Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 27, 2005. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ May 2 sí June 27, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí nìdí tí lílo àfiwé tààrà àti àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ fi jẹ́ ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó wúlò púpọ̀? (Jẹ́n. 22:17; Sm. 1:3; Ják. 3:6) [be-YR ojú ìwé 240 ìpínrọ̀ 2 sí 4, àti àpótí]
2. Ibo la ti lè rí àwọn àpẹẹrẹ tá a lè fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún tá a bá ń lo àpẹẹrẹ lọ́nà yìí? [be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
3. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń yan àpèjúwe tó múná dóko? [be-YR ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àwọn ohun tá a lè fojú rí nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, báwo sì ni Jèhófà ṣe lò ó? [be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 1 àti 2 àti àpótí]
5. Báwo la ṣe lè lo àwọn ohun tá a lè fojú rí láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní òde ẹ̀rí? [be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 249 ìpínrọ̀ 2]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Ìlànà wo ló wà ninú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa kíkọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́? [w03-YR 3/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3]
7. Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí Dáfídì tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé, báwo sì ni Dáfídì náà ṣe fìfẹ́ hàn sí Jèhófà? [w03-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]
8. Kí nìdí tí Jèhófà fi ka ẹbọ tí Ébẹ́lì rú sí, kí sì lèyí mú dá wa lójú? (Jẹ́n. 4:4) [3, w03-YR 5/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]
9. Kí ni “ìbáwí Jèhófà” tí Òwe 3:11 sọ fún wa pé ká má ṣe kọ̀? [6, w03-YR 10/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
10. Kí ni ìtumọ̀ “ẹ̀mí ohun-moní-tómi” bá a ṣe lò ó nínú 1 Tímótì 6:6-8? [w03-YR 6/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 àti 2 àti ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí ni ìfẹ́ tó lágbára, èyí tó so Jónátánì àti Dáfídì pọ̀ ṣàpẹẹrẹ? (2 Sám. 1:26) [w89-YR 1/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 13]
12. Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì kọ́kọ́ gbìyànjú láti gbé àpótí májẹ̀mú lọ sí Jerúsálẹ́mù kọ́ wa? (2 Sám. 6:2-9)
13. Níwọ̀n bí Diutarónómì 24:16 àti Ìsíkíẹ́lì 18:20 ti sọ pé ọmọ ò lè kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀, kí nìdí tí ọmọ tí Bátíṣébà bí fún Dáfídì fi kú nígbà tó jẹ́ pé Dáfídì àti Bátíṣébà ló dẹ́ṣẹ̀? (2 Sám. 12:14; 22:31)
14. Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí Síbà sọ pé Mẹfibóṣẹ́tì ṣe kì í ṣe òótọ́? (2 Sám. 16:1-4)
15. Síbà fọ̀rọ̀ èké ba Mẹfibóṣẹ́tì jẹ́. Kí nìdí tí ohun tí Mẹfibóṣẹ́tì ṣe lákòókò náà fi jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé? (2 Sám. 19:24-30)