Mímú Ìhìn Rere Náà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Àwọn Tá A Bá Lè Rí
1. Kí láwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe kí wọ́n báa lè wàásù ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí wọ́n bá lè rí?
1 Taratara làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri ibi gbogbo. Wọ́n ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe láti rí i pé àwọn wàásù ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí wọ́n bá lè rí. Èdè Gíríìkì tó wà lẹ́nu àwọn aráàlú tó sì jẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Ọba Róòmù làwọn Kristẹni òǹkọ̀wé Bíbélì fi kọ Ìwé Mímọ́. Síwájú sí i, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn oníwàásù tó fi ìtara ṣiṣẹ́ láti bí ọ̀rúndún kejì sí ìkẹta ló kọ́kọ́ lo ìwé àfọwọ́kọ alábala, ìyẹn codex, tó rọrùn láti fi ṣèwádìí ju àkájọ ìwé lọ.
2, 3. (a) Ọ̀nà wo ni Aísáyà 60:16 ń gbà nímùúṣẹ lóde òní? (b) Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti fi mú ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú?
2 Lílo Ẹ̀rọ Ìgbàlódé: Jèhófà gba ẹnu wòlíì Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu.” (Aísá. 60:16) Lóde òní, ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí gbà ṣẹ ni báwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń lo àwọn ohun èèlò wíwúlò tó wá látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè láti fi mú iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1914, nígbà tí kò tíì sí sinimá tó ń gbé ohùn jáde, làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí fi “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló tipasẹ̀ wíwo àwòrán tó ń kọjá lára ògiri àti sinimá oníwákàtí mẹ́jọ tó ń gbé ohùn àtàwòrán mèremère jáde gbọ́ ìwàásù.
3 Ní ojúmọ́ tó mọ́ lónìí, àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ayára bí àṣá àtàwọn ẹ̀rọ tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ ni wọ́n fi ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Àwọn ohun ìrìnnà ti mú kó ṣeé ṣe láti máa yára kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dé òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ibi jíjìnnà réré lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà ti fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti lè lo ẹ̀rọ ìgbàlódé fún mímú kí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì dé etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn tó pọ̀ débi tá ò tíì rírú ẹ̀ rí.
4. Ìyípadà wo làwọn kan ṣe nínú ìgbé ayé wọn kí wọ́n bàa lè mú ìhìn rere dé ọ̀dọ́ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i?
4 Ìyípadà Tó Yẹ Kẹ́nì Kọ̀ọ̀kan Ṣe: Káwọn olùjọ́sìn tòótọ́ bàa lè mú ìhìn rere dé ọ̀dọ́ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i, wọ́n ti ṣe àwọn ìyípadà kan tó yẹ. Ọ̀pọ̀ ti dín lára àwọn nǹkan tí wọ́n dáwọ́ lé kù kí wọ́n bàa lè túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà. Àwọn kan ti ṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn mìíràn sì ti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i nípa kíkọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè.
5, 6. Kí la lè ṣe láti lè wàásù ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tá a bá lè rí?
5 Láfikún sí i, a tún lè mú káwọn èèyàn púpọ̀ sí i gbọ́ ìhìn rere náà tá a bá ń wàásù lákòókò tá a lè bá wọn nílé tá a sì ń lọ sáwọn ibi tá a ti lè rí wọn. Báwọn èèyàn kì í bá fi bẹ́ẹ̀ sí nílé lọ́wọ́ àárọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yìn, ṣé wàá kúkú lọ máa bẹ̀ wọ́n wò bó bá di ọjọ́rọ̀? Ǹjẹ́ àwọn ibi térò máa ń pọ̀ sí tó o ti lè máa wàásù wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Ṣó o ti gbìyànjú láti fi fóònù wàásù rí? Ṣé o ti wàásù fáwọn èèyàn níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé rí? Ṣó o máa ń wá ọ̀nà tí wàá fi wàásù láìjẹ́-bí-àṣà?
6 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti wà lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìjẹ́rìí gíga lọ́lá yìí nípa orúkọ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀! Ǹjẹ́ ká máa báa nìṣó láti máa wàásù òtítọ́ tó ń fúnni níyè látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn tá a bá lè rí.—Mát. 28:19, 20.