ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/15 ojú ìwé 19-24
  • Jèhófà Ń ṣètò Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń ṣètò Sílẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Ńlá
  • Àǹfààní Tí Ìsìn Ṣí Sílẹ̀
  • Àwọn Àǹfààní Òfin
  • Àkókò Àlàáfíà àti Òmìnira Ẹ̀sìn
  • Ipa Tí Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kó
  • Mímúra Àwọn Orílẹ̀-Èdè Sílẹ̀ fún “Ẹ̀kọ́ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Ń Darí Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tí À Ń Ṣe Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Ẹ̀rí Fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/15 ojú ìwé 19-24

Jèhófà Ń ṣètò Sílẹ̀

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí.”—MÁTÍÙ 24:14.

1. Kí ni iṣẹ́ ìwàásù náà ti mú kí ó ṣeé ṣe ní ọ̀rúndún kìíní àti ní ọ̀rúndún ogún yìí?

NÍTORÍ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ohun tó wù ú ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Èyí ló fà á tí a fi ní láti wàásù, kí a sì kọ́ni jákèjádò àgbáyé. Ní ọ̀rúndún kìíní, wíwàásù yìí sọ ìjọ Kristẹni di “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni sáà gígùn ti ìpẹ̀yìndà dé, nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ di bàìbàì. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, láàárín “àkókò òpin,” “ìmọ̀ tòótọ́” tún ti di púpọ̀ yanturu, èyí tó ti mú ìrètí ìgbàlà àìnípẹ̀kun tí a gbé ka Bíbélì wá fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn.—Dáníẹ́lì 12:4.

2. Kí ni Jèhófà ti ṣe nípa ìgbòkègbodò wíwàásù náà?

2 Láìka bí Sátánì ṣe ń sapá láìsinmi láti dá ète Ọlọ́run dúró sí, iṣẹ́ ìwàásù náà ti ṣe àgbàyanu àṣeyọrí ní ọ̀rúndún kìíní àti ní ọ̀rúndún ogún yìí pẹ̀lú. Ó mú kí a rántí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. Nígbà tí Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Júù tó wà nígbèkùn yóò ṣe padà wá sí Júdà ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó wí pé: “Gbogbo àfonífojì ni kí a gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké sì ni kí a sọ di rírẹlẹ̀. Ilẹ̀ págunpàgun sì gbọ́dọ̀ di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ, ilẹ̀ kángunkàngun sì gbọ́dọ̀ di pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì.” (Aísáyà 40:4) Jèhófà tún ti ṣètò sílẹ̀, ó mú kí a wà ní sẹpẹ́ fún iṣẹ́ ìwàásù ní ọ̀rúndún kìíní àti ní ọ̀rúndún ogún yìí pẹ̀lú.

3. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú ète rẹ̀ ṣẹ?

3 Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń darí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní tààràtà kí wíwàásù ìhìn rere náà ṣáà lè máa tẹ̀ síwájú; bẹ́ẹ̀ ni kò sì túmọ̀ sí pé Jèhófà ń lo agbára tó ní láti mọ bí ọ̀la yóò ti rí, láti lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Lóòótọ́, ó lágbára láti rí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, kó sì darí rẹ̀. (Aísáyà 46:9-11) Àmọ́, ó tún máa ń rí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun bí wọ́n bá ṣe ń yọjú. Bí olùṣọ́ àgùntàn kan tó ti nírìírí ṣe mọ bí yóò ṣe darí agbo ẹran rẹ̀ tí yóò sì dáàbò bò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń darí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń ṣamọ̀nà wọn sí ìgbàlà, ó ń dáàbò bò ipò tẹ̀mí wọn, ó sì ń mú kí wọ́n lo àǹfààní ipò èyíkéyìí àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun láti mú kí wíwàásù ìhìn rere náà jákèjádò ayé kẹ́sẹ járí.—Sáàmù 23:1-4.

Iṣẹ́ Ńlá

4, 5. Èé ṣe tí wíwàásù ìhìn rere náà fi jẹ́ iṣẹ́ kan tí ń peni níjà?

4 Gẹ́gẹ́ bí kíkan áàkì náà ṣe jẹ́ iṣẹ́ ńlá ní ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà ṣe jẹ́—ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní pẹ̀lú. Lóòótọ́ ni pé kò rọrùn láti mú ìsọfúnni èyíkéyìí lọ sọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí gan-an tún lékenkà. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò tó nǹkan. Wọ́n sì ti pa Jésù, Ọ̀gá wọn, nítorí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀mọ́jọba tí wọ́n fi kàn án. Ní ti ìsìn àwọn Júù, gbọn-ingbọn-in ló fìdí múlẹ̀. Tẹ́ńpìlì àwòyanu wà ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ìsìn tó wà ní àgbègbè Mẹditaréníà tó jẹ́ pé wọn kì í ṣe tí àwọn Júù pàápàá fìdí múlẹ̀ dáadáa, wọ́n ní tẹ́ńpìlì, wọ́n tún láwọn àlùfáà. Bákan náà, bí “àkókò òpin” ṣe bẹ̀rẹ̀ ní 1914, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kéré níye, àwọn tó fara mọ́ ìsìn mìíràn tí wọ́n sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run sì pọ̀ rẹpẹtẹ.—Dáníẹ́lì 12:9.

5 Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ó ṣe inúnibíni sí wọn. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Ní àfikún sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, pàápàá ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn Kristẹni yóò bá ara wọn nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Bí iṣẹ́ náà ṣe pọ̀ tó, bí a ṣe ń rí inúnibíni lọ́tùn-ún lósì, àti bí àkókò ṣe ṣòro tó, ti mú kí iṣẹ́ wíwàásù náà túbọ̀ jẹ́ iṣẹ́ tí ń peni níjà, tó sì ṣòro. Ó wá pọndandan kí a ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.

6. Ẹ̀rí wo ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn yóò ṣàṣeyọrí?

6 Bí Jèhófà ṣe mọ̀ pé àwọn ìṣòro yóò wà, bẹ́ẹ̀ náà ló mọ̀ pé kò sí ohun tó lè dá iṣẹ́ náà dúró. Àṣeyọrí yìí ni a sọ nípa rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó, tó ní ìmúṣẹ gígadabú ní ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún ogún yìí pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Mátíù 24:14.

7. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe lọ jìnnà tó ní ọ̀rúndún kìíní?

7 Nítorí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kìíní kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́, ó ṣeé ṣe fún wọn láti lè máa bá iṣẹ́ tí a yàn fún wọn lọ. Nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn, wọ́n ń ṣe àṣeyọrí tó ga gan-an ré kọjá ohun tí wọ́n retí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn ikú Jésù, ó ṣeé ṣe fún un láti sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere náà pé a ti “wàásù” rẹ̀ “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Ní ìfiwéra, bí ọ̀rúndún ogún yìí sì ti ń lọ sí òpin rẹ̀, a ti wàásù ìhìn rere náà ní ilẹ̀ igba àti mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.

8. Lábẹ́ irú ipò wo ní ọ̀pọ̀ ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà? Fúnni lápẹẹrẹ.

8 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí. Ọ̀pọ̀ ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ipò tí kò bára dé—ní àwọn àkókò ogun, lábẹ́ ìfòfindè, àti lójú inúnibíni líle koko pàápàá. Bákan náà ló ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní. Ìgbà kan wà tí wọ́n fi ọ̀pá na Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní ìnà ìkà, tí wọ́n sì sọ wọ́n sínú túbú. Ẹ wo irú ipò tí kò bára dé tí wọ́n wà, tí wọ́n sì ní láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn! Síbẹ̀, ohun tí Jèhófà lo ipò yẹn fún gan-an nìyẹn. Wọ́n dá Pọ́ọ̀lù àti Sílà sílẹ̀, onítúbú pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ sì di onígbàgbọ́. (Ìṣe 16:19-33) Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn alátakò kò lè dá ìhìn rere náà dúró. (Aísáyà 54:17) Síbẹ̀síbẹ̀, kò tí ì sígbà kan nínú ìtàn Kristẹni tí wọn kò dojú kọ ìpọ́njú àti inúnibíni. Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a wá darí àfiyèsí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra tó ti ṣèrànwọ́ láti múra wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù náà, kó lè kẹ́sẹ járí ní ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún ogún yìí pẹ̀lú.

Àǹfààní Tí Ìsìn Ṣí Sílẹ̀

9, 10. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí àwọn èèyàn máa fojú sọ́nà fún wíwàásù ìhìn rere náà ní ọ̀rúndún kìíní àti ní ọ̀rúndún ogún yìí?

9 Gbé àkókò tí a fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí ipò nǹkan ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, àsọtẹ́lẹ̀ aláàádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún tí a rí nínú ìwé Dáníẹ́lì 9:24-27, tọ́ka ní pàtó sí ọdún ti Mèsáyà náà yóò fara hàn—ìyẹn ni ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kò lóye àkókò pàtó tí àwọn nǹkan yóò ṣẹlẹ̀, síbẹ̀, wọ́n ń retí, wọ́n sì ń dúró de Mèsáyà náà. (Lúùkù 3:15) Ìwé ilẹ̀ Faransé náà, Manuel Biblique, sọ pé: “Àwọn ènìyàn mọ̀ pé àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún tí Dáníẹ́lì sọ ń sún mọ́ tòsí; kò sí ẹni tó yà lẹ́nu láti gbọ́ tí Jòhánù Oníbatisí ń kéde pé ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.”

10 Báwo ni ipò nǹkan ti rí lóde òní? Ní ti gidi, ohun títayọ lọ́lá tó wà níbẹ̀ ni gbígbé Jésù gorí ìtẹ́ lókè ọ̀run, èyí tó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára Ìjọba. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé èyí ṣẹlẹ̀ ní 1914. (Dáníẹ́lì 4:13-17) Ìháragàgà fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tún sún àwọn onísìn kan lóde òní láti máa retí lójú méjèèjì. Ìfojúsọ́nà yìí tún hàn kedere láàárín àwọn olùfọkànsìn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde gẹ́gẹ́ bíi Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence ní ọdún 1879. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọ̀rúndún kìíní àti ní àkókò tiwa yìí, ìrètí tí a gbé ka ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wíwàásù ìhìn rere náà.a

11. Ìpìlẹ̀ wo ló ti wà tẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn tó sì wá ṣèrànwọ́ fún wíwàásù ìhìn rere náà?

11 Kókó mìíràn tó tún ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ Kristẹni ní sànmánì méjèèjì ni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwùjọ àwọn Júù fọ́n káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí tó yí wọn ká. Àwọn àwùjọ náà ní sínágọ́gù tí àwọn ènìyàn ti ń pàdé lóòrèkóòrè láti gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ àti àlàyé rẹ̀. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni ìjímìjí láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí àwọn ènìyàn ti ní tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ kan. (Ìṣe 8:28-36; 17:1, 2) Ní ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tiwa, àwọn ènìyàn Jèhófà gbádùn irú àǹfààní kan náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Gbogbo àgbègbè tí Kirisẹ́ńdọ̀mù wà pátá ni Bíbélì ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ní pàtàkì ní àwọn ilẹ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti ń kà á; àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló sì ní ẹ̀dà tiwọn. Bíbélì ti wà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ná, àmọ́, wọ́n nílò ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ohun tí wọ́n ní.

Àwọn Àǹfààní Òfin

12. Báwo ni òfin Róòmù ṣe sábà máa ń jẹ́ ààbò ní ọ̀rúndún kìíní?

12 Iṣẹ́ ìwàásù àwọn Kristẹni sábà máa ń jàǹfààní látinú òfin ìjọba. Ilẹ̀ Ọba Róòmù ló jọba lé ayé lórí ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn òfin rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ sì nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Àwọn òfin wọ̀nyí ń pèsè ààbò, àwọn Kristẹni ìjímìjí sì jàǹfààní látinú wọn. Fún àpẹẹrẹ, gbàjarè tí Pọ́ọ̀lù ké sí òfin Róòmù ló mú kí wọ́n dá a sílẹ̀ nínú túbú, òun ni kò sì jẹ́ kí wọ́n nà án. (Ìṣe 16:37-39; 22:25, 29) Títọ́ tó tọ́ka sí ètò òfin Róòmù ló jẹ́ kí ara rọ àwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n fẹ́ fìbínú kọ lù ú ní Éfésù. (Ìṣe 19:35-41) Nígbà kan sì rèé, a yọ Pọ́ọ̀lù nínú rògbòdìyàn ní Jerúsálẹ́mù nítorí pé ó jẹ́ ọmọ Róòmù. (Ìṣe 23:27) Lẹ́yìn ìyẹn ni òfin Róòmù gbà á láyè láti fi òfin gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ níwájú Késárì. (Ìṣe 25:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn Késárì tó ṣèjọba láyé ọjọ́un ló jẹ́ òǹrorò, síbẹ̀ òfin ọ̀rúndún kìíní sábà máa ń fàyè sílẹ̀ fún “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”—Fílípì 1:7.

13. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń jàǹfààní lára òfin ní àkókò tiwa?

13 Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà tí wọ́n le “fi àṣẹ dáná ìjàngbọ̀n,” síbẹ̀ àwọn òfin tó wà lákọọ́lẹ̀, èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè ń lò, ka òmìnira ẹ̀sìn sí ẹ̀tọ́ gbogbo gbòò. (Sáàmù 94:20) Ní mímọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe adàlúrú, ọ̀pọ̀ ìjọba ló ti fún wa láṣẹ lábẹ́ òfin. Ó ti pé ọgọ́fà ọdún tí òfin ti mú kí ó ṣeé ṣe pé kí a máa tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde láìdáwọ́dúró ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí a ti ń tẹ ọ̀pọ̀ jù lọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí, tí àwọn ènìyàn sí ń kà á jákèjádò ayé.

Àkókò Àlàáfíà àti Òmìnira Ẹ̀sìn

14, 15. Báwo ni àlàáfíà díẹ̀ tó wà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ṣe ṣàǹfààní fún iṣẹ́ ìwàásù náà ní ọ̀rúndún kìíní?

14 Iṣẹ́ ìwàásù náà tún ti jàǹfààní àwọn àkókò tí àlàáfíà wà níwọ̀nba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ ní pàtó pé ní àwọn sànmánì wọ̀nyí, ‘orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè,’ síbẹ̀, àwọn sáà kan wà tí pákáǹleke kò sí, ìyẹn sì mú kí ó ṣeé ṣe láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní àṣekára. (Mátíù 24:7) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbé lábẹ́ Pax Romana, tàbí Àlàáfíà Róòmù. Òpìtàn kan kọ̀wé pé: “Róòmù tẹ àwọn ènìyàn àgbègbè Mẹditaréníà lórí ba pátápátá débi pé ó bá wọn fòpin sí ogun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àjààjàtán fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Àkókò tí àlàáfíà wà yìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni ìjímìjí láti rìnrìn àjò jákèjádò àgbègbè Róòmù láìséwu.

15 Ilẹ̀ Ọba Róòmù tiraka láti mú kí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lábẹ́ ìṣàkóso lílágbára rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Kì í ṣe rírin ìrìn àjò, òmìnira ẹ̀sìn, àti fífikùn lukùn nìkan ni àkóso yìí gbé lárugẹ, àmọ́ ó tún gbé èròǹgbà ẹgbẹ́ ará kárí ayé kalẹ̀. Ìwé náà, On the Road to Civilization, sọ pé: “Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Ọba [Róòmù] mú kí àǹfààní tó wà [fún ìwàásù Kristẹni] di èyí tó múnú ẹni dùn. Ẹ̀mí orílẹ̀-èdè-rẹ-ò déhìn-ín ò sí mọ́. Ẹní bá ti lè di ọmọ Róòmù ti di ọmọ onílẹ̀ níbikíbi lágbàáyé. . . . Láfikún sí i, orílẹ̀-èdè tó ti gbé ẹ̀mí pé, àparò kan kò ga ju kan lọ, ọ̀kan náà ni gbogbo ènìyàn, lárugẹ, ló ti lè rọrùn láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn tó ń fi ẹ̀mí ẹgbẹ́ ará kọ́ni.”—Fi wé Ìṣe 10:34, 35; 1 Pétérù 2:17.

16, 17. Kí ló fa ìsapá láti mú àlàáfíà wá lóde òní, orí ìparí èrò wo ni èyí sì sún ọ̀pọ̀ ènìyàn dé?

16 Àkókò tiwa wá ńkọ́? Ọ̀rúndún ogún yìí ni a rí ogun tó ba nǹkan jẹ́ jù lọ nínú ìtàn, ogun ẹlẹ́kùnjẹkùn kò sì dáwọ́ dúró ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. (Ìṣípayá 6:4) Síbẹ̀, àwọn àkókò kan wà tí a ní àlàáfíà díẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ alágbára ayé kò tí ì bára wọn jagun àjàkú-akátá fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún báyìí. Ipò yìí ti ṣèrànwọ́ gan-an fún wíwàásù ìhìn rere náà ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn.

17 Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí ogun ọ̀rúndún ogún yìí ti dá sí àwọn ènìyàn lára ti mú kí ọ̀pọ̀ rí i pé a nílò ìjọba àgbáyé lójú méjèèjì. Ṣe bí ìbẹ̀rù ogun àgbáyé ló mú kí wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. (Ìṣípayá 13:14) Ète tí àjọ méjèèjì polongo rẹ̀ ni láti gbé àjọṣe àti àlàáfíà gbogbo orílẹ̀-èdè lárugẹ. Àwọn èèyàn tí wọ́n ń ronú nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fayọ̀ gba ìhìn rere nípa ìjọba àgbáyé tí yóò mú ojúlówó àlàáfíà pípẹ́ títí wá—ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run.

18. Ẹ̀mí wo ní àwọn èèyàn ń ní sí ẹ̀sìn báyìí tó wá ṣe iṣẹ́ ìwàásù lóore?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣenúnibíni gbígbóná janjan sáwọn Kristẹni lọ́pọ̀ ìgbà, bó ṣe ọ̀rúndún kìíní, bó sì ṣe ọ̀rúndún ogún yìí, ọ̀rúndún méjèèjì la ti fún àwọn èèyàn lómìnira ẹ̀sìn. (Jòhánù 15:20; Ìṣe 9:31) Àwọn ará Róòmù fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun lómìnira láti sin àwọn ọlọ́run àti yèyé òrìṣà wọn, wọ́n tilẹ̀ tún sọ wọ́n di ọlọ́run tiwọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Rodney Stark kọ̀wé pé: “Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, òmìnira ẹ̀sìn tí àwọn ará Róòmù fúnni kò láfiwé títí di ìgbà tí Ìyípadà Tegbòtigaga wáyé nílẹ̀ Amẹ́ríkà.” Ní òde òní, àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ túbọ̀ ń ṣe tán láti gbọ́ èrò àwọn ẹlòmíràn, èyí sì ń mú kí wọn fẹ́ fetí sí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú tọ̀ wọ́n wá.

Ipa Tí Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kó

19. Báwo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe lo ìwé àfọwọ́kọ alábala?

19 Paríparí rẹ̀, ronú nípa bí Jèhófà ṣe mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹfààní lára ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò gbé ní sànmánì tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń yára tẹ̀ síwájú, síbẹ̀ wọ́n lo ìlọsíwájú kan tó jẹ́ ti ìwé àfọwọ́kọ alábala. Ìwé àfọwọ́kọ alábala náà ló dípò àkájọ ìwé kàbìtì-kàbìtì. Ìwé náà, The Birth of the Codex, sọ pé: “Ní ìyàtọ̀ sí bí àwọn òǹkọ̀wé ayé ṣe fi ọ̀rọ̀ títẹ́wọ́ gba ìwé àfọwọ́kọ alábala falẹ̀, tí wọn kò sì jára mọ́ bí yóò ṣe rọ́pò àkájọ ìwé, ọ̀nà tí àwọn Kristẹni fi tẹ́wọ́ gba ìwé àfọwọ́kọ alábala náà yára kánkán, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ níbi gbogbo.” Ìwé ìtọ́ka yìí tún sọ pé: “Àwọn Kristẹni lo ìwé àfọwọ́kọ alábala náà níbi gbogbo ní ọ̀rúndún kejì débi pé ṣáájú ọdún A.D. 100, ó ti di ohun tí gbogbo ayé mọ̀.” Ìwé àfọwọ́kọ alábala náà rọrùn láti lò ju àkájọ ìwé lọ. Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ ṣeé tètè rí. Dájúdájú èyí ran àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́, kì í ṣe láti lè ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n, bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n “ń fi ẹ̀rí ìdánilójú” àwọn ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni “hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka.”—Ìṣe 17:2, 3.

20. Báwo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ nínú ìgbòkègbodò wíwàásù kárí ayé, èé sì ti ṣe?

20 Ìlọsíwájú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ní ọ̀rúndún tiwa ti gadabú. Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ayára bí àṣá ti ṣèrànwọ́ láti lè máa mú ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní onírúurú èdè lẹ́ẹ̀kan náà. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì yára kánkán. Àwọn ọkọ̀ akẹ́rù, ọkọ̀ ojú irin, ọkọ̀ òkun, àti ọkọ̀ òfuurufú tí mú kí yíyára kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ sí gbogbo àgbáyé ṣeé ṣe. Tẹlifóònù àti ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni ti sọ ètò ìbánisọ̀rọ̀ lójú ẹsẹ̀ di ohun tó ṣeé ṣe. Jèhófà ti tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ sún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti lo irú àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó dára, kí wọ́n lè gbé pípín ìhìn rere náà jákèjádò ayé lárugẹ. Wọn ò lo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n fẹ́ láti mọ̀ nípa ohunkóhun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde àti láti rí ọ̀nà àtilò wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun àkọ́kọ́ tó sì tún jẹ́ olórí ìfẹ́-ọkàn wọn ní láti ri ohun tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tó yá kánkán jù lọ.

21. Kí ló lè dá wa lójú?

21 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àwa lónìí ń rí i lọ́nà gbígbòòrò. Láìfi bí iṣẹ́ náà ti tóbi tó, tó sì ṣòro tó pè, yálà lákòókò tó wọ̀ tàbí àkókò tí kò wọ̀, ìgbà tí òfin àti ìwà àwọn èèyàn yí padà, ìgbà tí ogun ń jà tàbí ìgbà tí àlàáfíà wà, àní láàárín àkókò tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ń tẹ̀ síwájú lónírúurú ọ̀nà pàápàá, ìhìn rere náà ṣì ń báa lọ, bẹ́ẹ̀ náà la sì ń wàásù rẹ̀. Ǹjẹ́ èyí kò mú ọ kún fún ìbẹ̀rù nípa bí ọgbọ́n Jèhófà ti pọ̀ tó àti bí agbára rẹ̀ láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la ti múni gbọ̀n rìrì tó? Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, ó yẹ kó dá wa lójú gbangba pé a ó parí iṣẹ́ ìwàásù náà ní àkókò tí Jèhófà ti yàn, yóò sì mú ète rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ṣẹ, tí yóò sì já sí ìbùkún fún àwọn olódodo. Ilẹ̀ ayé yóò wá jẹ́ tiwọn, wọn ó sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé. (Sáàmù 37:29; Hábákúkù 2:3) Bí a bá mú ìgbésí ayé wa bá ète Jèhófà mu, a ó wà lára wọn.—1 Tímótì 4:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì nípa Mèsáyà yìí, wo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 36, 97, àti 98 sí 107, tí Watch Tower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Àwọn Kókó fun Àtúnyẹ̀wò

◻ Báwo ni wíwàásù ìhìn rere náà ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó peni níjà?

◻ Àwọn ọ̀nà wo ni iṣẹ́ àwọn Kristẹni fi jàǹfààní látinú àwọn ètò tí ìjọba ṣe àti lára àlàáfíà díẹ̀ tó wà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà?

◻ Kí ni ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ ìwàásù náà ń mú dá wa lójú nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́