Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ June 15
“Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló máa ṣiṣẹ́ dọjọ́ alẹ́. Àdúrà làwọn kan ka ìyẹn sí, bẹ́ẹ̀ lójú àwọn míì, èpè ló jọ. Ngbọ́ kí lo ti rò ó sí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 2:24.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ bí Bíbélì ṣe lè mú ká ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́. Ó tún jíròrò bá a ṣe lè fàyà rán ságbàsúlà níbi iṣẹ́.”
Ile Iṣọ July 1
“Gbogbo wa la mọ àwọn èèyàn kan tó dà bíi pé wọ́n rí já jẹ, síbẹ̀ táwọn fúnra wọn ṣì máa ń ráhùn pé nǹkan kan ṣì ń jẹ àwọn níyà. Kí lo rò pé ó kù tí wọ́n tún ń wá? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Mátíù 5:3.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun pàtàkì kan tá a lè ṣe ká lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìyẹn ni títẹ́ àìní tẹ̀mí wa lọ́rùn.”
Jí July 8
“Ǹjẹ́ o rò pé àdúgbò wa yìí á túbọ̀ ṣeé gbé tó bá jẹ́ pé gbogbo wa là ń fi ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ kà yìí ṣèwà hù? [Ka Éfésù 4:28. Kó o wá ní kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí àdánù tí ṣíṣàfọwọ́rá ń fà fún gbogbo wa ṣe pọ̀ tó. Ó tún sọ bí a ò ṣe ní gbúròó àfọwọ́rá àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì mọ́ láìpẹ́.”
“Nítorí báwọn tó ń wá iṣẹ́ ṣe pọ̀ tó lóde òní, àtiríṣẹ́ ti dogun. Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan márùn-ún tó lè mú kéèyàn rí iṣẹ́. [Fa kókó tó wà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó dúdú yàtọ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà “Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́,” yọ.] Ó tún dábàá àwọn ohun tá a lè ṣe tí iṣẹ́ ò fi ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.” Ka Òwe 22:29, bá a ṣe kọ ọ́ sójú ìwé 10.