lo Máa Ń Lò? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January 2005, ojú ìwé 5. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá tó wà lójú ìwé náà kó o sì ṣàṣefihàn bẹ́ ẹ ṣe máa lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu nígbà tẹ́ ẹ bá ń lo ìwé ìròyìn tá a dábàá fún lílò lóṣù August. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.

Orin 218 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́